Oluwo dá ẹgbẹ́ lọ́balọ́ba lẹ́kùn ìdìbò Ìwọ̀ oòrùn Osun sílẹ̀, di alága láéláé, àwọn ọba míì fi èrò wọn hàn

Oluwo ti ilu Iwo wọ aṣọ olomi aro, o n wo ọọkan , awọn ọba meji wa lẹgbẹẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Abdulrasheed Akanbi Telu/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn lọbalọba ni ẹkun iwọ oorun ipinle Osun ti gbe igbimọ lọbalọba ẹkun naa dide ti wọn si fi Oluwo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ṣe alaga rẹ.

Fidio kan to wa loju opo Facebook Oluwo ti ilẹ Iwo, ni wọn ti kede igbesẹ naa.

Akọle to wa lori fidio naa sọ pe Akire ti ilu Ikire Ile, Oba Azeez Olatunbosun lo da aba lati gbe igbimọ naa kalẹ, ti Alawo ti ilu Awo si ṣikeji rẹ.

Akọle ori fidio naa ni ibẹ naa ni wọn ti dabaa lati fi Oluwo ṣe alaga laelae fun awọn lọbalọba naa.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, agbenusọ Oluwo, Alli Ibrahim ṣalaye pe awọn ọba to wa ni ẹkun iwọ oorun Osun ni wọn woye pe o yẹ ki iṣọkan wa laaarin gbogbo wọn, ti wọn si da labaa lati da igbimọ naa sile.

Ibrahim ni awọn ọba naa ni wọn pinnu lati gbe igbimọ naa kalẹ lasiko ti wọn lọ ṣe ṣiṣe kan ni aafin Oluwo.

"Kii ṣe Oluwo lo beere fun idasilẹ igbimọ yii, ọtọ ni nnkan ti wọn wa ṣe laaafin lọjọ naa, wọn wa wo o pe ohun to le mu Oluwo ko wa jọ bayii ko le de ti a ko le fi ni igbimọ lọbalọba ni Osun West ko wa jẹ awokọṣe fawọn ọba ni ipinlẹ Osun ati ilẹ Yoruba."

Agbẹnusọ Oluwo naa ṣalaye pe awọn ọba naa fẹnuko lati yan Oluwo gẹgẹ bi alaga wọn nitori oun ni ọba ipilẹ kan ṣoṣo to wa ni ẹkun iwọ oorun Osun.

Awọn ọba to wa nibi ijokoo ti wọn ti gbe igbimọ naa dide

Oríṣun àwòrán, Abdulrasheed Akanbi Telu/Facebook

Ki ni ojuṣe igbimọ lọbalọba yii?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ibrahim ṣalaye pe koko iṣẹ ti igbimọ yii maa gbajumọ ni bi iṣọkan ṣe maa wa laaarin awọn lọbalọba to wa ni ẹkun naa.

O ni ọpọ wọn gbe igbimọ naa dide lati ṣe atunṣe awọn iṣẹlẹ to ti waye laye atijọ nigba ti awọn ọba n ṣatilẹyin fun owo ẹru.

O sọ pe igbimọ naa yoo tun wa fun lati maa beere fun ẹtọ awọn lọbalọba yii lọwọ ijọba.

Ibrahim woye pe niṣe ni awọn eeyan maa n foju ibẹru wo aafin laye atijọ ati lawọn ilu kan nilẹ Yoruba, o ni igbimọ naa yoo ṣe igbelarugẹ fun fifi aaye gba awọn araalu lati le maa yọju si aafin gẹgẹ bi Oluwo ṣe maa n faaye gba.

Nigba to n sọrọ lori idasilẹ igbimọ yii yatọ si igbimọ lọbalọba ipinlẹ Osun to ti wa tẹlẹ, Ibrahim ni oju ọrun to ẹye fo lai fi ara kan ara wọn ati pe ojuṣe igbimọ mejeeji ko tako ara wọn.

O fi kun pe ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Osun ni igbimọ tuntun naa wa fun, ti ko si ni nnkankan ṣe pelu igbimọ lọbalọba to ti wa tẹlẹ.

Agbẹnusọ Oluwo naa tẹsiwaju pe gbogbo awọn ọba to wa ni Osun West ni wọn faramọ igbimọ naa ati iyansipo Oluwo gẹgẹ bi alaga igbimọ naa, o ni awọn ko i tii gbọ pe ọba kankan ko faramọ agbedide igbimọ naa.

Ki ni ero awọn ọba mii lori agbedide igbimọ lọbalọba lẹkun iwọ oorun Osun?

Amọ nigba ti BBC News Yoruba kan si Agbowu ti ilu Ogbaagba, Ọba Dhikrullahi Akinropo ti oun naa wa ni ẹkun iwọ oorun Osun sọ pe ko mọ nnkankan nipa igbimọ naa ati pe oun ko si nibi ijokoo ti agbedide igbimọ naa ti waye.

Nigba to n dahun ibeere boya o faramọ idasilẹ igbimọ naa, Ọba Akinrọpo ni oun ko le sọ ohunkohun nipa rẹ nitori oun ko mọ nnkan ti igbimọ naa dale lori.

"Ki eeyan to le sọ pe oun yoo ṣe nnkan, a gbọdọ jọ jokoo jiroro rẹ, ki ni ibẹrẹ, ki lopin? ki lo bii?

"Nigba ti mi o si nibi ijokoo naa mi o le sọ ki lo bi."

Orangun ti Oke-Ila, Oba Adedokun Abolarin nigba to n sọrọ lori igbimọ naa sọ pe bi o tilẹ jẹ pe oun ko si ni ẹkun iwọ oorun Osun ni awọn Ọba naa ni ẹtọ labẹ ofin lati gbe igbimọ dide lati ja fun ẹtọ wọn.

Orangun ni oun ko le sọ ohunkohun nipa igbimọ yii nitori oun ko si lara wọn, ti oun ko si mọ idi ti wọn fi gbe e kalẹ ati pe oun mọ nnkankan nipa rẹ.