Salawa Abeni ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Kollington Ayinla

Oríṣun àwòrán, Premium Times
Agbaọjẹ olori Waka, Salawa "Queen of Waka Music" Abeni, ti fesi si ọrọ ogbontarigi olorin Fuji, Kollington Ayinla to ni iyawo oun ṣi ni.
Lẹyin ọdun kan o le diẹ ti Kolington to sọrọ naa ni Salawa to fi ọrọ rẹ tirẹ lede ninu ifọrrọwerọ kan pẹlu Oyinmomo TV.
Ninu oṣu Karun un, ọdun 2025 ni Kolington sọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu Teju Babyface pe Salawa Abeni kii ṣe ọrẹbinrin tabi ale oun bi ko ṣe iyawo ti oun fẹ niṣu-lọka ati pe iyawo oun ṣi ni.
Bi irinajo Salawa Abeni ati Kollington Ayinla ṣe lọ
Lẹyin ti Salawa kọ oludasilẹ ileeṣẹ orin, Lateef Adepoju, silẹ lọdun 1986 loun ati Kollington fẹ ara wọn.
Ọmọ meji lo bi fun Adepoju nigba to bi ọmọ mẹta fun Kollington ki igbeyawo wọn to fori ṣọpan lọdun 1994.
Lẹyin to fi Adepoju silẹ lọdun naa lọhun lo fi ileeṣẹ orin rẹ silẹ to si darapọ mọ ileeṣẹ orin Kollington nibi to ti gbe awo orin I Love You (1988) ati We Are the Children jade lọdun 1989.
Nigba ti yoo di ọdun 2023 ni Salawa tun kede ọgbẹni Rasheed Adahunse, to jẹ ọga agba ati adari ile ẹkọ Nigeria Customs Training College, gẹgẹ bii ọkọ rẹ.
Ẹwẹ, ni ti Kolington, oniruru iyawo lo fẹ, amọ o sọ fun ileeṣẹ iroyin The Nation lọdun 2014 pe iyawo oun ko to mẹẹdogun gẹgẹ bii awọn eeyan kan ṣe n sọ ni igboro.
Ohun ti Salawa Abeni sọ
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu Oyinmomo TV, Salawa Abeni sọ pe oun ko fi igbeywo oun ati Kollington silẹ.
O ni "Nipa igbeyawo emi ati Kollington, mo ka a nibi kan to sọ pe iyawo oun ṣi ni mi.
"Lootọ ni mo bi ọmọ fun amọ kii ṣe emi ni mo fi igbeyawo naa silẹ.
"Kii ṣe ọrọ igberaga, tabi agidi tabi nnkan ti mo ṣe. Iya mi ko ni ọkọ meji, o ni orogun kan. Baba mi nikan ni iya mi bi gbogbo awọn ọmọ rẹ fun.
"Ayanmọ ko le ṣe lai ṣẹ, ki Ọlọrun tẹsiwaju lati maa daabo bo mi."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, iriri ohun to ṣẹlẹ laarin oun ati Kollington wa lara nnnkan to fi gbe awo Experience jade lọdun 1991.
Bo tilẹ jẹ pe ko ṣalaye ni kikun nipa ibaṣepọ oun ati agba olorin Fuji naa lọwọ yii, o fidi rẹ mulẹ pe awọn mejeji ṣi maa n kan si ara wọn nitori awọn ọmọ to wa laarin wọn.


























