Ilé aṣòfin Amẹrika buwọ́lù àbá láti dá ìrànwọ́ Amẹrika fún Naijiria dúró títí tíjọba yóò fi wá ojútùú sí ìṣekúpani àwọn Kristẹni

Oríṣun àwòrán, Donald Trump/Facebook
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin orilẹede Amẹrika ti buwọlu aba lati dawọ gbogbo iranwọ ti Amẹrika n ṣe fun Naijiria duro titi ti ijọba yoo fi wa ojutuu si iṣekupani awọn kristẹni ni Naijiria.
Ṣaaju ni orilẹede Amẹrika ti kọkọ din iranwọ to n ṣe fun Naijiria ku si ida 50%, amọ, wọn ti dinku si ida 100% bayii.
Aṣofin Gregory Stuebe to n ṣoju ẹkun Florida lo da aba naa l'Ọjọru ki gbogbo ile to gba a wọle.
Aṣofin to fi fidio ijokoo ile naa lede loju opo ayelujara rẹ sọ pe ''aba atunṣe ofin ti mo da lati dawọ gbogbo iranwọ ti Amẹrika n ṣe fun Naijiria duro titi ti ijọba yoo wa ojutuu iṣekupani awọn kristẹni ti wọle.
Awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ko le ma fun ijọba to kọ eti ikun si iṣekupani awọn kristẹni ati iṣẹlẹ ijinigbe to n waye.
A o le maa fi iranwọ orilẹede Amẹrika silẹ okeere ṣofo mọ,'' Gregory Steube lo sọ bẹẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, ile aṣoju-ṣofin yii naa lo dabaa wi pe ki ijọba Amẹrika ṣe adinku iranwọ to n ṣe fun Najiria si ida 50% loṣu Kẹrin ọdun yii.
Amọ, akọwe ijọba Amẹrika to n ri ọrọ ilẹ okeere sọ pe ijọba Naijiria ti n gbe igbesẹ lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ nigba naa.
''Ọpọ awọn obinrin kristẹni lawọn janduku agbebọn n ji gbe ti wọn si n ṣekupa wọn''
Aṣofin Steube sọ pe ''fifun ijọba Naijiria ni ida 50% iranwọ ti Amẹrika n fun orilẹede naa tumọ si pe Amẹrika n bun ijọba lowo nigba ti ijọba apapọ si ti kuna lati ṣe ojuṣe rẹ fun araalu.
Eyi lo jẹ ki n dabaa wi pe ki Amẹrika da gbogbo iranwọ to n ṣe fun Naijiria duro.
Ni bayii, a ma a wo o nnkan ti ijọba apapọ Naijiria yoo ṣe lati fopin si iṣẹlẹ igbesunmọmi ati iṣekupani to ti wọpọ bayii ni Naijiria.
Orilẹede Naijiria n koju oniruuru iwa ipa eyi ti ijọba ti kuna lati wa ojutuu si latari iwa ibajẹ.
Fun ọpọlọpọ ọdun lawọn janduku agbebọn ti ṣekupa awọn kristẹni atawọn ẹlẹsin kekeke mii ni Naijiria ti ijọba ko si fi wọn jofin.
Ọpọ awọn obinrin kristẹni lawọn janduku agbebọn n ji gbe ti wọn si n ṣekupa wọn, bẹẹ naa ni wọn n huwa ipa si wọn.
Bakan naa ni wọn tun n dana sun ile ijọsin kaakiri orilẹede Naijiria.''
Aṣofin naa sọ pe ile ko ni gba ki ijọba Amẹrika maa fun ijọba ti ko wa ominira ẹsin ati ijọba to ti kuna lati gbogun ti igbesunmọmi ati lati daabo bawọn olujọsin lọwọ awọn to n ṣe inunibini si wọn lowo ori tawọn ọmọ ilẹ Amẹrika n san.
Ile aṣofin agba Amẹrika naa gbọdọ fontẹ lu aba naa ki Aarẹ Donald Trump si buwọlu u ki o to le dofin.
Eyi ṣẹlẹ lẹyin ti Trump ti kọkọ ṣapejuwe Naijiria lọdun 2025 gẹgẹ bi orilẹede ti nnkan to n ṣẹlẹ nibẹ n kọ Amẹrika lominu papaa julọ lori ẹsun ṣiṣe inunibini sawọn kristẹni.
Ẹwẹ, ijọba apapọ ti sọ pe ko si inunibini kristẹni ni Naijiria, lẹyin naa si ni ileeṣẹ ologun Amẹrika ṣiṣẹ pọ pẹlu Naijiria lati jumọ gbogun tawọn agbesumọmi to n ṣọṣẹ kaakiri Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post



























