Ọlọ́pàá mẹ́rin tó gbégi dínà lójú pópó fi tipá gba rìbá N57,000 lọ́wọ́ ọ̀gá àjọ tó ń gbógun tìwà àjẹbánu, ICPC, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ

Akọyinsi aworan ọlọpaa ti wọn fẹsun ilọnilọwọgba kan l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Awọn ọlọpaa naa/Screenshot

Àkọlé àwòrán, Awọon ọlọaa ọhun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Lati ọdun to ti pẹ ni awọn ọmọ Naijiria ti n pariwo sita nipa ilọnilọwọgba ati iwa ajẹbanu to n ṣẹlẹ ninu iṣẹ ijọba, to si jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ni aje ọrọ naa ṣi mọ lori julọ.

Awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ni wọn lo maa fi gbogbo igba beere owo riba, ti wọn si n lọ awọn eeyan lọwọ gba nigba ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ wọn.

Ṣugbọn ṣa, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n sọ pe ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo ni ti olohun, lo ṣẹlẹ gẹlẹ pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi mẹta.

Lasiko yii, alaga ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, ICPC, Musa Aliyu ni awọn ọlọpaa kan fọwọ ṣikun ofin gbe nilu Abuja, ti wọn si fi ẹsun titapa si ofin kan an, leyi to jẹ ki wọn beere owo lọwọ rẹ.

Bá wo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Alaga ICPC lo wa si olu ileeṣẹ BBC niluu Abuja, nibi ti a ti fi ọrọ wa a lẹnu wo lori oniruuru ohun to n ṣẹlẹ, ati bi awọn ọlọpaa ṣe kan an nipa fun un lati san owo riba.

Nigba to n sọrọ, o sọ pe "Lọjọ Abamẹta, mo n wa ọkọ mi lọ, nigba ti awọn yooku n tẹle mi lẹyin, mo de ibi ti awọn ọlọpaa wa ni ikorita Barnex.

"Nigba ti mo duro, ọlọpaa kan wa sibi ọkọ ayọkẹlẹ mi. MO si fa gilaasi ọkọ mi silẹ. O sọ pe ki n ṣilẹkun ọkọ mi, mo si ṣi i, loju ẹsẹ lo wọle.

"Lẹyin to wọle, lo bẹrẹ sii beere oniruru ibeere lọwọ mi. O sọ pe mo fo ina lati bọ eeyan lọwọ. Mo sọ pe rara, ko ri bẹẹ, nitori pe niṣe ni mo duro nigba ko to di pe ina bẹrẹ sii jo."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aliyu sọ pe lasiko naa, ọkọ miran wa niwaju oun, ti ọlọpaa naa ko lọ sibẹ lati fi ẹsun kan.

"O wa sọ pe ki n mu kaadi aṣẹ wiwa ọkọ mi wa, mo si mu le lọwọ. O loun yoo gbe mi lọ sile ẹjọ nitori pe mo ti tapa si ofin. Mo sọ fun un pe ko jẹ ka lọ si ile-ẹjọ," o sọ bẹẹ.

"Nigba to ya, a bẹrẹ sii rin siwaju, o wa sọ fun mi pe eeyan nla ni mi, wi pe bi oun ba gbe mi lọ sile ẹjọ, wọn yoo sọ pe ki n san ẹgbẹrun mejilelaadọta naira, ati pe ki n ko owo naa wa, k'oun lọ ba mi san an.

"Mo wa sọ pe ko fun mi ni apo aṣuwọn ile ifowopamọsi rẹ, ki n le fi owo ọhun ranṣẹ, ṣugbọn o kọ. O sọ pe PoS kan wa niwaju, o si mu mi lọ sibẹ, nibi ti mo ti gba ẹgbẹrun mẹtalelaadọta naira, ti oni PoS naa si gba ẹgbẹrun kan naira.

"Lẹyin naa, o tun sọ fun mi pe ki n fun oun lowo ọkọ lati lọ san owo naa, mo si fun un ni ẹgbẹrun meji naira, o tun sọ pe owo naa kere, mo wa fun un ni ẹgbẹrun mẹta naira si i.

"Mo tun gbe e pada sibi ti mo ti gbe e tẹlẹ. Lẹyin ti mo ja a silẹ, o wọ ọkọ taisi. Mo tẹle taisi naa lẹyin lati mọ ibi ti wọn n lọ, ṣugbọn wọn poora mọ mi loju," alaga ICPC ṣalaye.

O wa sọ siwaju pe alaga naa ti lọ fi to awọn alakoso eleto aabo leti.

Musa Aliyu jẹ ko di mimọ pe, apapọ owo ti ọlọpaa naa gba lọwọ oun jẹ ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta naira

"Idi pataki ti mo fi ṣe eyi ni pe mọ bi iru awọn nnkan bayii ṣe n ṣẹlẹ, ati pe ka si le wa ọna lati dẹkun rẹ siwaju sii," O fidi rẹ mulẹ.

Ìgbésẹ̀ ti Ọlọ́pàá gbé

Wayii o, lu ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja ti gba asọ lọrun ọlọpaa mẹrin lori ẹsun ilọnilọwọgba naa, ti wọn si ti wa lahaamọ.

Ọga agba pata fun ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, ICPC, Musa Aliyu la gbọ pe awọn ọlọpaa naa gba ẹgbẹrun mẹtalelaadọta naira lọwọ rẹ, to jẹ owo ilọnilọwọgba.

Asiko ti wọn sọ pe awọn ọlọpaa n yẹ awọn ọkọ ati awọn to n kọja lọ wo lọna aitọ ni wọn da Aliyu duro, ti wọn si fẹsun kan an, ko to di pe wọn gba owo ọhun lọwọ rẹ.

Ahmed Sanusi to jẹ ọga ọlọpaa FCT lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin niluu Abuja lọjọ Aje, ọsẹ yii, to si ni iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lori wọn.

Ọga ọlọpaa naa sọ pe niṣe ni awọn ọlọpaa wọnyi fi ibi ti wọn pin wọn si lati ṣiṣẹ silẹ, ti wọn si lọ gbegi dina lọna aitọ lagbegbe Banex to wa ni Wuse, nibi ti wọn ti lọ alaga ajọ ICPC lọwọ gba.

Sanusi jẹ ko di mimọ pe niṣe ni wọn kan an nipa fun alaga ICPC naa lati lọ gba owo ọhun, ẹgbẹrun mẹtalelaadọta naira lẹnu ẹrọ PoS gẹgẹ bi owo to yẹ ko san, ṣugbọn to sọ pe niṣe ni wọn pin owo naa laaarin ara wọn.

"Mo fẹẹ tun sọ fun un yin nibi wi pe a ni awọn ọlọpaa mẹrin to wa ni ahamọ, awọn ni wọn lọ eeyan pataki lawujọ lọwọgba, lai mọ pe eeyan pataki ni ẹni naa jẹ lawujọ," Sanusi sọ bẹẹ.

"Lai fi ọrọ sabẹ ahọn sọ, alaga ajọ ICPC ni wọn lọ lọwọ gba. Ẹgbẹrun mẹtalelaadọta naira ni wọn gba lọwọ rẹ.

"Wọn mu lọ si ṣọọbu PoS kan, nibi to ti gba owo fun wọn, owo ti wọn fẹsun iwa rẹ kan an, ti wọn si pin-in laaarin ara wọn.

"Ikọ ọdaran ti wọn fi iṣẹ wọn silẹ, wọn panupọ lati korajọ, ti wọn si gbe agbegbe ilọnilọwọgba wọn kalẹ ni Wuse Banex, nibi ti wọn ti n huwa buruku ko to di pe wọn salọ."

Sáájú kí ọwọ́ tóó tẹ̀ wọ́n

Ọga ọlọpaa naa jẹ ko di mimọ pe awọn ti kọkọ kede awọn mẹrẹẹrin gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa, ko to di pe ọwọ tẹ olori wọn. Bo ṣe jẹwọ ẹṣẹ rẹ, lo bẹrẹ sii tọka awọn yooku ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi naa.

"Gbogbo wọn pata la fi ọwọ ṣikun ofin gbe. A si maa rii daju pe wọn jiya ẹṣẹ to tọ si wọn labẹ ofin," Ṣanusi sọ bẹẹ.

"Awọn to yẹ ka gba iṣẹ lọwọ wọn, la maa gba a lai fi akoko ṣofo, nigba ti asiko ba to.

Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe ọga awọn patapata, Tunji Disu ti sọ pe iwa ti ko ba ofin mu ni ki ọlọpaa da araalu duro, lati maa yẹ foonu wọn wo.

O wa rọ awọn araalu lati ma ṣe gba ọlọpaa kankan laaye lati yẹ foonu wọn wo nibikibi, ati pe ki wọn tete fi to ileeṣẹ wọn leti nigba ti iru iṣẹlẹ bẹẹ ba waye.

A ṣi n tẹle aṣẹ ọga agba. Awọn kan ṣi n ṣiṣẹ buruku naa nirori pe wọn ko ni erongba meji to kọj iwa ọdaran. Bi a ba rọwọ to wọn, a maa rii daju pe wọn foji winna ofin," o kadi ọrọ rẹ nilẹ.