"APC ló ń pàwọn èèyàn l‘Osun torí wọn kò le borí ìbò, irọ ni, Accord lẹgbẹ́ apànìyàn, tó dá aṣọ APC láti máa dàlúrú"

Àkọlé fídíò, "APC ló ń pàwọn èèyàn l‘Osun torí wọn kò le borí ìbò, irọ ni, Accord lẹgbẹ́ apànìyàn, tó dá aṣọ APC láti máa dàlúrú"
"APC ló ń pàwọn èèyàn l‘Osun torí wọn kò le borí ìbò, irọ ni, Accord lẹgbẹ́ apànìyàn, tó dá aṣọ APC láti máa dàlúrú"
Published

Bi eto idibo gomina se n sunmọ ni ipinlẹ Osun, ni iwa jagidi-jagan oselu naa n fẹju si.

Aawọ oselu naa ko si sẹyin awọn alatilẹyin fẹgbẹ oselu Accord ati APC nipinlẹ naa.

Ni ọjọ Ẹti to kọja yii lasan, ọpọ mọto ni wọn bajẹ ladugbo Idi Sẹkẹ nilu Osogbo tori ija oselu

Ọpọ eeyan lo ti ku nitori ija oselu naa, ti amimọye dukia si ti sofo danu lasiko tawọn oloselu naa ba wọya ija.

Koda, iye eeyan to ti farapa ko ni onka nitori ija oselu naa eyi to n mu ki ọpọ eeeyan maa kọminu pe eto idibo to n bọ naa yoo kẹsẹ jari.

Idi ree ti BBC News Yoruba fi mori le ipinlẹ Osun lati fọrọ wa awọn oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oselu mejeeji to n gbogun tira wọn naa, lẹnu wo.

A fẹ mọ ẹgbẹ oselu ti aje iwa ipaniyan ati idaluru yii si mọ lori amọ se ni awọn mejeeji n naka aleebu sira wọn.

Oludije gomina fẹgbẹ oselu APC, Bola Oyebamiji aọ asọ alawọ buluu, o si de fila asọ oke alawọ buluu naa, o durp sẹgbẹ́ gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke to wọ ankara alawọ buluu ati goolu to jẹ toke tilẹ ati agbada rẹ, o si tun de fila asọ oke olomi buluu ati goolu naa

Awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC lo wa nidi idaluru nipinlẹ Osun tori wọn mọ pe awọn ko le wọle ibo gomina naa – Gomina Ademola Adeleke

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori iwa idaluru, ipaniyan ati fifi dukia sofo to n waye nipinlẹ Osun, Gomina Ademola Adeleke ni ẹgbẹ oselu APC lo wa nidi isẹlẹ naa.

"Ẹ wo ẹnu ilẹ, ẹ wo ẹnu ọkọ, APC ti mọ pe oun ko le wọle ti a ba di ibo gomina naa ni oni yii, to si lọ bo se yẹ, wọn ko le bori laelae.

Wọn wa ro pe o yẹ ki awọn maa dẹru bawọn eeyan wa, se iyẹn dara fun awọn eeyan to ni awọn fẹ wa se ijọba, ti wọn wa n pa awọn eeyan?

Irọ ni APC n pa pe awa Accord la wa nidi idaluru naa, sebi ẹnikan wa ti wọn n pe ni Asiri, to gbe igi, ọkọ Ambọ lọ se idaluru.

Irọ wọn ti pọju, emi ti mo jẹ olori, mo ni ibẹru Ọlọrun, n ko ni gba ki wọn maa pa eeyan, ki ni wọn n pawọn eeyan fun?

Kaka bẹẹ, maa ya ni ki wọn gba nnkan wọn, eyi ti mo se ti to dipo ki ẹ maa pa eeyan, emi ko fẹ iyẹn.

Abi ki ni wọn n ta ẹjẹ eeyan si, wọn si n pawọn eeyan kaakiri."

Eeyan meji to farapa nibi idaluru to waye ni ipinlẹ Osun sun sori ibusun nile iwosan pẹlu oniruuru ọgbẹ ara wọn ti wọn so bandeji mọ

Oríṣun àwòrán, Others

"Ọga agba ọlọpaa wa bẹ mi wo, ti a si tahun sira wa gan ni, awọn ọlọpaa ko mu ẹnikẹni lori ipaniyan naa amọ nisinsin yii, mo gbọ pe wọn ti mu eeyan bi ọgbọn si atimọle."

Gomina Ademola Adeleke, ti awọn eeyan tun n pe ni imọlẹ salaye pe oun ti pariwo sita nitori awọn isẹlẹ idaluru ati ipaniyan naa.

O ni oun ti pariwo gan, ti isẹlẹ naa si ti n lọ silẹ lẹnu ọjọ mẹta yii.

"Olori ileesẹ ologun wa bẹ mi wo, bakan naa ni ọga agba ọlọpaa wa bẹ mi wo, ti a si tahun sira wa gan ni.

Koda, mo tun pariwo sita fawọn ologun pe ki wọn gba wa, ti wọn si pinnu lati maa lọ kaakiri lati ri pe gbogbo rogbodiyan naa wa silẹ.

Gbogbo igba ti wọn n pa eeyan kiri yẹn, awọn ọlọpaa ko mu ẹnikẹni amọ nisinsin yii, mo gbọ pe wọn ti mu eeyan bi ọgbọn si atimọle."

Gomina Adeleke wa sẹ lori ẹsun pe ẹgbe oselu Accord lo n da asọ APC sawọn eeyan lọrun lati maa pawọn eeyan kiri.

"Ẹni to ba sẹ, ki wọn mu si atimọle ọlọpaa, koda, to ba jẹ ọmọ mi, emi ko le gba igbakugba rara.

Accord la mọ gẹgẹ bi ẹgbẹ apaniyan, ẹgbẹ APC kii se ẹgbẹ jagidi-jagan – Bola Oyebamiji

Nigba ti oun naa n ba BBC News Yoruba sọrọ, Alhaji Bola Oyebamiji tii se oludije sipo gomina fun ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Osun, wa tako gomina Ademola Adeleke.

Oyebamiji, ti ọpọ eeyan mọ si Ambọ salaye pe kii se ẹgbẹ oselu APC lo n pa eeyan, amọ ẹgbẹ oselu PDP to parada di Accord bayii lo wa nidi isẹlẹ idaluru naa.

"Ni ọdun 2022, ti a fẹ seto ipolongo ibo, awọn ẹgbẹ oselu PDP to di Accord bayii ko tiẹ jẹ kawọn eeyan wa wọ awọn ilu kan rara.

Awọn eeyan wa ti wọn ti pa le ni marundinlọgọta nigba yẹn, Accord la mọ gẹgẹ bi ẹgbẹ apaniyan, ẹgbẹ APC kii se ẹgbẹ jagidi-jagan.

Ẹgbẹ awọn eeyan to leto ni wa, ẹgbẹ awọn agblagba ati ẹgbẹ awọn ọlọpọlọ pipe ni, ko si ẹnikan, ti a le sọ pe APC pa.

Eeyan kan to farapa nibi idaluru to waye ni ipinlẹ Osun sun sori ibusun nile iwosan pẹlu oniruuru ọgbẹ ara wọn ti wọn so bandeji mọ

Oríṣun àwòrán, Others

"Awọn Accord lo n da asọ APC si ara mọto lati fi huwa ọdaran, ọwọ ti dun wọn, awọn ara Osun ti mọ pe wọn kii se ijọba ti awọn le tẹle."

Bakan naa bi Oyebamiji salaye pe isẹlẹ idaluru ati ipaniyan to n waye ni ipinlẹ Osun naa ko de bawọn lojiji ninu ẹgbẹ oselu APC tori awọn ti kẹẹfin rẹ tẹlẹ pe o le waye.

"Sugbọn a ti sọ fun awọn agbofinro tẹlẹ nibi osu kan si asiko yii pe, a ti gbọ pe awọn Accord ti fẹ maa da asọ APC si ara mọto lati maa fi huwa ọdaran kaakiri.

A ti kọ lẹta sawọn ọga ọlọpaa, ọtẹlẹmuyẹ DSS atawọn ileesẹ Civil Defense pe onibara awọn Accord n bole bọ, a si mọ pe wọn fẹ maa gbe igbesẹ idaluru naa.

Idi ti wọn fi n se bẹẹ ni pe ọwọ ti dun wọn, awọn ara Osun patapata ti mọ pe wọn kii se ijọba ti awọn le tẹle."

Oyebamiji ni isejọba ti dun mọ Accord pupọ ju, wọn ko si fẹ fi apere ijọba silẹ ni wọn se n paniyan kiri.

O ni ẹgbẹ APC kọ lo n pawọn eeyan, awọn Accord lo n pa eeyan.