You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn nǹkan tí o kò kà kún tó lè dí ojú òpó Wi-Fi rẹ lọ́wọ́ àti ọ̀nà àbáyọ
Bi eeyan ba gbe foonu igbalode dani, tabi bi eeyan ba n lo ẹrọ kọmputa alagbeletan tabi iyowu ko jẹ, ti ko wa si Wi-Fi to n mu ayelujara ṣiṣẹ lori ẹrọ naa, bi ẹni gbe gbunduku ẹrọ dani ni.
Idi ni pe oju opo Wi-Fi yii ni ohun to n so eeyan pọ mọ itakun agbaye, to n mu ayelujara si gbogbo ibi ti eeyan ba ran an lọ.
Bi oju opo yii ṣe ṣe pataki to, to ba ti duro ni ikansiraẹni lodikeji duro. O le jẹ bi owo ba tan lorii rẹ tabi bi awọn nnkan kan ba di iṣẹ rẹ lọwọ.
Wayi, yatọ si ọrọ owo atawọn idiwọ to le mu Wi-Fi ma ṣiṣẹ, wọnyi ni awọn nnkan mi-in ninu ile tabi ni ọfiisi rẹ ti o ko fọkan si tabi ka kun, ti wọn le maa ṣakoba fun oju opo ikansira ẹni lori ayelujara rẹ.
Ọkunrin kan, Alex Hills, jẹ ọkan lara awọn to kọkọ ṣiṣẹ lori awọn nnkan wọnyi.
Ni 1993, nigba to n kọ wọn lẹkọọ ni Carnegie Mellon University (USA), o lewaju ikọ kan to ṣiṣẹ lorii Wi-Fi.
Iwe rẹ to pe ni "Wi-Fi and the Bad Boys of Radio" ṣalaye awọn nnkan to le fa idiwọ fun Wi-Fi.
Nnkan akọkọ ni:
Microwave
Fun ọdun mẹtadinlogun, awọn awọrawọ oju ọrun lorilẹede Australia koju ohun ti ko ye wọn lati lo ayelujara.
Awọn kan sọ pe agbara itansan oorun lo n di awọn lọwọ, awọn mi-in si ro pe awọn idiwọ aye ni.
Nigbẹyin ni wọn ri I pe ohun to n fa idiwọ naa ko rin jinna rara, ẹrọ ti wọn fi n wo ohun to ba jinna rere lo n mu awọn isemọ kan wa lati ara ẹrọ Microwave ti wọn fi n mu ounjẹ gbona lọwọ ọsan.
Telescope yii nikan kọ ni Microcawave n yọ lẹnu, bẹẹ naa lo le dena aṣepe iṣẹ Wi-Fi.
Gẹgẹ bi Hills ṣe ṣalaye, bi eeyan ba ṣi ilẹkun microwave ko too gbona ohun ti ẹ gbe sinu rẹ tan, o ni o le dena ijagara Wi-Fi.
Aquariums
Eyi ni apoti alaranbara ti wọn maa n ko ẹja to ṣi wa laaye si, o maa n rẹwa pupọ.
Bi o ba wa ni ẹja tabi ẹranko to n gbe inu omi ninu ile, o le fa idiwọ fun Wi-Fi rẹ.
Wi-Fi ati omi ki i ṣe ọrẹ ara wọn. Omi le di nnkan ti yoo di oju opo ikansiraẹni lọwọ.
Bi o ba gbe aquarium sibi ti Wi-Fi rẹ wa, o le ko ba a bi Hills ṣe sọ.
O ni eeyan le lo ohun ti a mọ si Wi-Fi repeater lati ṣe atunṣe, eyi ko ni I daamu ẹjẹ to wa ninu aquarium naa.
Jígí
Bi ohun to n fi aworan han bii jigi tabi ojiji ba wa nibi kan, o le di iṣẹ Wi-Fi lọwọ.
Bakan naa ni awọn nnkan bii tẹlifiṣan le fa a idiwọ pẹlu.
Bakan naa ni eeyan le koju iṣoro intanẹẹti bi awọn ogiri ile rẹ ba ni Irin ninu.
Bi o ba n koju iṣoro ai ja gaara Wi-Fi, wo awọn nnkan wọnyi boya wọn wa nitosi rẹ, gbe wọn kuro ni apa ibi ti o wa fun oju opo to ja gaara.
Asiko otutu (Winter)
Ko yẹ ki ojo di oju opo Wi-Fi rẹ lọwọ, afi to ba jẹ inu ile miran to yatọ sibi ti o ti n lo o ni o gbe e si.
Amọ bi oju ọjọ ko ba ṣe daadaa lapapọ, o ṣee ṣe ki oju opo ayelujara ma ja gaara.
Yìnyín to n jabọ lakọlakọ le ṣe akoba fun oju opo gbogbo odidi ilu, otutu to lagbara le fa eyi, intanẹẹti si le dipa bi yinyin ba ti di ọna to yẹ ko tọ de ọdọ awọn to nilo re.
Ooru naa le fa iṣoro kan naa.
Igba mi-in si wa to le ma kan oju ọjọ rara, ohun ti a mọ si network le ma yara bii ti tẹlẹ, nigba ti ero ba pọ to n lo o lasiko kan naa.
Bi apẹẹrẹ, bi gbogbo ẹbi kan ba wa nile lasiko kan naa, ti wọn n wo YouTube lasiko kan naa, o ṣee ṣe ki oju opo naa maa fa bii igbin, ko ma ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.
Ọna abayọ
Iwọ funra rẹ ni lati sa ipa rẹ lati da aabo bo bi oju ọjọ ṣe n ri, afọwọfa ọpọ eeyan lo n mu ayipada to lewu ba oju ọjọ, to si n fa idiwọ ati aisi alaafia to peye kari aye.
Yatọ si eyi, o le ba awọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ sọrọ lati gbe igbesẹ aabo ṣaaju ọjọ ewu.
Ni ti Alex Hills, ilu Alaska lo n gbe bayii, nibi to ti n ran awọn abule to ta kete lọwọ lati ni intanẹẹti, kawọn naa le maa mọ bo ṣe n lọ lori ayelujara.