Wo àwọn nǹkan mẹ́fà tó ti yípadà lẹ́yìn ìdìbò 2023 tó le nípa lórí ìdìbò 2027

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Uche Akolisa
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11
Bi ọdun 2027 ṣe n sunmọ etile ni awọn ọmọ Naijiria n gbaradi fun eto idibo gbogbogbo nibi ti awọn eeyan yoo ti ni anfaani lati dibo yan aarẹ, awọn gomina atawọn aṣofin ti yoo maa ṣoju wọn.
Lasiko eto idibo ọdun 2023, ọpọ lo gbagbọ pe imọ ẹrọ BVAS ti ajọ to n mojuto eto idiboNaijiria, INEC gbe jade, bi awọn ọdọ ṣe tu jade lati dibo lasiko naa ati bi oludije sipo aarẹ mẹta gboogi ṣe kopa nibi eto idibo naa maa mu ayipada wa ninu eto idibo Naijiria paapaa lojuna ati mu igbooro ba iṣejọba awaarawa ṣugbọn ipenija ti ko mu BVAS naa ṣiṣẹ ja igbagbọ awọn eeyan lori eto idibo naa kulẹ.
Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress jawe olubori nibi eto idibo naa. Awọn alatako rẹ, Atiku Abubakar ti ẹgbe oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ati Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party pe ijawe olubori naa nija nile ẹjọ amọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria fidi rẹ mulẹ Tinubu ni awọn eeyan dibo yan lati di aarẹ.
Ọdun mẹrin mii tun ti de tawọn eeyan yoo tun maa dibo pẹlu gbogbo ayipada to ti waye lẹka oṣelu ati eto ọrọ aje Naijiria. Awọn ofin eto idibo ti yipada, ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba lọwọ ti mu alekun bai bi ti ọwọja wọn de tẹlẹ, tawọn oludibo naa si n koju ipenija ọtun paapaa lori igbeaye, aisi aabo ati ina ọba ti ko duro ire.
Bakan naa ni awọn ọdọ yoo tun maa ko ipa to ṣe koko nibi eto idibo yii.
Awọn ọna mẹfa ree ti ayipada ti ba Naijiria lẹyin eto idibo sipo aarẹ to kọja.
Ofin eto idibo ti yipada
Oniruuru awuyewuye lo waye lasiko eto idibo sipo aarẹ lọdun 2023 bi INEC ko ṣe fi awọn esi ibo ibudo idibo kọọkan soju opo ayelujara bi wọn ti ṣaaju sọ pe awọn maa ṣe lati ṣafihan pe eto idibo naa ko ni eru kankan ninu.
Lasiko awọn eto idibo to waye lọdun 2022, ṣaaju eto idibo gbogbogbo, INEC ṣamulo awọn imọ ẹrọ yii, ti wọn si ṣiṣẹ daadaa amọ ipenija ti INEC sọ pe o waye lasiko eto idibo gbogbogbo mu ki ọpọ ọmọ Naijiria maa kọminu boya eto idibo naa ko ni ẹja n bakan ninu.
Ninu atunṣe ofin eto idibo to waye lọdun 2026, awọn oṣiṣẹ to ba mojuto eto idibo gbọdọ fi esi idibo sori ayelujara lẹyin ti wọn ba ti pari kikọ esi ibo naa sinu fọọmu EC8A, ti wọn si buwọluu gẹgẹ bi abala ọgọta iwe ofin naa ṣe sọ.
Amọ, ofin naa ṣi fi aaye gba lilo fọọmu lati fi kọ esi ibo nibi ti imọ tabi nẹtiwọọki ko ba ti ṣiṣẹ.
Sam Amadi, Adari ile ẹkọ nipa ọrọ awujọ ati oṣelu ni ilu Abuja gbagbọ pe fifi ayafi sabẹ ofin naa le mu ki awọn eeyan ma ni igbagbọ ninu rẹ to.
O ni fifi aaye silẹ fun fifi esi ibo naa ṣọwọ lai lo imọ ẹrọ le mu ki awọn oṣiṣẹ INEC kan ma lo imọ ẹrọ naa ti wọn yoo si fi nẹtiwọọki kẹwọ pe oju opo ayelujara ko se daadaa.
INEC ninu ọrọ wọn sọ pe kii ṣe pe fifi esi ibo sori ayelujara paarọ lilo fọọmu bi ko ṣe pe o je afikun lasan ni. Ọga agba ajọ INEC ni ipinlẹ Edo, Obo Effang sọ pe eto idibo Naijiria si jẹ ohun to maa n waye lai lo imọ ẹrọ ati pe ohun ti wọn ba kọ si inu iwe naa ni wọn maa n ya, ti wọn maa fi sori ayelujara.
Akojọpọ awọn esi idibo lati ibudo idibo ni wọn maa ko papọ ni ijọba ibilẹ de ipele ijọba ipinle titi de ẹka ijọba apapọ. O woye pe ti to ba jẹ pe ofin la a mọlẹ pe dandan ni fifi sori ayelujara, awọn oṣiṣẹ INEC maa wa ọna lati fi sori ayelujara yala oju opo ja gaara tabi bẹẹkọ.
Awọn to n ṣatileyin fun atunto ofin eto idibo naa ni o ṣeeṣe ko mu adinku ba eru to maa n waye lasiko ibo tawọn to n bu ẹnu atẹ lu atunto naa ni fifi esi ibo ṣọwọ lai lo ẹrọ ayelujara le ma mu eto idbo naa kẹsẹ jari.
Ọdun 2027 ni yoo sọ boya awọn atunṣe si ofin eto idibo yii maa mu igboya ba awọn araalu bi awọn eeyan ba ṣe dibo si.
Ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba ti ni akoso awọn ipinlẹ to pọ si
Eto oṣelu Naijiria ni ayipada nla ti ba lati igba eto idibo ọdun 2023.
Eto idibo sipo aarẹ Naijiria to waye ni ọdun 2023 ni eyi to lagbara julọ lati igba ti Naijiria ti pada si eto iṣejọba awaarawa lọdun 1999. Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to n ṣejọba koju oludije gboogi lẹgbe oṣelu PDP ati Labour Party ti oludije wọn, Peter Obi mu ki ọpọ awọn ọdọ kopa ninu eto idibo naa.
Ṣaaju eto idibo 2027, agbara awọn ẹgbẹ oṣelu ti yipada gidi. Fifi ẹgbẹ oṣelu silẹ ti mu ki awọn gomina lẹgbe oṣelu APC jẹ ọgbọn ninu gomina mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria. Igbesẹ yii mu ki awọn eeyan maa kọminu boya Naijiria ti n lọ sọko nini ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo.
Irú agbára òṣèlú báyìí ti wáyé rí. Ní ọdún 2007, Ẹgbẹ́ People's Democratic Party (PDP), tó jẹ́ ẹgbẹ́ tó ń ṣèjọba nígbà náà, ń ṣàkóso ìpínlẹ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (28) nínú ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlogoji (36) tí Nàìjíríà ní.
Àwọn onímọ̀ sọ pé níní àkójọpọ̀ agbára òṣèlú bẹ́ẹ̀, láìfi ẹgbẹ oṣelu to b ani ṣe le mu ikerẹte bae to iṣejọba awaarawa. Ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣatìlẹ́yìn fún un sọ pé àwọn gómìnà máa ń darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń ṣàkóso ìjọba àpapọ̀ láti mú ìbáṣepọ̀ àti rírí ànfààní láti ọwọ́ ìjọba àpapọ̀ pọ̀ si ni.
Eto aabo jẹ ipenija nla

Oríṣun àwòrán, ACLED
Ọ̀rọ̀ ààbò ló jẹ́ kókó pàtàkì nínú ìpolongo ìdìbò ààrẹ ọdún 2023, tó sì tún kókó kan gbòógì tí yóò pinnu bí ìdìbò 2027 ṣe máa rí.
Lọ́jọ́ ìbúra rẹ̀ lọ́jọ́ 29 Oṣù Karùn-ún, 2023, Ààrẹ Bola Tinubu ṣe ìlérí pé ààbò yóò jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn ohun tí ìjọba rẹ̀ máa dojúọ́. Ó sọ pé "àlàáfíà àti ìdàgbàsókè tàbí ìdájọ́ òdodo kò lè wáyé níbi tí àìsí ààbò àti ìwà-ipá bá wà." Ó tún ṣe ìlérí láti tún ètò àti àgbékalẹ̀ ààbò ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe.
Látìgbà náà, ìjọba ti sọ pé wọ́n ti gba ọlọ́pàá tuntun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ogún (20,000) sí iṣẹ́, má àlékún bá owó tí wọ́n ń ná sí ètò ààbò pẹ̀lú mímú àtúntò bá àwọn ipò olórí ẹ̀ka ààbò. Pẹ̀lú gbgbo àwọn ìgbésẹ̀ yìí, ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé, ìgbéṣùmọ̀mí, àti àwọn ìwà-ipá míì ṣì ń tẹ̀síwájú kọjá àwọn agbègbè tí wọ́n ti mọ̀ọ́mọ́ tẹ́lẹ̀ ní àwọn ẹkùn Àríwá Ìlà Oòrùn àti Àríwá Ìwọ̀ Oòrùn, tó sì ti ń tàn wọ àwọn apá kan ní Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn.
Ní Ìpínlẹ̀ Oyo fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ogun ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìtúsílẹ̀ àwọn ènìyàn mẹ́rìndínláàádọ́ta (45) kúrò ní àhámọ́ àwọn ajínigbé tó fi mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkọ́, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) tí wọ́n ti wà nígbèkùn.
Ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ lábẹ́ ìjọba yìí ni jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní 300 lọ láti ilé-ẹ̀kọ́ St. Mary's Private Catholic School ní Ìpínlẹ̀ Niger gbé. Èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ jùlọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Naijiria.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ Acled ṣe sọ, láàárín ọdún 2015 sí 2023, Nàìjíríà ní ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́wàá (10) tí wọ́n ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé, tí iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí ó kàn sì jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méjìlélógójì-dín-lọ́gbọ̀n (1,127). Ní ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́ ìṣèjọba Tinubu, ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé mẹ́sàn-án (9), ló ti wáyé táwọn ènìyàn ti wọn jí gbé sì lé 500.
Ìpa àwọn ìjínigbé yìí kò mọ lórí ètò ààbò nìkan. Ìkọlù sí àwọn àgbègbè ti iṣẹ́ àgbẹ̀ gbokùn níbẹ̀ ti dá ètò ọ̀gbìn rú tó sì mú àlékún bá ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ. Àjọ World Food Programme ṣe àfihàn pé nǹkan bí mílíọ̀nù márùndínlógójì (35 million) àwọn ọmọ Nàìjíríà lè dojú kọ àìrí oúnjẹ jẹ ní ọdún 2026, láti orí mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógún (24.8 million) tó jẹ́ ní ní ọdún 2023.
Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń múra fún ètò ìdìbò míì, ó ṣeé ṣe kí ìpèníjà ààbò jẹ́ ohun kan gbòógì táwọn èèyàn fi máa ṣe ìgbéléwọ̀n ìjọba tó wà lórí ipò báyìí, àti àwọn ìlérí táwọn tí wọ́n ń wá láti rọ́pò rẹ̀.
Awọn ọmọ Naijiria n koju igbe aye to le si

Oríṣun àwòrán, NBS

Samson Itodo, Olùdarí Yiaga Africa, sọ pé: "Gbogbo ọmọ Nàìjíríà tó nífẹ̀ẹ́ sí ìdàgbàsókè àti didara ìgbésí ayé rẹ̀ gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ sí ẹni tí yóò ṣẹ́gun ìdìbò ọdún 2027, nítorí àwọn olórí tuntun náà ni yóò ṣe àwọn ìpinnu òṣèlú àti ètò ọrọ̀ ajé tó máa ní ipa lórí ayé àti ààyè àwọn ọmọ Nàìjíríà."
Lasiko iburawọle fun Ààrẹ Bola Tinubu ló kéde ìfopin sí ètò ìrànwọ́ owó epo, tó sì sọ pé aba isuna ti oun ba ko fi aaye silẹ fun-un. Láti ìgbà náà, ìyọkúrò ètò ìrànwọ́ yìí àti fífi iye owó naira jẹ́ kí ọjà pinnu rẹ̀ ti yí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà padà gan-an, tí ó sì ti mú kí owó ọkọ̀, iye oúnjẹ àti àwọn ináwó ilé pọ̀ sí i.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Ilé Ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà ṣe fi hàn, ọwọngogo ni Naijiria wa ni 24.7% ní ọdún 2023, kí ó tó gòkè dé àkọsílẹ̀ gíga jù lọ tó jẹ́ 37.57% ní Oṣù Kẹjọ ọdún 2024. Ní Oṣù Kiini ọdún 2026, ó ti sọ̀kalẹ̀ sí 17.18%, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣì ń kojú ìnáwó ìgbésí ayé tó ga.
Amòye ètò ọrọ̀ ajé, Boniface Chizea, gbà pé àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà ti túbọ̀ burú sí i láti ìgbà ìdìbò tó kọjá.
Ó tún sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọngogo ti dínkù, "àwọn nǹkan kò burú tó báyìí ní ọdún 2023" gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe rí ní asiko yìí.
Fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà, ìbéèrè tó máa ṣe pàtàkì sí wọn lọ́dún 2027 lè má ṣe dá lórí òṣèlú nìkan, ṣùgbọ́n lórí bóyá ìgbésí ayé wọn ti sunwọ̀n sí i tàbí ti buru sí i lábẹ́ àwọn ìpinnu ọrọ̀ ajé tí ìjọba ṣe.
Ina mọnamọna je ohun tawọn eeyan fi n ṣe igbelewọn iṣejọba
Ipese ina ọba to duro ire jẹ ohun kan tawọn ará Nàìjíríà fi ń díwọ̀n aṣeyọrí ààrẹ wọn, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tawọn eeyan n sọ lori eto idibo 2027.
Nígbà ìpolongo ìdìbò ọdún 2023, Bola Tinubu sọ fún àwọn olùdìbò pé: "Tí mi ò bá fún yín ní iná déédéé, tí mo sì padà wá béèrè fún àkókò kejì, ẹ má dìbò fún mi, àfi bí mo bá fún yín ní ìdí Pataki kí tí mi ò fi lè ṣe é."
Láti ìgbà tó ti gba akoso ijọba, Tinubu ti ṣe àwọn àtúnṣe pàtàkì lẹka iná ọba Nàìjíríà. Òfin Electricity Act àti àtúnṣe sí Òfin Orílẹ̀-Èdè (Constitution) ti jẹ́ kí àwọn ìpínlẹ̀ lè dá iná tiwọn ni, nípa ṣíṣe, fífi ránṣẹ́ àti pínpín iná láì fi bẹ̀ẹ̀ gbarale àkójọpọ̀ amáyédẹrùn iná àpapọ.
Ìjọba tún ti fọwọ́ sí ètò ìrànwọ́ tó tó dọ́là bílíọ̀nù 2.4 ($2.4bn) láti yanjú àwọn gbèsè tó ti pé pẹ́ nínú ẹ̀ka iná mànàmáná. Igbésẹ̀ náà ni láti mú àwọn ilé iṣẹ́ iná dúró ṣinṣin nípa owó àti láti mú kí ìpèsè iná dájú sí i.
Síbẹ̀síbẹ̀, pẹlu àwọn àtúnṣe wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣì ń kojú airi ina lo deede, tí wọ́n si tún ń san owó iná gegege.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé ajọ Tó Ń Ṣàkóso Ẹ̀ka Iná Mànàmáná Nàìjíríà (NERC), Nàìjíríà n pese iná tó ju 4,922 megawatt (MW) lọ ní ọdún 2023. Ní Oṣù Kini ọdún 2026, ìwọ̀n iná tó wà fún pínpín jẹ́ nǹkan bí 4,901MW, láti inú agbára tí a ti fi ṣètò tó jẹ́ 13,625MW.
Bí àwọn ilé àti àwọn ilé iṣẹ́ ṣe ń ṣamulo ẹrọ amúnáwá jẹnẹretọ àti àwọn orísun iná míì lati fi rọpo ina ọba, ó ṣeé ṣe kí iná ọba jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì pàtàkì tí àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò fi ṣe àyẹ̀wò iṣẹ́ ìjọba nígbà tí wọ́n bá padà sí ibudo ìdìbò ní ọdún 2027.
Ipa awọn ọdọ lori idibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ọdọ Nàìjíríà ko ipa pàtàkì nínú eto idibo ọdún 2023, ó sì ṣeé ṣe ko tún ri bẹẹ nibi eto idibo 2027.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé INEC, àwọn ènìyàn tó wà láàárín ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) sí márùndínlogoji (35) jẹ́ ìdá mẹrindínlọ́gọ́rin (76%) àwọn tí wọ́n forúkọsílẹ̀ fún ìdìbò gbogbogbò tó kọja amọ, ìdá ọgbọ̀n péré nínú wọn ló dibo.
Iye àwọn ọdọ tó ń forúkọsílẹ̀ sì ti ń pọ̀ sí i. Nígbà ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò tuntun tó ń lọ nígbà gbogbo (Continuous Voter Registration) ní ọdún 2026, INEC fi àwọn olùdìbò tuntun tó jẹ́ 2,782,589 kún iye 93,469,008 tí a forúkọsílẹ̀ fún ìdìbò ọdún 2023.
Èyí mú kí iye gbogbo àwọn olùdìbò tí o forúkọsílẹ̀ dé 96,251,597 ní Oṣù Kini ọdún 2026. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́rìndínláàdọ́rin (69%) àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ forúkọsílẹ̀ wọ̀nyí ni ọdọ.
Idi tawọn orilẹ ede agbaye mii fi ni iwoye si eto idibo Naijiria

Ìdìbò ọdún 2027 ní Nàìjíríà ṣe pàtàkì kọjá ààlà orílẹ̀-èdè yii nikan. Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tó ní ọ̀pọ̀ ènìyàn jùlọ ní Áfíríkà àti ọ̀kan lára àwọn ọrọ̀ ajé tó tóbi jùlọ lẹkun Africa, àìdúróṣinṣin òṣèlú ní Nàìjíríà lè ní ipa lórí òwò, ìṣílọ àwọn ènìyàn, ààbò agbègbè, àti ìdókoòwò káàkiri Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà àti àwọn agbègbè míì.
Amòye ètò ọrọ̀ ajé, Boniface Chizea, sọ pé ìwọ̀n àti ipa tí Nàìjíríà ní túmọ̀ sí pé àwọn àbájáde ìṣòro òṣèlú tó bá pẹ́ yóò kọjá ààlà orilẹ̀-èdè náà lọ.
Ó ní "Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ṣe pàtàkì gan-an nípa ìlànà àgbáyé. A ní orílẹ̀-èdè tó ní ènìyàn tó lé ní mílíọ̀nù igba (200 million). Kò sí orílẹ̀-èdè ní ayé tí wọ́n ní iye ènìyàn tàbí ilẹ̀ tó tóbi bí ti Nàìjíríà. Nítorí náà, tí ìṣòro òṣèlú, ìfowó pọ̀ gan-an (high inflation), tàbí ìṣílọ àwọn olùgbé síta kúrò ní Nàìjíríà bá ṣẹlẹ̀, yóò da ìdúróṣinṣin agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà rú. Yóò sì tún ní ipa káàkiri ayé, bí a ṣe rí nínú ipò tó wà ní Iran lọwọlọwọ."
Nígbà tí wọ́n bá ń dìbò ní ọdún 2027, ọ̀pọ̀ nínú wọn yóò máa ronú lórí ìbéèrè pàtàkì kan ṣoṣo:
"Ṣé ayé wa dára sí i lónìí ju bí ó ṣe rí nígbà tí a dibò ní ọdún 2023?"





























