Wo àwọn nǹkan tí Andy Burnham, Olóòtú ìjọba UK tuntun lóun yóò ṣe fún ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi ayipada ṣe n de ba United Kingdom pẹlu bi wọn ṣe ṣẹṣẹ yan Olootu ijọba tuntun ti i ṣẹ Andy Burnham, olori ẹgbẹ Labour naa ti sọrọ fun igba akọkọ nipo yii.

Nigba to n ṣalaye ipinnu ati erongba rẹ fun ilẹ Gẹeṣi, Burnham sọ pe bi orilẹede United Kingdom yoo ṣe duro ṣinṣin lo mumu laya oun to si jẹ oun logun julọ.

Andy to jẹ Olootu keje fun UK lati 2016, sọ pe asiko ironusi bi nnkan ṣe n lọ ni UK ree.

Bẹẹ lo ni o ṣe pataki gan-an fun ilẹ Gẹẹsi lati ri agbara iduroṣinṣin pada lẹẹkan si i.

"Awọn oloṣelu ko ti i daa to bo ṣe yẹ ki wọn daa"

Ni itẹsiwaju ọrọ Olootu UK tuntun naa lo ti ni awọn oloṣelu ilẹ naa ko ti i kare to bo ṣe yẹ.

Andy Burnham ni amọ ayipada nla yoo de yatọ si bi nnkan ṣe wa lati ogoji ọdun sẹyin.

O ṣeleri pe oun yoo bẹrẹ eto lati ọla lọ lati fun araalu ni irọrun lati gbele aye lai si inira.

"Mo maa too gba ibi ilẹkun to wa lẹyin mi yii, ti ma a fi fopin si airilegbe lorilẹede eyi.

"Mo maa fi gbogbo agbara mi ṣe eyi."

Olootu tuntun fun UK naa tun sọ pe nnkan gbọdọ daa ju bo ṣe wa lasiko yii lọ.

O loun yoo ṣeto ọlọdun mẹwaa kan ti yoo mu erongba oun ṣẹ.

Bakan naa lo ni oun yoo kọ ile igbimọ to pọ si i.

Ohun ti maa kọkọ paṣẹ ni fifi opin si airi ile gbe

Pataki ninu ọrọ ti Olootu UK tuntun naa sọ ni pe oun yoo fopin si airilegbe, eyi to n mu awọn eeyan kan maa sun sawọn ibi ti ko yẹ nigboro.

Ṣaaju ni Burnham ti ṣabẹwo sile awọn eeyan ti ko nibugbe gidi kan ni Victoria, Aarin Gbungbun London, eyi to ṣe apẹẹrẹ awọn nnkan to ni oun yoo mu ni koko nipo olootu.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori rẹ, Andy sọ pe ojuṣe gbogbo araalu ni bi awọn yoo ba fopin si asunkiri.

O ṣalaye igbesẹ to gbe lorii rẹ lasiko arun Corona, Andy sọ pe awọn ṣe e nigba naa, o si tun ṣee ṣe bayii.

O ni ipe oun akọkọ nipo Olootu yoo lọ sọdọ Aarẹ America; Donald Trump ati Aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky.

O fi kun un pe atilẹyin UK fun Ukraine ko ni i yingin, ipinnu atilẹyin naa ko si ni I yipada.

Lori awọn nnkan ti Burnham loun yoo ṣe nipo yii, Olootu tuntun naa ni gbogbo ipa loun yoo sa si i.

Iṣẹ yoo bẹrẹ lẹyẹ o sọka, pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe n foju sọna lati mọ awọn ti yoo ba a ṣejọba .

Ta a ni Andy Burnham?

Wọn bi Andy Burnham ni Liverpool ni ọdun 1970, o si dagba si Culcheth, ilu kan nitosi abule Cheshire ti ko jinna si Warrington.

Iya ati baba rẹ jẹ olutẹlẹ ẹgbẹ Labour, wọn si nifẹẹ si oṣelu lati ilẹ.

Burnham funra ẹ sọ pe ọmọ ọdun mẹrinla loun wa toun ti nifẹẹ lati di ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour.

Burnham atawọn ọmọ iya rẹ ọkunrin meji ni won kọkọ lọ sile ẹkọ giga yunifasiti ninu ẹbi wọn.

Oun kẹkọọ nipa ede Gẹẹsi ni Cambridge.

Lẹyin to kawe giga tan, Andy bẹrẹ iṣẹ bii oniroyin.

Laarin asiko to wa lẹni ogun ọdun soke lo moke ninu oṣelu, bẹẹ lo ṣiṣẹ bii oluwadii fun Oloogbe Tessa Jowell to jẹ olootu Dulwich ati West Norwood nigba naa.

Andy pada di oludamọran pataki nipa aṣa fun Chris Smith, ki wọn too yan an sipo MP.

O ti figba kan ṣiṣẹ bii minisita kekere labẹ Blair.

O ti du ipo olori Labour ni 2010, o ṣe ipo kẹrin ninu awọn marun-un to dije.

O tun gbiyanju ni 2015, amọ Jeremy Corbyn gbe e lulẹ.

2017 ni Andy Burnham dupo olori ni Manchester, o yege pẹlu ibo to le ni ida ọgọta, wọn si tun un yan ni 2021.

Ayọ ni mo fipo silẹ-Keir Starmer

Olootu ijọba Gẹẹsi to kuro nipo, Keir Starmer naa ko ṣai fi ohun silẹ bo ṣe n kuro nipo to si ri Ọba Charles Kẹta

Alaye ti Starmer ṣe ni pe ọpọ nnkan lo ti yipada si daadaa boun ṣe n kuro nipo.

O ni ọrọ aje, iṣẹ ode, lile iṣẹ ati oṣi jinna ti kuro lara ọpọ ọmọde, bẹẹ lo ni orukọ ilẹ Britain ti gbayi daadaa ni saa oun.

Starmer sọ pe ayọ loun fi fipo silẹ, ati pe ohun ti oun yoo maa ranti ju ni anfaani ti oun ni lati ri ayipada rere to ba UK lasiko oun.

Olootu tẹlẹ naa ni oun ri I lara awọn eeyan pe wọn ri iṣẹ oun.

Starmer ni iṣẹ oun ti pari, oun dupẹ fun anfaani lati sin ilẹ UK, ẹrin si pa ẹkẹ oun kuro nipo ni.

Bakan naa lo ki Andy Burnham kaabọ, Stermer ni oun ki I kuu oriire, oun yoo ti I lẹyin, adura oun si ni pe yoo ṣe aṣeyọri.