You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìdí tí ECOWAS ṣe fòǹtẹ̀ lu ríri ọ̀pá gáàsì láti Nàìjíríà lọ Morocco dé Yúróòpù, àti ìpè láti kọjú oro sí South Africa lórí àtakò rẹ̀ sáwọn adúláwọ̀ míì
Ijọba Naijiria ti rọ awọn olori orilẹ ede lekun iwọ oorun Africa lati panupọ bu enu atẹ lu ikọlu to n waye sawọn ọmọ Naijiria atawọn ọmọ ilẹ Africa mii ni orilẹ ede South Africa.
Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu sọ pe ti awọn olori orilẹ ede Africa ba kọ lati dakẹ, ti wọn ko ba gbiyanju pana aawọ, o ṣeeṣe ko mu alekun ba aisi igbọra ẹni ye nilẹ Africa.
Tinubu parọwa yii lasiko to kopa nibi eto apero ikọ ECOWAS ẹlẹkẹrindinlaaadọrin iru rẹ to waye ni Freetown, orilẹ ede Sierra Leone lọjọ Aiku, nibi ti igbakeji aarẹ, Kashim Shettima ti ṣoju Tinubu.
"Ti gbogbo ilẹ Africa ba bu ẹnu ate lu atako, yoo jẹ itaniji fun awọn eeyan South Africa pe ṣiṣe ikọlu sawọn akẹgbẹ wọn kii ṣe ohun ti wọn yoo faye gba ni ẹkun Africa"
Atẹjade ti igbakeji aarẹ fi soju opo ayelujara rẹ lo ti sọrọ nipa ohun to waye nibi apero naa.
Igbesẹ ijọba Naijiria yii lo n waye latari ikọlu to n waye sawọn ọmọ Naijiria atawọn ọmọ ilẹ Africa mii ni South Africa, ti ikọlu naa si ti n mu adinku ba ibaṣepọ to wa laaarin orilẹ ede mejeeji, ti ijọba Naijiria si ti ko awọn eeyan rẹ kuro ni South Africa.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, Tinubu ni ti gbogbo awọn ilẹ Africa ba panupọ lati bu ẹnu ate lu iwa yii yoo jẹ itaniji fun awọn eeyan South Africa pe ṣiṣe ikọlu sawọn akẹgbẹ wọn kii ṣe ohun ti wọn yoo faye gba ni ẹkun Africa.
Ipe ijọba Naijiria lo n kin ọrọ Aarẹ Ghana, John Mahama lẹyin to ti ṣaaju sọ pe gbogbo awọn orilẹ ede lẹkun Africa gbọdọ panupọ nibi apero ẹgbẹ orilẹ ede Africa lati bu enu atẹ lu ikọlu naa.
Aarẹ Naijiria fi kun pe eeyan 1,490 ni ijọba Naijiria ti ko pada sile lati South Africa lati igba ki ikọlu naa ti bẹrẹ, ti wọn si fun awọn eeyan ni gbedeke lati fi orilẹ ede wọn silẹ.
Awọn olori orilẹ ede lẹkun iwọ oorun Africa to fi mọ Benin, Cabo Verde, The Gambia, Ghana, Guinea-Bissau, Cote d'Ivoire, Senegal, Togo, Liberia lo peju sibi apero naa.
Lara awọn ohun ti wọn gbeyẹwo nibi apero naa ni awọn nnkan to n nipa ni ẹkun Africa to fi mọ ọrọ aabo, iṣejọba awaarawa, eto ọrọ aje, ohun amayedẹrun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
ECOWAS ṣatilẹyin fun ṣiṣe ọpa epo laaarin Morocco ati Naijiria
Lara awọn ohun to waye nibi apero ECOWAS naa ni bibuwọlu ṣiṣe ọpa epo laaarin Morocco ati Naijiria eyi ti ajọ naa ṣatileyin fun.
Atẹjade tawọn alaṣẹ orilẹ ede mejeeji fi lede sọ pe ọpa epo naa ni ireti wa pe o maa le gbe gaasi ti iwọn rẹ to biliọnu ọgbọn mita kubiiku lati Naijiria gba orilẹ ede iwọ oorun mẹtala lọ si Morocco.
Atẹjade naa ti ajọ NNPC ati ileeṣẹ to n ri si epo ati iwakusa ni Morocco, ONHYM fi lede ṣalaye pe, afẹfẹ gaasi biliọnu mẹẹdogun mita kubiiku ninu rẹ ni yoo maa lọ si ilẹ Yuroopu eyi to maa ma gba ọpa epo to lọ si Spain lati Morocco to ti wa tẹlẹ.
Lati bii ọdun mẹwaa sẹyin ni Naijiria ati Ọba Morocco ti fẹnuko lori ajọṣepọ yii, ti wọn si gba lati ri ọpa epo naa maa gba ọna to to kilomita 6,900, ti wọn si ni, o maa na awọn lowo to to $25 billion.
Ni oṣu Kẹrin, ONHYM sọ fun Reuters pe ṣiṣe agbekalẹ ọpa epo naa maa mu eto ọrọ aje gbooro si ni iwọ oorun Africa.
Aaarẹ Senegal di alaga tuntun fun ECOWAS
Aarẹ Senegal, Bassirou Diomaye Faye ti di alaga tuntun fun ajọ ECOWAS.
Faye gba ipo alaga naa lọwọ Aarẹ Sierra Leone, Julius Maada Bio, ẹni to ti wa nipo naa lati oṣu Kẹfa ọdun 2025.
Aarẹ Senegal naa lo n gba ipo lasiko ti ẹkun iwọ oorun Africa n koju awọn ipenija aisi aabo, ipenija eto iṣejọba awaarawa, ati aisi ibaṣepọ to danmọran pẹlu awọn orilẹ ede bii Mali, Burkina Faso ati Niger ti wọn ti kuro ni ECOWAS.
Lara awọn afojusun Faye ni lati fa awọn orilẹede ti ologun ti gbajọba ni Afrika bii Burkina Faso, Mali ati Niger pada sinu ajọ Ecowas.
Gẹgẹ bi alaga, lara awọn ohun ti olori orilẹ ede Senegal naa yoo gbajumọ ni mimu ibaṣepọ to danmọran waye laaarin awọn orilẹ ede to wa lẹkun iwọ oorun Africa.
Ta ni Bassirou Faye?
Ẹni ọdun mẹrinlelogoji ni Bassirou Diomaye Faye nigba to di aarẹ Senegal lọdun 2024 eyi to mu ko jẹ Aarẹ ti ọjọ ori rẹ kere julọ ninu itan orilẹ ede naa.
Faye wa lara awọn oloṣelu inu ẹgbẹ alatako ti wọn tu silẹ lọgba ẹwọn lọjọ mẹwaa ṣaaju eto idibo naa.
Inu ọgba ẹwọn ni wọn ti ṣe ipolongo ibo fun Faye ko to jade lọgba ẹwọn.
Ọkunrin naa, to jẹ oṣiṣẹ owo ori tẹlẹ ni Aarẹ karun un ti Senegal yoo ni lati igba to ti gba ominira lọwọ orilẹede France lọdun 1960.
Faye tun ni Aarẹ akọkọ ti yoo sọ ni gbangba pe oun kii ṣe oniyawo kan.