Ajínigbé yọ̀ǹda òkú ìyá, dẹ́rẹ́bà àti ọ̀kan lára ọmọ ìyá mẹ́ta tí wọ́n jí gbé, bèèrè N30m

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn ajinigbe to ji ọmọ iya kan naa mẹta to fẹ lọ sinku iya wọn gbe ni Benue lọjọ Abamẹta ti yọnda oku iya naa, dẹrẹba to wa ọkọ ati ọ̀kan lara awọn ọmọ iya mẹta naa.

Amọ itusilẹ naa ko ba ọfẹ de, awọn ajinigbe naa n beere ọgbọn miliọnu naira (30m) ki wọn to le fi awọn ọmọ iya meji to ṣẹku nigbekun silẹ.

Ẹ o ranti pe ṣaaju ni a ti fi to yin leti, pe awọn ajinigbe naa gbe awọn eeyan wọnyi lọ lasiko ti wọn n rin irinajo lati Abuja si Oklenyi, nijọba ibilẹ Okpokwu, ipinlẹ Benue lati sin oku iya wọn.

Ọkọ̀ ti wọn n gbe lọ lo bajẹ loju ọna Otukpo–Ogobia, nibi ti wọn ti n wa atunṣe si i ni awọn ajinigbe ti ba wọn, ti wọn gbe wọn lọ.

Bi wọn ṣe yọnda oku, dẹrẹba ati ọmọ oku kan

Gẹgẹ bi awọn ẹbi ti ọrọ naa kan ṣe ṣalaye fun ẹka iroyin Idoma Voice, wọn ni awọn ajinigbe naa pada fi dẹrẹba to wa ọkọ naa silẹ pẹlu ọmọ oku kan, wọn si gbe oku iya ti wọn ti kọkọ gbe lọ naa pada fun wọn.

Amọ meji ninu awọn ọmọ oku naa ni awọn ajinigbe kọ lati yọnda, afi bi wọn ba san ọgbọn miliọnu naira.

Gẹgẹ bi awọn ẹbi ṣe wi, awọn ajinigbe naa ti n ba awọn sọrọ lorii foonu.

Wọn ni wọn si n leri pe bawọn ko ba sanwo naa, ko si itusilẹ fawọn meji to wa nigbekun rara.

Iṣẹlẹ yii ti da mọlẹbi naa si idaamu, pẹlu bi wọn ko ṣe le fi ifọkanbalẹ ṣeto isinku iya ti ajinigbe yọnda ọhun, nigba ti awon ọmọ rẹ meji ṣi wa ninu ahamọ, ti wọn ko si ti i rowo gba wọn kalẹ.

Agbébọn jí ọmọ ìyá kan náà mẹ́ta tó ń lọ sìnkú ìyá wọn gbé ní Benue

Ijinigbe tun gba ọna mi-in yọ lọjọ Abamẹta, ọjọ kejindinlogun oṣu Keje ọdun 2026 yii, nigba ti awon ajinigbe ji ọmọ iya kan naa mẹta to n lọ sinku iya wọn gbe nipinlẹ Benue.

Gẹgẹ bi a sẹ gbọ, awọn ajinigbe naa da ọkọ awọn ọmọ iya mẹta naa duro loju ọna Ogobia–Otukpo Road, nijọba ibilẹ Ohimini.

Laaarin ibi kan ti wọn n pe ni Omutele ati Ankpechi ni iroyin sọ pe ijinigbe yii ti waye, ni nnkan bii aago mẹrin idaji.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Awọn eeyan ninu fidio kan to n lọ lori ayelujara nipa iṣẹlẹ naa ṣalaye, pe ọkọ tawọn ọmọ oloku naa fi n rin irin ajo lo yọnu lojiji si oju ọna marosẹ.

Eyi ni wọn ni wọn n wa atunṣe si lọwọ ti awọn kan fi kọlu wọn ti wọn si gbe wọn lọ.

Boya wọn gbe oku naa mọ wọn ni fidio naa ko fidi ẹ mulẹ.

Bakan naa ni olugbe agbegbe naa kan to pe ara rẹ ni Elijah, ṣalaye fun ikọ iroyin Punch pe iro ibọn lo ji awọn eeyan lati aago mẹta oru si mẹrin ọjọ Satide naa.

O ni awọn tiẹ kọkọ ro pe awọn darandaran lo n kọlu adugbo ni, afi nigba ti ilẹ mọ tawọn gbọ pe ajinigbe lo gbe ọmọ iya mẹta to n lọ sinku iya wọn lọ.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni awọn ajinigbe dena de ọkọ to n gbe oku oṣiṣẹ FRSC kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Augustine Ikwue, loju ọna Ochadamu-Ejule, ipinlẹ Kogi.

Eeyan mẹsan-an ni wọn ji gbe lọ ninu awọn to n gbe oku naa lọ sibi ti wọn yoo ti sin in.

Bakan naa ni wọn si figba kan gbe oku paapaa lọ ki wọn too ju u sibi kan ti awọn ẹbi ti pada lọ gbe e ti wọn si sin i.

Iṣẹlẹ yii ti mu ki ọpọ eeyan maa sọ pe eto aabo ko fẹsẹmulẹ ni Benue, Kogi atawọn ilu to sun mọ wọn.

Lasiko ti a pari iroyin yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue ko ti i sọrọ lori iṣẹlẹ naa.