You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ nípa ìtàn ife ẹ̀yẹ àgbáyé àti òdiwọ̀n góòlù tí wọ́n fi ṣe ife ẹyẹ ọdún 2026
Okuta olowo iyebiye ni Wura ti a tun mọ si goolu jẹ, oun ni wọn fi ṣe Ife Ẹyẹ Agbaye ọdun 2026 yii .
Oniṣẹ ọna ọmọ ilẹ Italy, Silvio Gazzaniga lo rọ ọ́.
Bo ṣe jẹ olowo iyebiye to, ikọ agbabọọlu Spain to jawe olubori nibi idije naa to si gba a ko ni i gbe e sọdọ, wọn yoo da a pada lẹsẹkẹsẹ ni.
Odinwọn goolu Ife Ẹyẹ Agbaye naa:
Ni ti iye ti goolu Ife Ẹyẹ Agbaye naa to, akọsilẹ fi han pe o to $713,000 (£532,000).
Iwọn rẹ jẹ 6.175kg, gẹgẹ bi akọsilẹ ti London Stock Exchange Group (LSEG) ṣe.
Afarajọ goolu ni ikọ to gba Ife Ẹyẹ Agbaye naa gbe lọ, ojulowo goolu naa n pada si ibudo itọju nnkan pataki (Museum) to wa ni Zurich, Switzerland ni.
Atupalẹ rẹ
Ipele goolu ti a mọ si 18-karat ni ajọ FIFA fi ṣe Ife Ẹyẹ Agbaye yii, eyi to tumọ si pe ida marundinlọgọrin ara rẹ (75%) lo jẹ goolu.
Giga rẹ jẹ 36.8 centimeters
Iwọn rẹ jẹ: 6.175 kilograms
Isalẹ rẹ kun fun awọn okuta alawọ ewe ti a mọ si malachite, eyi to bu kun ẹwa rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ife naa gbajumọ nitori pe o jẹ goolu, iyi rẹ pọ lọkan awọn ololufẹ bọọlu afẹsẹgba ju ti wura to jẹ lọ.
Eyi ri bẹẹ nitori aṣeyọri ati apọnle to jẹ fun ikọ to ba gba a kaakiri agbaye.
Itan Ife Ẹyẹ Agbaye
Ọdun 1930 ni ajọ FIFA ṣe ifilọlẹ Ife Ẹyẹ Agbaye akọkọ, labẹ idari Jules Rimet, ẹni ti wọn fi ife eyẹ naa sọri.
Rimet ni aarẹ FIFA to pẹ ju nipo ninu itan, o wa nipo naa fun ọdun mẹtalelọgbọn, iyẹn laaarin ọdun 1921 si 1954.
Oniṣẹ ọna ọmọ ilẹ Faranse kan, Abel Lafleur, lo ṣe ife ẹyẹ naa.
Iṣẹ rẹ ṣafihan Nike, ooṣa Iṣẹmbaye aṣeyọri Greek to gbe ife dani.
Omi Fadaka lo fi ṣe ife naa, o si fi omi wura sita rẹ, ori okuta iyebiye lapis lazuli lo si gbe e le.
Lasiko ogun Agbaye Keji, ajọ FIFA kede pe oṣiṣẹ ọmọ ilẹ Italy kan, Ottorino Barassi, tọju ife ẹyẹ naa sinu paali to n ko bata rẹ si niluu Rome.
Won ni o ṣe bẹẹ kawọn ṣọja Nazi ma baa gbe e lọ.
Bi wọn ṣe bẹrẹ si i lo tasiko yii
Itan Ife Ẹyẹ Agbaye ti wọn n lo lọwọ yii bẹrẹ ni ọdun 1974, lẹyin ti orilẹede Brazil gba eyi ti wọn pe ni Jules Rimet Trophy ti wọn si gbe e sọdọ.
Ni 1970, Brazil gba ife ẹyẹ naa fun igba kẹta ni Mexico.
Gẹgẹ bi ofin igba naa, orilẹede to ba gba ife naa fun igba mẹta yoo gbe e sọdọ gbere lai da a pada mọ.
Eyi mu ajọ FIFA maa wa ife ẹyẹ mi-in ni 1974 ti idije naa tun fẹ waye ni Iwọ-Oorun Germany.
Iṣẹ ọna mẹtalelaadọta (53 artworks) ni awọn oniṣẹ ọna fi ranṣẹ kaakiri agbaye pe ki wọn mu ninu rẹ .
Lara rẹ ni FIFA si ti yan ti gbajumọ oniṣe ọna, Silvio Gazzaniga.
Wọn ti ji Ife Ẹyẹ Agbaye lọ lẹẹmeji ri
Nigba to ku oṣu diẹ ki Ife Ẹyẹ Agbaye ọdun 1966 bẹrẹ ni England, wọn ji ife naa lọ lasiko ti wọn ṣafihan rẹ nita gbangba.
Lẹyin ti wọn wa a doju ami, aja kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Pickles, lo ri i ninu iwe iroyin ti wọn we e mọ labẹ ogiri ile kan ni Guusu London.
Iṣẹlẹ naa si di ọkan lara itan ti ko ṣee gbagbe ninu itan Ife Ẹyẹ Agbaye.
Ni 1983, wọn tun ji ife ẹyẹ Jules Rimet lọ lẹẹkan si i.
Akata olu ile ẹgbẹ agbabọọlu Brazil ni wọn ti gbe e lọ ni Rio de Janeiro.
Wọn ko ri ife ẹyẹ naa mọ titi di oni.
Ohun tawọn eeyan gbagbọ ni pe wọn yọ́ ọ to si di bii omi ni, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to fidi eyi mulẹ.
Awọn orilẹede to ti gba ife ẹyẹ agbaye ri
Lati ibẹrẹ rẹ ni 1930, de eyi ti wọn gba gbẹyin ni Qatar ni 2022, orilẹede mẹjọ lo ti gba ife ẹyẹ agbaye yii ri.
Brazil ti gba a nigba marun-un, Germany gba a lẹẹmẹrin. Awọn yoku ni:
Italy:
Argentina
France
Uruguay
England ati Spain.