Iyabo Obasanjo àti olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ APC l‘Ogun, Yayi, ń tutọ́ síra wọn lójú

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Sẹnetọ Solomon Adeola ti ọpọ eeyan mọ si Yayi ti fun Sẹnetọ Iyabo Obasanjo lesi lori awọn ẹsun to fi kan-an.

Yayi lo n fun Iyabo Obasanjo lesi lẹyin ti Obasanjo fẹsun kan pe Yayi ko ṣe awọn nnkan to ṣeleri rẹ fun oun leyin ti oun gba pe ki wọn panupọ fẹnuko lati yan-an bi oludije sipo gomina lẹgbẹ APC.

Ṣaaju ni Iyabo Obasanjo ti fi erongba rẹ han lati dije sipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ṣugbọn ti ẹgbe naa pada pawọpọ lati kede Yayi gẹgẹ bi eni to maa dije dupo gomina labẹ ẹgbẹ naa.

Bi o tilẹ je pe Iyabo Obasanjo nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ leyin ikede naa sọ pe oun ko ni fi ẹgbẹ oṣelu APC ati pe oun maa ṣatilẹyin fun Yayi ti ẹgbe ti fa silẹ amọ ninu oṣu Karun-un ni o kede pe oun kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Lara ohun ti Obasanjo ni o mu oun fi ẹgbe oṣelu APC silẹ ni aisi ibọwọ fun oun atawọn ẹsun mii.

Obasanjo, nigba to n sọrọ lori idi to fi kuro ninu ẹgbe oṣelu APC lọ si ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nibi to ti n dije sipo sẹnetọ aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, sọ pe Yayi ṣeleri nnkan mẹta fawọn alatileyin oun lasiko ti awọn ṣapade lẹyin wọn ti kede rẹ gẹgẹ bi oludije APC amọ to ni Yayi ko mu ileri rẹ kankan ṣẹ.

Yayi kọ lati mu ileri rẹ ṣẹ, o bẹrẹ si ni fi owo lọ mi lẹyin ti mo kuro ninu ẹgbẹ APC - Iyabo Obasanjo

O ni nnkan mẹta ti oun beere fun lọwọ Yayi ni ki wọn fun oun ni tikẹẹti lati dije spo sẹnetọ ile aṣofin, ikeji ni pe ki wọn da owo ti oun na lasiko ti oun polongo lati dije sipo gomina pada fun oun, ti ikẹta si jẹ pe ki Yayi fun awọn alatilẹyin oun kọọkan nipo oṣelu.

Obasanjo ni oun ko ni ki Yayi ṣe gbogbo nnkan mẹtẹẹta ti oun n beere naa ṣugbọn ko sọ eyi to ba le ṣe fun oun ninu wọn amọ dipo bẹẹ Yayi ko bao un sọ ohunkohun mọ ayafi igba ti o n pe oun lẹyin ti kuro ninu ẹgbe oṣelu APC.

O fẹsun kan pe lẹyin ti oun ko gbe foonu Yayi nigba ti oun kuro ninu ẹgbẹ lo wa n fi owo lọ oun pe ki oun ma kuro ninu APC.

Iyabo Obasanjo tun bu ẹnu atẹ lu bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe yan Yayi gẹgẹ bi oludije wọn, to si ni ko ba ilana ẹgbẹ naa mu rara.

O fi kun pe bi o tilẹ jẹ pe oun gba lati ṣatilẹyin fun ẹnikẹni ti ẹgbẹ ba fa kalẹ, wọn ko bao un sọ ohunkohun tabi jẹ ki oun gbọ nnkankan ki wọn to kede Yayi bi ẹni ti ẹgbe fa kalẹ.

Bibeere owo ti o fi ṣe ipolongo pada lọwọ jẹ abuku fun mi - Yayi fesi pada fun Obasanjo

Amọ nigba to n fesi, agbẹnusọ Sẹnetọ Yayi, Kayode Odunaro sọ fun BBC News Yoruba pe Yayi ri awọn ibeere Iyabo Obasanjo bi awọn nnkan to tabuku rẹ nitori oun ko gbọ ri nibi ti eeyan kan ti n beere fun owo to na fun ipolongo ibo pada lọwọ oludije mii.

Yayi ni o fi han gbangba bayii pe Iyabo Obasanjo ko ni nnkankan to fẹ ṣe fun awọn araalu bikoṣe pe o fẹ kowo wọn je to ba ni anfaani lati de ipo gomina ipinlẹ naa.

Odunaro ṣalaye pe Yayi sọ ọrọ yii nigba to n ba awọn Iyalaje ati Babalaje ti ilẹ Remo ti wọn ṣabẹwo si ni ọfiisi rẹ to wa ni ilu Ilaro, ijọba ibilẹ Yewa South sọrọ.

O ni awọn ọrọ ti Iyabo Obasanjo sọ fi han pe erongba rẹ lati dije dupo gomina jẹ ojuna lati dokoowo, ti kii ṣe lati ṣiṣẹ sin awọn araalu ati pe ko ni ifẹ awọn eeyan lọkan bikoṣe ohun to le ko sapo ara rẹ.

Oludije lẹgbẹ oṣelu APC naa fi kun pe oun ṣe abẹwo si Obasanjo pẹlu erongba lati ri daju pe ko si ikunsinu laaarin gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ leyin ti wọn panupọ yan oun, ti oun si ri gẹgẹ bi eni to ni erongba rere fun awọn araalu ṣugbọn ti oun pada ri pe imọtara ẹni nikan lo n ba ja.

"Ki eeyan maa beere lọwọ mi lati da owo to na fun ipolongo ibo pada fun oun jẹ ohun abuku fun mi. O ti kuro ninu ẹgbẹ bayii, kii ṣe pe ẹgbẹ ṣẹ ẹ lẹṣẹ bikoṣe nitori pe awọn kan fi owo lọ ẹ."