Aisha Achimugu, bọ̀rọ̀kìnní obìnrin tí iléẹjọ́ gbẹ́sẹ̀lé ẹ̀ṣọ́ ara àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí owó rẹ̀ tó ₦8.9bn lẹ́yìn tí EFCC fí ẹ̀sùn kíkọ́rọ̀ jọ lọ́nà èrú kàn án

Oríṣun àwòrán, efcc/x/Aisha Achimugu
L'Ọjọbọ ọsẹ yii ni ile-ẹjọ giga to wa niluu Abuja paṣẹ pe ki ijọba apapọ gbesẹ le gbogbo dukia olowo iyebiye to jẹ ti gbajugbaja olokoowo nni, Arabinrin Aisha Achimugu.
Awọn dukia naa bii ẹṣọ ara to din diẹ ni biliọnu marun-un owo naira (N4,645,170,294.90), ọkọ bọginni mọkanla to le ni biliọnu mẹrin (N4.293) owo naira ati ẹgbẹrun lọna aadọta owo dọla, to fi mọ miliọnu lọna ogbọn naira, eyi ti wọn ba ninu ile rẹ.
Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ Naijiria, EFCC wọn fidi iroyin naa mulẹ f'awọn akọroyin lẹyin ti idajọ naa waye lori ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan an.
Atẹjade ọhun ti agbẹnusọ wọn, Dele Oyewale fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe ile-ẹjọ gbọ ẹbẹ wọn lori ẹsun iwa jibiti, ajẹbanu ati gbigbe owo rin lọna aitọ, eyi ti awọn fi kan an.
O sọ pe Onidajọ Jude Onwugbuzie lo gbe idajọ ọhun kalẹ, eyi to lo tun jẹ aṣeyọri tuntun lara agbekalẹ ati ilana ajọ EFCC lati gbogun ti gbogbo awọn to lọwọ si iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii.
Oniruuru iwa gbigbe owo nla rin lọna aitọ ni wọn fi tọpinpin Achimugu ninu iṣẹ iwadii to jinlẹ, ko to di pe aṣiri rẹ tu si EFCC lọwọ.
Taani Aisha Achimugu

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook
Aisha Sulaiman Achimugu ni apeja orukọ rẹ, ọjọ kejilelogun, oṣu keje, ọdun 1974 ni wọn bi i sinu idile Captain JEA Adole ati arabinrin Adole. Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ofu nipinlẹ Kogi ni obinrin yii.
O bẹrẹ irin ajo rẹ nile-ẹkọ girama Federal Government Girls' College of Science to w ani kuje niluu Abuja, ko to di pe o lọ si fasiti ipinlẹ Jos, nibi to ti kẹkọọ-gboye nipa eto iṣuna, iyẹn lọdun 1998.
Obinrin naa tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ ni fasiti Belize, nibi to ti kẹkọọgboye Masters lọdun 2010, to si tun gboye Ọmọwe ni fasiti Commonwealth ni Belize.
Odu ni Aisha Achimugu, kii ṣaimọ f'oloko lagboole okoowo nilẹ Naijiria, oun si ni oludasilẹ awọn ileeṣẹ bii Felak Concept Group ti wọn wa lẹka imọ-ẹrọ, epo rọbii, omi, ati ikansira-ẹni ti imọ-ẹrọ (ICT).
Lara awọn ileeṣẹ to wa labẹ ileeṣẹ Felak Concept Group ni Oceangate Engineering Oil & Gas Limitied ati awọn miran ti ajọ EFCC sọ o fi n lu jibiti.
Yatọ si eyi, Aisha tun jẹ gbajugbaja ẹlẹyinju aanu to ti ṣe iranwọ pupọ fun awọn eeyan, paapaa nipinlẹ Kogi, lara eyi to ṣagbekalẹ eto owo iranwọ ẹgbẹrun lọna ogun fun ẹẹdẹgbẹta idile.
Oniruuru amieyẹ idalọla ni Aishat ti gba lori awọn akitiyan rẹ lẹka eto okoowo ati eto ironilagbara kaakiri.
Báwo ni àṣírí àwọn dúkìá náà ṣe tú sọ́wọ́ àjọ EFCC?

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ibeere yii lo n wa sọkan awọn ọmọ Naijiria, nigba ti wọn gbọ nipa bi ile-ẹjọ ṣe gbẹsẹ le awọn dukia olowo iyebiye yii, to si ti di ohun ariwisi kaakiri igboro.
Gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, EFCC ṣe ṣalaye ninu atẹjade ti wọn sfi sita, wọn ni olobo kan lo tẹ awọn lọwọ nipa bi obitibiti owo ṣe n fo kaakiri lawọn aṣuwọn ile ifowopamọ mẹrindinlogoje (136) ti wọn tọpinpin rẹ de ọdọ Aishat Achimugu.
Latigba naa ni ajọ EFCC ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ kulẹkulẹ awọn ibi ti owo naa ti n jade, ati awọn ibi to n wọlẹ sii.
Ajọ naa sọ pe awọn oniṣẹ iwadii ṣawari oniruuru owo to le ni biliọnu naira ati miliọnu owo dọla, to n lọ kaakiri awọn apo aṣuwọn ileeṣẹ to nii ṣe pẹlu gbajugbaja oniṣowo naa
Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn owo to n lọ kaakiri yii ni ko si ninu akọsilẹ eto iṣuna ti awọn ileeṣẹ naa n gbe lọ fun ileeṣẹ to n ri si eto ipawowọle nilẹ Naijiria, FIRS lọdọọdun.

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook
Lẹyin ti awọn aṣiri iwadii naa tu, ni ajọ EFCC gba ile-ẹjọ lọ, lati lọ gba aṣẹ nipa bi wọn yoo ṣe lọ yẹ ile obinrin naa wo, lati le ran iṣẹ iwadii wọn lọwọ, ti ile-ẹjọ si gba fun wọn.
Gbara ti wọn de ile agba olokoowo ilẹ Naijiria yii, ni wọn tib a oniruuru ẹṣọ ara olowo iyebiye, ọkọ bọginni olowo iyebiye ati awọn owo nla-nla, eyi ti ile-ẹjọ pada gbẹsẹ le fun ijọba apapọ.
Bakan naa, EFCC sọrọ sita pe laaarin asiko ti iṣẹ iwadii awọn n lọ lọwọ, wọn sọ fun obinrin naa lati sọ gbogbo ohun to ni nigbesi aye rẹ, ṣugbọn ti ko mẹnuba awọn dukia wọnyi, eyi tii ṣe awọn ẹṣọ, ọkọ bọginni ati owo, mọ ara awọn dukia rẹ.
Kete ti awọn aṣiri yii tit u, ni ajọ EFCC ti bẹrẹ sii fi oju rẹ bai le-ẹjọ, ṣugbọn ti igbẹjọ n sun siwaju, pẹlu bi iṣẹ iwadii ṣe n lọ siwaju sii, ko to di pe idajọ ododo pada waye.
EFCC sọ ọ di mimọ pe awọn owo to n fo kaakiri naa ni ko wa lati okoowo ti wọn ṣe labẹ ofin, bẹẹ si ni gbogbo awọn dukia ti wọn gba ni wọn ko fi owo okoowo to mọ ra.
Báwo ni Achimugu ṣe di ẹni tí wọ́n n fi ojí 's lára?

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook
Inu oṣu Kinni, ọdun 2024 ni ọrọ Aishat Achimugu jade sori ikanni ayelujara, lẹyin ayẹyẹ ọjọ ibi aadọta ọdun rẹ to ṣe lorileede Granada, nibi ti awọn ilu-mọn-ọn-ka lẹka eto oṣelu, okoowo ati bẹẹbẹẹlọ, to fi mọ Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ti peju.
Nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọhun la gbọ pe wọn tib a owo ninu jẹ, to si di ohun ti awọn eeyan n beere nipa iru ẹni ti obinrin naa jẹ.
Bo tilẹ jẹ pe oniruuru iroyin lo ti jade nipa awọn irin-ajo Gomina Babajide Sanwo-Olu si awọn agbegbe ti wọn n pe ni Caribbean Island lasiko pọpọṣinṣin ọdun, ṣugbọn to sọ pe fun idagbasoke ipinlẹ Eko ni.
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2025 ni ajọ EFCC kede Achimugu gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa, lori ẹsun iwa jibiti to nii ṣe pẹlu owo ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ, ati paapaa ileeṣẹ MBA Trading and Capital Limited ti wọn lo mọ nipa rẹ.
Kete ti ajọ EFCC fi orukọ rẹ sita, ni Achimugu ti gba ile-ẹjọ giga apapọ lọ niluu Abuja lati da ajọ naa lọwọ kọ lati gbe e, pẹlu bo ṣe sọ pe wọn n dunkooko mọ ẹtọ oun labẹ ofin.
Ṣugbọn ṣa, Onidajọ Inyang Ekwo pa a laṣẹ pe ko fi ara rẹ han niwaju ile-ẹjọ fun ifọrọwanilẹnuwo.
Gbara ti obinrin naa wọ Naijiria lati irin-ajo rẹ si ilu London ni ajọ EFCC ti gbe e ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe International to wa niluu Abuja.

























