You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ọkọ̀ bọ́ọ̀sì tó ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ ogún
Awọn alakoso orileede Uganda sọ pe yatọ si awọn akẹkọọ ogun ti wọn ba ijamba naa lọ, agbalagba kan ku, bẹẹ ni awọn miran tun farapa yannayanna ni agbegbe Kapchorwa.
Ìjọba fojú mẹ́ta lára àwọn afurasí agbésùnmọ̀mí tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé l'Ogbomoso hàn nílé ẹjọ́
Awọn afurasi mẹta ọhun, Abdulrazak Umar, Yunusa Musa ati Shamsu Adamu Sani ni ijọba ti fẹsun onikoko mẹwaa to da lori igbesunmọmi, ijinigbe, fifi ọrọ pamọ ati wiwa kusa lọna aitọ.
Ohun tí a mọ̀ nípa rògbòdìyàn tó wáyé l'Osogbo níbi tí èèyàn méjì ti kú, tí ọ̀pọ̀ tún farapa
Iroyin ni asiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ọhun n ṣe ipade lọwọ ni awọn afurasi naa ya bo agbegbe naa ninu bọọsi Toyota Hiace kan ti gbogbo wọn si wọ aṣọ dudu.
Aisha Achimugu, bọ̀rọ̀kìnní obìnrin tí iléẹjọ́ gbẹ́sẹ̀lé ẹ̀ṣọ́ ara àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí owó rẹ̀ tó ₦8.9bn lẹ́yìn tí EFCC fí ẹ̀sùn kíkọ́rọ̀ jọ lọ́nà èrú kàn án
Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ Naijiria, EFCC wọn fidi iroyin naa mulẹ f'awọn akọroyin lẹyin ti idajọ naa waye lori ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan an.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,00
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Gbogbo ìgbà ti ọmọ mi bá rí àlejò ni ẹ̀rù máa ń bà á báyìí – Ìyá akẹ́kọ̀ọ́ tó gba ìtúsílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo
Gẹgẹ bii obinrin naa ṣe sọ, niṣe ni ọmọ ọhun maa n bẹru to si maa n sa to ba ri alejo ti ko mọ ri.
Wo bí 'Muhammad' ṣe di orúkọ tí wọ́n ń sọ ọmọkùnrin jùlọ ní England àti Wales
Abọ iwadii ti ajọ to n ri si onka ni UK iyẹn UK Statistics Office lo fidi eyi mulẹ ninu iwadii kan ti won ṣe nipa orukọ tawọn obi fun ọmọ wọn julọ lọdun to kọja.
Fídíò, Ìpinnu mi láti di gómìnà ìpínlẹ̀ Osun jẹ́ kádàrá èmi àti Ọlọ́run – Bola Oyebamiji olùdíje APC, Duration 6,21
Bọla Oyebamiji ṣalaye pe ṣalaye pe iṣẹ agbẹ loun yoo mojuto bi oun ba de ori oye
Ìjọba, ẹ bá wa ṣètò láti gbé òkú ọkọ mi wálé ká lè sin ín, ẹ sì ràn mí lọ́wọ́ lórí ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ - Ìyàwó John Olaleye
Gẹgẹ bii ohun ti arabinrin Rachael Alamu sọ, ọjọ Aiku, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii ni wọn pa Ọgbeni John Olaleye si igbekun.
Ilé aṣòfin Amẹrika buwọ́lù àbá láti dá ìrànwọ́ Amẹrika fún Naijiria dúró títí tíjọba yóò fi wá ojútùú sí ìṣekúpani àwọn Kristẹni
Aṣofin Gregory Stuebe to n ṣoju ẹkun Florida lo da aba naa l'Ọjọru ki gbogbo ile to gba a wọle.
Òjò yóò rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́wàá gbáko – Àyẹ̀wò ojú ọjọ́
Omiyale tete maa n waye nipinlẹ Eko latari bo ṣe sunmọ eti omi, paapaa alagbalugbu omi okun Atlantic Ocean.
Wo àwọn orílẹ́-èdè ilẹ̀ Afirika táwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹrika kò gbọdọ̀ lọ
Amẹrika sọ pe ipele kẹrin ni awọn orileede mẹtalelogun ọhun wa ninu awọn orileede ti Amẹrika sọ pe awọn araalu ko gbọdọ lọ, fun idi eyi, wọn ni ko si idi pataki ti kan ti awọn eeyan fi gbọdọ lọ sibẹ.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
''Ohun tó kàn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Oríire tó bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé rèé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ọ́...''
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Arabinrin Abiola sọ pe ''awọn obi awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ gbominira lọwọ ajinigbe ni iṣẹ to pọ lati ṣe nitori iriri ti wọn ni ninu igbo ti ṣakoba fun ilera ọpọlọ wọn.
Wo orúkọ gbogbo àwọn ọmọ ogun àti ọlọ́pàá tó kú sínú ìgbìyànjú láti dóòlà àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ Oriire
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, awọn ẹṣọ aabo mẹwaa ọtọọtọ lo kopa ninu igbiyanju lati tu awọn eeyan naa silẹ eyi ti Ọgagun Chinedu Ralph Nnebeife ti ọga ileeṣẹ ologun Commanding 2 Division tẹka ileeṣẹ ologun.
Èyí lohun tí MC Oluomo, Sego sọ̀rọ̀ lórí ikú tó pa Toba Ijaya, akọ̀wé NURTW ní ìpínlẹ̀ Eko
A gbọ pe awọn agbebọn naa kọlu Ajiboye ti ọpọ mọ si 'Tọba Ijaya' loju ọna marosẹ Ikorodu nibi ti wọn ti ṣina ibọn fun ọkọ rẹ.
Ìjọba àpapọ̀ wọ́gilé àfikún owó ìdánwò WAEC àti NECO tó ṣe láti ₦27,500 sí ₦50,000
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ekọ ni Naijiria fi lede, ijọba ni oun gbe igbesẹ yii lọna ati kọkọ jiroro pẹlu awọn ti ọrọ kan lori igbesẹ ọhun.
Ilé aṣòfin àgbà ní kí ìjọba yé dáríji àwọn agbéṣùmọ̀mí Boko Haram tó bá juwọ́ sílẹ̀ mọ́
Ile aṣofin agba fẹnuko lori igbesẹ yii nibi ijiroro to waye nile aṣofin lọjọ Iṣẹgun lori aba ti aṣofin Abdulaziz Yar'Adua fi siwaju ile lori awọn ikọlu to n waye lemọlemọ kaakiri Naijiria to fi mọ ijinigbe ati ipaniyan.
Wo orílẹ́èdè 62 táwọn èèyàn ibẹ̀ kò nílò fisà láti wọ orílẹ́èdè Germany
Gẹgẹ bii atẹjade ti ẹka ijọba orilẹede Germany to n ri si ọrọ ilẹ okeere fi sori itakun agbọrọkaye wọn, awọn eeyan lati orilẹede mejilelọgọta yii lanfaani lati ṣabẹwo si Germany fun aadọrun un ọjọ fun irinajo igbafẹ, ipade okoowo ati igbadun ẹbi.
Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa John Olaleye, olùkọ́ Oriire kẹta tí àwọn agbésùnmọ̀mí pa ní àhámọ́?
Inu ọpọlọpọ araalu lo dun lẹyin ti awọn eeyan naa pada wale amọ ọgbẹni John Olaleye ko si ninu wọn.
Àwọn agbófinró nawọ́ gán Adeyemi, Ọ̀gá àgbà ayédèrú àjọ PFIPC lẹ́yìn tó kọ̀ láti yọjú sílé ẹjọ́
Ẹsun onikoko mẹjọ to da lori iwe yiyi, jibiti ati pipe ara rẹ ni nnkan ti ko jẹ ni wọn fi kan Adeyemi Adeniyi.
''Makinde ní láti tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé, àjọ UNO tó ń ké pè kò lè sèwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà''
Sẹnẹtọ Jimoh Ibrahim sọrọ yii lẹyin ti Makinde ti ke pe ajọ UNO lati ṣewadii ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ijinigbe ọhun to waye nile ẹkọ girama Esinele ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ Yawota nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso.
Ọlọ́pàá mú afurasí ajọ́mọgbé méjì n'Ibadan, dóòlà ọmọ ọdùn márùn-un tí wọ́n jí gbé
Lẹyin ti wọn ji ọmọ naa gbe ni wọn beere fun miliọnu mẹwaa naira owo itusilẹ gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe wi, wọn si ti gba miliọnu kan ninu owo naa ki ọwọ palaba wọn too pada segi.
Wo bí epo tí Dangote fẹ́ máa tà ní dọ́là dípò náírà yóò ṣe kàn ọ́
Alaye ti ileeṣẹ Dangote ṣe ni pe ayipada yii ṣe pataki nitori ohun ti okoowo n fẹ, ati nitori iyatọ to wa ninu owo naira ati tilẹ okeere lọja agbaye.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Alága àdúgbò dá baálé ilé dọ́bálẹ̀, fi pankẹ́rẹ́ dá sẹ̀ríà ìyà fún un torí pé ó sọ̀rọ̀ lórí àṣepatì àkànṣeiṣẹ́ àjọ NDDC, ọlọ́pàá ní iléẹjọ́ yá
Atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta fi sita lo fidi ẹ mulẹ, pe awọn eeyan naa huwa to lodi sofin, igbejọ si ti bẹrẹ lori ọrọ wọn.
Ọdún méjìdínlógún ni mo fi wojú Ọlọ́run fọ́mọ kí n tó bí ìbejì - Ricardo Agbor
Ninu ifọrọwerọ kan ti agba oṣere naa ṣe pẹlu AfricanAList lo ti ṣalaye irinajo rẹ ninu sinima ṣiṣe ati igbeaye rẹ lai si ninu sinima.
Ìjọba Nàíjíríà ṣe àfikún lórí owó oṣù àwọn ọmọ ogun láti 49,000 sí 100,000 náírà
Ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira ni ijọba gbe owo oṣu naa si bayii, lati ẹgbẹrun mọkandinlaadọta naira ti wọn n gba tẹlẹ gẹgẹ bi owo oṣu.
"Àkọ̀bí mi tó ń tọ́jú èmi àtàwọn àbúrò rẹ̀ ní wọ́n pa nínú ìjà Hausa àti Yorùbá n'Ibadan"
Ounjẹ alẹ ti Habeeb fẹ jẹ la gbọ pe o lọ ra to fi lugbadi iku ojiji ninu ija Yoruba ati Hausa naa
Iléẹṣẹ́ ológun Nàìjíríà ṣàlàyé iṣẹ́ oṣù kan tí wọ́n fi gba akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ Oríire lọ́wọ́ ajínigbé
Ọgagun Danjuma Jonah Danjuma, ti ẹka ikede nileeṣẹ ologun ẹkun keji (2 Division) lo fi atẹjade to ṣalaye ọna tawọn to wa nigbekun naa gba ri itusilẹ lọjọ kẹwaa, oṣu Keje ọdun 2026.
Èyí ni àpéjọpọ̀ ẹ̀sìn márùn-ún táwọn èèyàn ti máa ń pọ̀jù lágbàáyé
Lọwọlọwọ yii, apejọpọ marun-un lo jẹ koko ti wọn si gbajumọ ju lagbaaye, eyi to jẹ ti ẹsin.
Wo orúkọ àwọn ọmọ Naijiria 124 tí Amẹrika kéde pé àwọn yóò lé kúrò lórílẹèdè náà
Ọrọ yii lo wa ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ijọba Amẹrika to n ri si ọrọ abẹnu fi lede lori itakun ayelujare wọn.
'Mi ò ní ìgboyà rẹ̀': Alicia Lissu sọ̀rọ̀ lórí ipa tí ètò òṣèlú Tanzania ní lórí ìdílé rẹ̀
Alicia Lissu, iyawo olori ẹgbẹ oṣelu alako ni Tanzania sọrọ nipa awọn nnkan to n koju lati igba ti ọkọ rẹ ti n koju igbẹjọ diditẹ mọ ijọba .
Mo lè má sí láyé láti kópa nínú ètò ìdìbò ọdún 2027 – Obi
Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra sọ pe ọpọ awọn ẹtọ oun ni ijọba ilẹ Naijiria fi n dunkooko mọ oun, ati pe gbogbo awọn to duro gẹgẹ bi alatako ijọba ni wọn n dojukọ idunkooko loriṣiriṣi.