Wo bí 'Muhammad' ṣe di orúkọ tí wọ́n ń sọ ọmọkùnrin jùlọ ní England àti Wales

Awọn ọmọde to jokoo ti wọn n ṣere

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Orukọ Muhammad tun ni orukọ to gbajumọ tawọn obi sọ ọmọkunrin wọn julọ ni orilẹ ede England ati Wales ni ọdun 2025.

Abọ iwadii ti ajọ to n ri si onka ni UK iyẹn UK Statistics Office lo fidi eyi mulẹ ninu iwadii kan ti won ṣe nipa orukọ tawọn obi fun ọmọ wọn julọ lọdun to kọja.

Eyi lo fi n jẹ ọdun kẹta lera wọn ti Muhammad n jẹ jade gẹgẹ bi orukọ tawọn obi n sọ ọmọ wọn julọ ni England ati Wales.

Bẹẹ gẹgẹ lo ri lọdun 2023, 2024 ati 2025.

Muhammad, Mohammed ko Muhammed?

Abọ iwadii naa sọ pe Muhammad lo lewaju ninu orukọ awọn ọmọkunrin ni gbogbo oṣu ni ọdun 2025.

Wọn ni awọn ọmọkunrin 5,957 ni wọn sọ ni orukọ Muhammad, nigba ti bi wọn ṣe n kọ orukọ naa lọna ọtọ bii Mohammed ati Muhammed tun jẹyọ lọna pupọ.

Ipo ogun ni Mohammed wa ninu awọn orukọ to wọpọ pẹlu awọn ọmọ 1,712 to n jẹ orukọ naa.

Mohammad naa jẹyọ nipo karundinlọgọta nigba tawọn ọmọ to n jẹ bẹẹ jẹ 895.

Kí ló fà á tí Muhammad fi wọ́pọ̀?

Ọmọbinrin ati ọmọkunrin to wa legbẹ ara wọn, wọn n rẹrinin, wọn n wo ọọkan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ nipa sisọ ọmọ lorukọ, Clare Green to n ṣiṣẹ pẹlu oju opo isọmọlurukọ Nameberry sọ pe ko ya oun lẹnu pe Muhammad lo tun lewaju ninu orukọ ti wọn n sọ ọmọkunrin ni ọdun 2025.

O ni ayipada kii tete waye si orukọ to ba ti wa loke bayii, to si jẹ pe ti orukọ kan ba ti gbajumọ, o maa n wa bẹẹ fun ọdun diẹ ko to yipada.

Onimọ naa fi kun pe o ṣeeṣe ko jẹ pe bi orukọ naa ṣe gbajumọ lo n mu ki awọn obi maa sọ orukọ bẹẹ, ti yoo si maa mu gbajumọ sii.

"Ti awọn eeyan ba n fun awọn ọmọ wọn ni orukọ kan, awọn obi mii to gba gbọ orukọ bẹẹ le nifẹẹ sii ki wọn si sọ ọmọ ti wọn, eyi lo maa n mu ki orukọ kan gbajumọ ni asiko kan."

Awọn orukọ mii

Awọn ọmọdebinrin meji to n ṣere

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yatọ si Muhammad, awọn orukọ mii to tun tẹle ni Noah, Leo, Luca ati Arthur.

Awọn mii to tun tẹle wọn ni Oliver, George, Oscar, Theodore ati Freddie.

Fun awọn ọmọ obinrin, Olivia ni orukọ to gbajumọ julọ, to si ti wa bẹẹ fun ọdun mẹwaa lera wọn bayii.

Awọn ọmọbinrin tuntun 5,000 ni wọn n jẹ orukọ naa bayii.

Atẹjade awọn orukọ ọmọ to gbajumọ julọ