Wo ẹ̀sùn mẹ́wàá tí wọ́n fi kan àwọn afurasí tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé l'Ogbomoso

Awọn afurasi ajinigbe mẹta

Oríṣun àwòrán, Oyo affairs

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Keje ọdun 2026 yii ni ijọba apapọ Naijiria fi oju awọn afurasi mẹta kan han nile ẹjọ giga ilu Abuja, lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu ijinigbe to ṣẹlẹ si awọn olukọ ati akẹkọọ mẹrinlelogoji niluu Ogbomoso loṣu Karun-un ọdun yii.

Bi wọn ṣe fi Abdulrazak Umar ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu Khalifa/Abu Khalid) han ni wọn gbe Yunusa Musa ati Shamsu Adamu ti wọn tun n pe ni Abu Itisar wa sile ẹjọ naa lati sọ ti ẹnu wọn.

Gẹgẹ bi kootu ṣe fidi ẹ mulẹ, ẹsun onikoko mẹwaa ni awọn afurasi naa ni lati jẹjọ lori rẹ.

Wọnyi ni awọn ẹsun mẹwaa naa bi kootu ṣe fi kan wọn

  • Ẹsun Akọkọ:

Ẹyin mẹtẹẹta ti ẹ jẹ agbalagba ti ẹ si wa lati ijọba ibilẹ Suleja, ipinlẹ Niger, ledi apo pọ pẹlu Muhammad Sani, Jibril Mohammed ati Ibrahim Khabab, lati ji awọn akẹkọọ ati awọn olukọ gbe nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo, laaarin oṣu Kin-in-ni si Ikarun-un ọdun 2026.

  • Ẹsun keji: Ṣiṣe iranlọwọ fun Muhammad Sani, Jibril Mohammed ati Ibrahim Khabab, lati ji awọn akẹkọọ ati awọn olukọ gbe nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo, laaarin oṣu Kin-in-ni si Ikarun-un ọdun 2026.
  • Ẹsun kẹta: Iranlọwọ lati ri i pe ijinigbe naa kẹsẹjari.
  • Ẹsun kẹrin: Didakẹ lai ke gbajare lẹyin ti ẹ ti gbọ pe agbesunmọmi ni Muhammad Sani, Jibril Mohammed ati Ibrahim Khabab, to si jẹ awọn ni wọn pilẹ ijinigbe naa.
  • Ẹsun Karun-un: Bibo aṣiri agbesunmọmi tako abala 16(1) ofin igbesunmọmi ọdun 2022, o si ni ijiya labẹ ofin kan naa.

Ẹsun kẹfa

  • Jijẹ ọmọ ẹgbẹ Darul Salam, ẹka Jamaatu Asarul Muslima Fi Bilandis Sudan (Ansaru), eyi ti ijọba ti ka si ẹgbẹ agbesunmọmi ni Naijiria.
  • Ẹsun keje: Pe Abdulrazak Umar n kọ awọn agbesunmọmi lẹkọọ iṣẹ wọn loju opo Whatsapp to da silẹ, eyi ti wọn pe ni "The oneness of Allah is the Foundation of Peace".
  • Ẹsun kẹjọ:

Pe bi Abdulrazak Umar ṣe n kọ agbesunmọmi lẹkọọ tako abala keji ofin igbesunmọmi ti ọdun 2022.

  • Ẹsun kẹsan-an:

Pe Abdulrazak Umar n kọ awọn ọmọ ẹgbẹ ori ẹka Whatsapp naa lẹkọ lati ji giri si igbesunmọmi.

  • Ẹsun kẹwaa:

Pe Abdulrazak Umar, wa goolu lati inu ilẹ laaarin ọdun 2024 si 2026 lagbegbe Chaza, nijọba ibilẹ Suleja, ipinlẹ Niger lọna aitọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn afurasi yii yoo tun foju ba kootu lọsẹ to n bọ, bi iwadii ṣe n tẹsiwaju.

Ìjọba fojú mẹ́ta lára àwọn afurasí agbésùnmọ̀mí tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé l'Ogbomoso hàn nílé ẹjọ́

Ijọba apapọ ti foju mẹta ninu awọn afurasi agbesunmọmi ti wọn ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ gbe lọ ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso han nile ẹjọ giga apapọ l'Abuja lonii ọjọ kẹtadinlogun oṣu Keje yii.

Awọn afurasi mẹta ọhun, Abdulrazak Umar, Yunusa Musa ati Shamsu Adamu Sani ni ijọba ti fẹsun onikoko mẹwaa to da lori igbesunmọmi, ijinigbe, fifi ọrọ pamọ ati wiwa kusa lọna aitọ kan.

Oni ọjọ Ẹti ni ijọba fawọn ẹsun naa kan wọn nile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe Umar lo n jẹ Abu Khalifa, nigba ti Musa n jẹ Yunusa bin Musa, Sani si n jẹ Abu Itisar.

Ijọba ibilẹ Suleja ni ipinlẹ Niger lawọn mẹtẹẹta ti wa.

Igbimọ olupẹjọ sọ fun ile ẹjọ pe awọn afurasi mẹtẹẹta gbimọ pọ pẹlu ọkunrin kan to n jẹ Muhammad Sani, Jibril Mohammed ati Ibrahim Khabab laarin oṣu Kinni si Ikarun un ọdun 2026 yii lati ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe nile ẹkọ girama Esinele ati Yawota nijọba ipinlẹ Oyo.

Wọn ni awọn ẹsun yii lodi si nnkan to wa ni abala 26(1) iwe ofin Naijiria lori ọrọ igbesunmọmi.

Ijọba apapọ tun fẹsun kan awọn afurasi mẹtẹẹta naa pe awọn lo ṣagbatẹru ijinigbe Oriire, ati pe wọn tun kọ lati sọrọ nipa awọn to ji awọn akẹkọọ ati olukọ naa gbe ni ijọba ibilẹ Oriire.

Ifarahan yii waye lẹyin ọsẹ kan tawọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe ni Oriire gba ominira.

Ni ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un ọdun yii lawọn ajinigbe naa ya wọ ilu Esinele ati Yawota l'Ogbomoso nibi ti wọn ti ji akẹkọọ mọkandinlogoji ati olukọ meje lọ.

Àwọn ajínigbé ṣekúpa sọ́jà, Amotekun, ọlọ́dẹ àti olùkọ́ méjì nínú igbó, Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ Esinele sọ ìdí tí wọ́n fi pa àwọn olùkọ́

Ṣaaju ni ọga agba ile ẹkọ girama Esinele, Arabinrin F.R. Alamu ti sọ pe iriri to buru jai ni a ni ninu igbo pẹlu awọn ajinigbe.

Arabinrin Alamu ni ''awọn ajinigbe naa dẹru ba wa, wọn tun sọ wa pe ijọba ti gbagbe wa sinu igbo.

Wọn maa n lo foonu wọn lati ba oriṣiiriṣii awọn eeyan sọrọ.

Arabinrin Alamu sọ pe nnkankan tawọn gbagbọ ni pe awọn ọmọ Naijiria n gbadura fawọn.''

Ọga ile ẹkọ girama Esinele fikun ọrọ rẹ pe ọjọ keji ti wọn ko awọn de inu igbo lawọn ajinigbe naa ṣekupa ọkan lara awọn olukọ ti wọn ji gbe , oloogbe Michael Oyedokun.

Arabinrin Alamu ṣalaye pe wọn pa awọn olukọ meji lati le jẹ ki ijọba fun wọn ni nnkan ti wọn n beere fun un.

O ni nigba tawọn gbominira tan lawọn to mọ wi pe gbogbo agbaye lo fẹ kawọn bọ lọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Apa ti wa ni ara wa bayii, amọ, a gbagbọ wi pe apa naa yoo san nigba to ba ya.

Arabinrin naa dupẹ lọwọ ijọba, awọn ẹṣọ eleto aabo ati gbogbo eeyan ti wọn kopa kan tabi omiran lati ri pe wọn gbominira lọwọ ajinigbe.