You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Afurasí tíṣà tí wọ́n ló lu akẹ́kọ̀ọ́ pa jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ọlọ̀pàá
Lẹyin iroyin kan to gbode pe obinrin tiṣa kan lu akẹkọọ ọmọ ọdun mejila pa nipinlẹ Anambra, ati pe tiṣa naa sa lọ lẹyin iṣẹlẹ yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti kede pe tiṣa ọhun ti wa fa ara rẹ le awọn lọwọ.
Iṣẹlẹ naa waye niluu Adazi-Ani, nijọba ibilẹ Anaocha, ipinlẹ Anambra.
Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Tochukwu Ikenga, ṣe kede ninu atẹjade to kọkọ fi sita, Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa waye.
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Lọjọ Ẹti, ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Keje ọdun 2026 yii ni Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Tochukwu Ikenga, fi atẹjade kan sita.
Ninu atẹjade naa lo ti ṣalaye pe awọn gba ipe nirọlẹ Ọjọbọ, pe tiṣa kan lu akẹkọọ pa.
Ọmọkunrin to ni olukọ lu pa naa lo pe orukọ rẹ ni Chinedu Emmanuel.
Gẹgẹ bo ṣe wi, tiṣa naa fẹsẹ fẹ ẹ nigba to gbọ pe akẹkọọ yii ti ku nileewosan ti wọn gbe e lọ.
Eyi to mu ki ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn ti n wa tiṣa naa kawọn si mu un.
Ṣaaju ni iroyin iṣẹlẹ naa ti jade pe olukọ obinrin ọhun lu Chinedu pupọ, ati pe àpá ẹgba han lara rẹ ketekete.
Iroyin sọ pe ijiya naa pọ to bẹẹ gẹẹ to jẹ pe wọn sare gbe e lọ sile iwosan fun itọju, amọ awọn dokita sọ pe ọmọkunrin naa ti jade laye.
Eyi di ariwo kaakiri agbegbe Adazi-Ani, awọn eeyan si n beere idajọ ododo bi wọn ṣe n wa olukọ naa.
Lẹyin iku Chinedu ni olukọ na papa bora, eyi to mu awọn ọlọpaa Anambra maa wa a kiri nipasẹ ikọ kan ti wọn pe ni "Safe School Protection Squad" ati awọn ọlọpaa lati agọ Neni.
Lẹyin eyi ni Ikenga fi atẹjade to n kede pe tiṣa naa ti funra rẹ wa ba ọlọpaa lede, pẹlu alaye pe o ti wa ni akata awon bayii.
O fi kun un pe awon yoo taari rẹ si ẹka to n tọpinpin iwa ọdaran, eyi to wa ni Awka, fun itẹsiwaju iwadii.
Alukoro ọlọpaa naa wa fi da awọn ẹbi Chinedu Emmanuel loju, pe idajọ ododo yoo waye lori ọro yii.
O rọ araalu lati ma ṣe maa funra wọn da sẹria fun afurasi, bi ko ṣe pe ki wọn maa ran agbofinro lọwọ lati mu wọn nipa ifisun ati olobo tita.