CBN kéde ẹni tó pàṣẹ pé kí wọn ṣí àkáǹtì fún ayédèrú iléeṣẹ́ PFIPC lábẹ́ Adeniyi Adeyemi, bí Gbajabiamila ṣe ń rojọ́ níwájú àjọ ICPC

Femi Gbajabiamila wọ kootu olomi buluu, Ọmọba Adeniyi Adeyemi wọ agbada funfun

Oríṣun àwòrán, Femi Gbajabiamila/X/Bayo Onanuga/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Adari oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ, Femi Gbajabiamila, ti lọ sọ tẹnu rẹ niwaju ajọ ICPC to n gbogun ti iwa ibajẹ lori ọrọ ayederu ajọ Presidential Foreign Intervention Promotion Council (PFIPC) ti Ọmọba Adeyemi Adeniyi n jẹjọ le lori.

Gbajabiamila farahan niwaju ajọ ICPC lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu paṣẹ pe ki ajọ naa ṣe iwadii finifini lori ọrọ naa.

Jiti Ogunye to jẹ agbẹjọro adari oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ sọ pe onibaara oun yọju lati pa aṣẹ ICPC to ranṣẹ pe e mọ.

Ogunye ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe ‘’adari oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ farahan niwaju ajọ ICPC ni nnkan bii ago mẹta ọsan ọjọ Aje ogunjọ oṣu Keje yii.

Onibaara mi sọ tẹnu rẹ lori awọn ibeere ti wọn bi i, o si pada sẹnu iṣẹ rẹ lẹyin naa.’’

Ti ẹ o ba gbagbe, Tinubu fun ajọ ICPC loṣu kan lati jabọ iwadii rẹ lori ọrọ ayederu ajọ PFIPC.

Ṣaaju ni Aarẹ Tinubu ti paṣẹ fun ajọ ICPC bẹrẹ lori iwadii ayederu ileeṣẹ ijọba PFIPC atawọn ọrọ mii to rọ mọ ileeṣẹ naa laarin ọgbọn ọjọ pere.

Agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga, sọ ninu atẹjade kan pe Aarẹ ni oun gbọdọ gba esi abajade iwadii naa laarin ọgbọn ọjọ ọhun.

Onanuga sọ pe aṣẹ yii waye lẹyin ti aṣiri tu nipa ileeṣẹ ọhun ti Aarẹ sọ pe oun ko mọ nipa rẹ tabi buwọlu lati maa ṣiṣẹ lorukọ oun.

Koko awọn ohun ti ijọba fẹ ṣe iwadii rẹ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Atẹjade agbenuso aare fi sita sọ pe Tinubu paṣẹ ki wọn ṣe iwadii iwe igbanisiṣẹ ti adari ajọ ofege naa, Adeniyi Adeyemi Mathew, n lo.

•Iwadii naa yoo tun tu pẹrẹpẹrẹ bi ọgbẹni Adeniyi Adeyemi Mathew ṣe ri iwe igbanisiṣẹ lati ọọfisi Aarẹ titi to fi di ẹni to n ṣoju ijọba Naijiria niwaju awọn aṣoju ijọba ilẹ okere mii.

•Ijọba yoo tun ṣewadii bo ṣe n gba fisa lorukọ rẹ, bo ṣe ṣi oniruru apo iṣuna lawọn ile ifowopamọ atawọn nnkan mii.

•Onanuga tun tẹsiwaju pe Aarẹ fẹ mọ ohun to fun afurasi naa ni igboya atawọn nnkan mii to rọ mọ bo ṣe ri iwe igbanisiṣẹ ijọba apapọ gba lorukọ ijọba.

•Atẹjade naa sọ pe "Iwadii naa yoo tu aṣiri bo ṣe ri ati bo ṣe n lo ayederu iwe lati ṣoju ijọba; bo ṣe ṣi awọn apo iṣuna ni oniruru ile ifowopamọ, bi owo ṣe n wọ inu awọn apọ iṣuna naa ati ibi ti owo ọhun ti wa, awọn banki to n lo atawọn to jẹ ki iṣẹ rẹ ṣeeṣe."

•Aarẹ tun paṣẹ ki ICPC ṣewadii awọn kudiẹ-kudiẹ to wa nileeṣe ijọba ti afurasi naa gba wọle ati ọna ti yoo fi di awọn kudiẹ-kudiẹ naa ki irufẹ iṣẹlẹ bẹe ma baa waye mọ lọjọ iwaju.

•Gẹgẹ bo ṣe sọ, Aarẹ paṣẹ fun gbogbo ileeṣẹ ijọba ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ICPC ninu iwadii naa ki wọn si fun ajọ naa ni ohun to ba bere fun iwadii rẹ.

CBN ṣalaye bi wọn ṣe ṣi akanti fun ayederu àjọ PFIPC

Banki apapọ Naijiria, CBN, ti ṣalaye fun ile igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja wi pe lati ọfiisi oluṣiro owo agba ni Naijiria lawọn ti gbaṣẹ pe kawọn ṣi akanti meji fun ajọ PFIPC.

Ọrọ yii jade lẹyin ti adari oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ, Gbajabiamila, lọ sọ tẹnu rẹ niwaju ajọ ICPC lori awọn ẹsun ti Ọgbẹni Adeniyi to jẹ adari ajọ naa fi kan naa lori ọrọ ayederu ajọ PFIPC yii bakan naa.

Adeniyi sọ pe ouns an N400m fun Gbajabiamila lati gbe ipo ọga agba ajọ PFIPC nipasẹ oloogbe Babatunde Dolapo Tanimola.

Ọmọba Adeniyi tun sọ pe Gbajabiamila tun beere fun ida 48% N27.3bn owo ti ajọ naa yoo fi bẹrẹ iṣẹ.

Gbaja ti sọ pe irọ ni Adeyemi n pa, o ti gbe e lọ si ile ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ eyi to fi n beere N15bn owo gba mabinu.

Iwadii tun fihan pe Adeyemi gbasẹ lati ni ọfiisi nile iṣẹ ijọba to wa l’Abuja ati lati ṣi akanti meji pẹlu banki CBN.

Ẹwẹ, Ọga agbaHamisu Abdullahi lati CBN ṣalaye nigba to n sọ tẹnu rẹ niwaju igbimọ ile aṣoju-aṣofin to n ṣewadii ọrọ ajọ PFIPC pe lati ọfiisi oluṣiro owo agba lawọn ti gbaṣẹ lati ṣi akanti meji fun ajọ naa.

Ọgbẹni Abdullahi sọ pe akanti akọkọ jẹ eyi ti owo dọla yoo maa wọ, nigba ti ekeji wa fun owo pọun Ilẹ Gẹẹsi.

O ni ọgbọnjọ oṣu Keje ọdun 2025 ni CBN ṣi akanti mejeeji fun ajọ PFIPC.

Amọ, Abdullahi ṣalaye fawọn aṣofin pe akanti mejeeji naa ko ṣiṣẹ tori ajọ naa kuna lati pese awọn to maa ṣe ibuwọlu fun un.