BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ilé aṣòfin Amẹrika buwọ́lù àbá láti dá ìrànwọ́ Amẹrika fún Naijiria dúró títí tíjọba yóò fi wá ojútùú sí ìṣekúpani àwọn Kristẹni
Aṣofin Gregory Stuebe to n ṣoju ẹkun Florida lo da aba naa l'Ọjọru ki gbogbo ile to gba a wọle.
Òjò yóò rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́wàá gbáko – Àyẹ̀wò ojú ọjọ́
Omiyale tete maa n waye nipinlẹ Eko latari bo ṣe sunmọ eti omi, paapaa alagbalugbu omi okun Atlantic Ocean.
Wo àwọn orílẹ́-èdè ilẹ̀ Afirika táwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹrika kò gbọdọ̀ lọ
Amẹrika sọ pe ipele kẹrin ni awọn orileede mẹtalelogun ọhun wa ninu awọn orileede ti Amẹrika sọ pe awọn araalu ko gbọdọ lọ, fun idi eyi, wọn ni ko si idi pataki ti kan ti awọn eeyan fi gbọdọ lọ sibẹ.
Fídíò, Àwọn ohun tí o lè ṣe rèé láti mú kí ọmọ rẹ má a jẹ èso àti ewébẹ̀ dáadáa, Duration 1,36
Ọpọ obi lo maa n ṣọrọ pe awọn ọmọ wọn kii fẹ jẹ eso ati ewebẹ daadaa ti wọn si ti fi awọn nnkan miran rọpo rẹ ni jijẹ.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,59
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Ohun tí a mọ̀ nípa bí Boko Haram àti ISWAP ṣe ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ AI fún ìgbésùnmọ̀mí
Iwadii ti fi han pe awọn Boko Haram ati ISWAP ti n lo AI, imọ ẹrọ to fẹrẹ ma si ohun ti ko le ṣe bi eeyan ba bẹ ẹ lọwẹ.
'Nàìjíríà tí mo padà sí yìí mo nílò láti ṣe àyẹ̀wò ọpọlọ mi' – Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó dé láti South Africa ṣàlàyé ohun ojú rí
Ṣaaju ni agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere, Kimiebi Ebienfa ti jẹ ko di mimọ pe awọn ọọdunrun-le-ni-mẹjọ ti wa ninu ọkọ baalu, lati agogo mẹfa aabọ aarọ oni, Ọjọru, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Keje.
Wo dúkìá 45 tó jẹ́ ti agbẹjọ́rò àgbà l'bẹ́ ìjọba Buhari, Abubakar Malami tí ilé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀lé
Ṣaaju idajọ rẹ ni adajọ ọhun kọ oniruru ẹbẹ Malami lẹyin to ni wọn ko lẹsẹ nilẹ.
Baálé ilé lu ìyàwó rẹ̀ pa nítorí oúnjẹ, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe nnkan bii aago mejila abọ ọsan lawọn eeyan kan lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa pe afurasi naa ti lu iyawo rẹ ti ẹmi si ti bọ lara iyawo naa.
''Ohun tó kàn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Oríire tó bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé rèé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ọ́...''
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Arabinrin Abiola sọ pe ''awọn obi awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ gbominira lọwọ ajinigbe ni iṣẹ to pọ lati ṣe nitori iriri ti wọn ni ninu igbo ti ṣakoba fun ilera ọpọlọ wọn.
Wo orúkọ gbogbo àwọn ọmọ ogun àti ọlọ́pàá tó kú sínú ìgbìyànjú láti dóòlà àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ Oriire
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, awọn ẹṣọ aabo mẹwaa ọtọọtọ lo kopa ninu igbiyanju lati tu awọn eeyan naa silẹ eyi ti Ọgagun Chinedu Ralph Nnebeife ti ọga ileeṣẹ ologun Commanding 2 Division tẹka ileeṣẹ ologun.
Èyí lohun tí MC Oluomo, Sego sọ̀rọ̀ lórí ikú tó pa Toba Ijaya, akọ̀wé NURTW ní ìpínlẹ̀ Eko
A gbọ pe awọn agbebọn naa kọlu Ajiboye ti ọpọ mọ si 'Tọba Ijaya' loju ọna marosẹ Ikorodu nibi ti wọn ti ṣina ibọn fun ọkọ rẹ.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fídíò, Ọdún mẹ́rin kò ní tó fún mi láti pari gbogbo iṣẹ́ takuntakun tí mo ti fọwọ́ bà – Gómìnà Adeleke, Duration 8,13
O ni gbogbo awọn ileri ti oun ṣe silẹ nigba ipade itagbangba BBC News Yoruba lọdun mẹrin sẹyin loun ti mu ṣẹ.
Wo ọ̀nà márùn-ún tí àwọn ọ̀dọ́ lè máa gbà rí owo gọbọi
Bi eeyan tiẹ ba ọla nile paapaa, to ri ogun gidi to le sọ di owo jẹ lọdọ awọn obi rẹ, dandan tun ni ko ṣiṣẹ kun un ki ọrọ naa ma baa parun.
Alága àdúgbò dá baálé ilé dọ́bálẹ̀, fi pankẹ́rẹ́ dá sẹ̀ríà ìyà fún un torí pé ó sọ̀rọ̀ lórí àṣepatì àkànṣeiṣẹ́ àjọ NDDC, ọlọ́pàá ní iléẹjọ́ yá
Atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta fi sita lo fidi ẹ mulẹ, pe awọn eeyan naa huwa to lodi sofin, igbejọ si ti bẹrẹ lori ọrọ wọn.
'Mi ò ní ìgboyà rẹ̀': Alicia Lissu sọ̀rọ̀ lórí ipa tí ètò òṣèlú Tanzania ní lórí ìdílé rẹ̀
Alicia Lissu, iyawo olori ẹgbẹ oṣelu alako ni Tanzania sọrọ nipa awọn nnkan to n koju lati igba ti ọkọ rẹ ti n koju igbẹjọ diditẹ mọ ijọba .
Wo orúkọ àwọn ọmọ Naijiria 124 tí Amẹrika kéde pé àwọn yóò lé kúrò lórílẹèdè náà
Ọrọ yii lo wa ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ abẹnu fi lede lori itakun ayelujare wọn.
Èyí ni àpéjọpọ̀ ẹ̀sìn márùn-ún táwọn èèyàn ti máa ń pọ̀jù lágbàáyé
Lọwọlọwọ yii, apejọpọ marun-un lo jẹ koko ti wọn si gbajumọ ju lagbaaye, eyi to jẹ ti ẹsin.
Iléẹṣẹ́ ológun Nàìjíríà ṣàlàyé iṣẹ́ oṣù kan tí wọ́n fi gba akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ Oríire lọ́wọ́ ajínigbé
Ọgagun Danjuma Jonah Danjuma, ti ẹka ikede nileeṣẹ ologun ẹkun keji (2 Division) lo fi atẹjade to ṣalaye ọna tawọn to wa nigbekun naa gba ri itusilẹ lọjọ kẹwaa, oṣu Keje ọdun 2026.
Sunday Igboho sọ ìdí tí ìjọba ṣe kọ̀ láti sanwó ìtúsílẹ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso
Ninu atẹjade kan ti Igboho fi lede lati ọwọ agbẹnusọ rẹ lo ti sọrọ naa.
Àlàyé lóríi bí àjọ NDLEA ṣe mú afurasí ọmọ South Africa kan l'Abuja lórí ẹ̀sùn pé ó gbé oògùn olóró Heroin
NDLEA ni ọmọ ọdun mẹta ti arabinrin naa gbe lọwọ lo fẹ fi boju ki aṣiri rẹ ma baa tu nibi ti wọn ti n ṣayẹwo fun un ni papakọ ofurufu ilu Abuja.
"Àkọ̀bí mi tó ń tọ́jú èmi àtàwọn àbúrò rẹ̀ ní wọ́n pa nínú ìjà Hausa àti Yorùbá n'Ibadan"
Ounjẹ alẹ ti Habeeb fẹ jẹ la gbọ pe o lọ ra to fi lugbadi iku ojiji ninu ija Yoruba ati Hausa naa
Ìjọba Nàíjíríà ṣe àfikún lórí owó oṣù àwọn ọmọ ogun láti 49,000 sí 100,000 náírà
Ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira ni ijọba gbe owo oṣu naa si bayii, lati ẹgbẹrun mọkandinlaadọta naira ti wọn n gba tẹlẹ gẹgẹ bi owo oṣu.
Ọdún méjìdínlógún ni mo fi wojú Ọlọ́run fọ́mọ kí n tó bí ìbejì - Ricardo Agbor
Ninu ifọrọwerọ kan ti agba oṣere naa ṣe pẹlu AfricanAList lo ti ṣalaye irinajo rẹ ninu sinima ṣiṣe ati igbeaye rẹ lai si ninu sinima.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Mo lè má sí láyé láti kópa nínú ètò ìdìbò ọdún 2027 – Obi
Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra sọ pe ọpọ awọn ẹtọ oun ni ijọba ilẹ Naijiria fi n dunkooko mọ oun, ati pe gbogbo awọn to duro gẹgẹ bi alatako ijọba ni wọn n dojukọ idunkooko loriṣiriṣi.
Èèyàn 161 pàdánù ẹ̀mí wọn láàrin oṣù márùn ún nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Ogun - FRSC
Agbẹnusọ sọ fun ajọ FRSC ẹka ti ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Afolabi Odunsi, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun ileeṣẹ iroyin NAN.
Àwọn ajínigbé de àwọn olùkọ́ ọkùnrin tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso mọ́lẹ̀, wón tún fi aṣọ bò wọ́n lójú fún ọjọ́ mérìndínlọ́gọ́ta - Soun
Ọba Olaoye lanfaani lati ri awọn akẹẹkọ at'awọn olukọ naa lasiko ti o kan sí ẹka ileeṣẹ ọmogun Naijiria to wa niluu Ibadan nibi ti kabiyesi ti gboṣuba kare fun ọga agba oludari ẹka naa to wa ni agbegbe Ojoo fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe lori bi wọn ṣe doola awọn akẹẹkọ at'awọn olukọ naa.
Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo gbẹ̀mí afurasí ajínigbé méjì lójú ọ́nà Owo lẹ́yìn tí wọ́n ṣíná ìbọn fúnra wọn
Ọlọpaa ni awọn ri ibọn ilewọ agbelẹrọ meji, ọta ibọn, awọn iboju meji, ẹrọ ilewọ ati kaadi ATM lakata wọn lẹyin ikọlu naa.
Àjọ EFCC wọ́ olórí ẹgbẹ́ Miyetti Allah lọ sílé-ẹjọ́ lórí ẹ̀sun jìbìtì $2.3m
Ẹsun mejila ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu iwa ajẹbanu ni ajọ naa fi kan Miyetti Allah niwaju ile-ẹjọ, eyi ti wọn sọ pe wọn tẹwọ gba obitibiti owo ilẹ okeere ọhun, ti wọn lo lodi si ofin.
Amẹ́ríkà àti Iran tún ju àdó olóró síra, èèyàn mẹ́rìnlá jáde láye
Amẹrika ni awọn ṣe ikọlu si ibudo awọn oloogun Iran to jẹ aadọrun-un. Iran sọ pe eeyan mẹrinla ni Amẹrika ti pa lẹnu ikọlu ọjọ meji naa.
Ìjìyà tó bá tọ́ sí agbésùnmọ̀mí la máa fún ṣọ́jà tó bá ń dúró de àṣẹ kó tó pa wọ́n- Mínísítà ètò ààbò
Ipinlẹ Sokoto ni Ọgagun Musa ti sọrọ yii, lasiko ti wọn n pin awọn ọkọ akọtami fawọn ẹka alaabo .
Aṣojú ìjọba Nàìjíríà nílẹ̀ Olómìnira Benin gba àlejò ọkùnrin tó gun ọ̀kadà láti London wá sí Nàìjíríà
Ọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii ni Olatunji Emmanuel Okedeyi gbera kuro niluu London.
Àwọn afurasí tò ṣekúpa òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì OGTV fojú ba ilé ẹjọ́, bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ rèé
Kitan Oyesiku ati ẹṣọ alaabo rẹ, Pelumi Adetayo ni awọn amookunṣeka naa pa nipakupa laipẹ yii niluu Kobape to wa loju ọna marosẹ Abeokuta si Sagamu.
Ifá kìlọ̀ fáwọn olóṣèlú tó fẹ́ dupò gómìnà l'Osun, àlàyè rèé
Ẹgbẹ naa ti orukọ wọn n jẹ Traditional Religion Worshippers Association of Osun State (TRAWSO), ṣekilọ yii lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.
Báwo ni owó PFIPC ṣe wọ́ àbá ìsúná tó bá jẹ́ ìjọba kò mọ nípa àjọ náà lóòótọ́, èmi kọ́ ni mo ṣé e, mo wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá lásìkò náà - Adeyemi sọ nínú fídíò tuntun
Ninu fidio kan to gba ori ayelujara ṣafihan bi Adeyemi ṣe n ba gbajumọ ori ayelujara, Martins Otse ti ọpọ eeyan mọ si VeryDarkMan sọrọ.
Ẹ má ṣe kọ̀ láti gba ọgọ́rùn-ún kan náírà, ìjìyà wà fún ẹni tó bá kọ̀ ọ́ – Báǹkì àpapọ̀ Naijiria kìlọ̀ fùn aráàlú
CBN sọ pe ki gbogbo awọn to n kọ lati maa gba owo ọgọrun kan naira naa dẹkun iwa naa bayii, nitori pe owo ọhun ṣi n jẹ itẹwọgba labẹ aṣẹ, akoso ati ofin ilẹ Naijiria.














































































