Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Published

Ile ẹjọ giga kan nillu Abua ti paṣẹ ki ijọba gbẹsẹ le dukia ti iye rẹ le ni ogoji to jẹ ti agbẹjọro agba Naijiria tẹlẹ, Abubakar Malami

Idajọ yii waye lẹyin ti Malami kuna lati ṣalaye pe ki n ṣe nipa ọna eburu loun fi kọ awọn ọrọ naa jọ

Lara awọn dukia ti ile ẹjọ gbẹsẹle ni mọṣalaṣi, igba eeka ilẹ ati fasiti

Ẹkunrẹrẹ wa loju opo BBC Yoruba

____________________________________________

Awọn onimọ nipa oju ọjọ ti sọ pe o ṣeeṣe ki ojo rọ nipinlẹ Eko lojojumọ fun ọjọ mẹwaa gbako, lati akokoo yii lọ

Wọn ni omiyale yoo waye lawọn agbegbe kan, nigba ti ọjọ naa ko ni milẹ lawọn adugbo mi

Ẹkunrẹrẹ wa loju opo wa

_____________________________________________

Gbọ na, ki lo kan bayii fun awọn olukọ ati akẹkọọ ipinlẹ Oyo lẹyin itusilẹ wọn lakata ajinigbe?

Onimọ nipa ero ọkan ẹda kan, Rhoda Durasawo ti ni awọn eeyan naa nilo iranlọwọ latari ohun ti wọn ti la kọja

Iru iranlọwọ wo niyẹn o?

Ti o ba fẹ mọ ẹkunrẹrẹ