Àwọn oníjìbìtì orí ayélujára tọwọ́ bọ ojú òpó Ààrẹ Kenya, wọ́n ń bèèrè $320,000

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn to maa n wọnu oju opo eeyan lọna aitọ pẹlu ero lati lu jibiti lori ayelujara ti tọwọ bọ oju opo Aarẹ ilẹ Kenya, William Ruto.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti I sẹni to mọ awọn onijibiti ori ayelujara to ṣiṣẹ naa.

Amọ ṣaa, ko din ni owo Kenya ti iye rẹ jẹ miliọnu mọkanlelogoji (41 million Kenyan shillings) ti wọn n beere ki wọn to le da oju opo naa pada.

Eyi to $320,000 owo dọla.

Wọn ni awọn fẹ gba owo naa ki aago mẹfa irọlẹ ọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun oṣu Keje ọdun 2026 too lu, gẹgẹ bi awọn ẹka iroyin abẹnu Kenya ṣe sọ.

Ki ni wọn ṣe si oju opo naa?

Gẹgẹ bi iroyin ṣe ro o ni Kenya, awọn to tọwọ bọ oju opo Aarẹ Ruto ba oju rẹ jẹ nipa gbigbe awọn iroyin ijọba to wa nibẹ kuro, wọn si kọ awọn ọrọ kobakungbe sibẹ.

Awọn eeyan naa leri sibẹ pe awọn yoo tu awon aṣiri ijọba ti ko gbọdọ fi oju han sode.

Ẹka to n ri si ikansira ẹni lorilẹede naa to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣalaye pe awọn alaṣẹ ibẹ ti fi to awọn ẹka to yẹ leti, wọn si ti n ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹka to yẹ lati wadii, fi oju awọn to tọwọ bo opo Aarẹ naa lede.

Ninu atẹjade ti William Gitau, Akọwe ileeṣẹ ijọba naa fi sita lo ti ni awọn ti gbe òté le oju opo Aarẹ Ruto fun asiko yii na, ki iwadii le rọrun lati ṣe.

Bakan naa lo ni iṣẹ ti n lọ lati ri i pe awọn gba oju opo naa pada.

Ẹka iroyin Kenya.co.ke ṣalaye pe oju opo naa n fi awọm ẹsun ti wọn fi kan Aarẹ Ruto han, ati aaye owo ori ayelujara (cryptocurrency wallet address), bẹẹ ni wọn n beere owo.

Bakan naa ni wọn yi idanimọ oju opo naa pada, amọ orukọ ijọba Kenya ṣi wa nibẹ.

Iṣẹlẹ yii n waye lẹyin iru rẹ to ṣẹlẹ loṣu Kọkanla ọdun 2025, nibi ti awọn onijibiti naa ti da oju sọ ọpọ oju opo ijọba, eyi ti awọn alaṣẹ sọ pe wọn farabalẹ ṣeto rẹ ni.