You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
ICPC ṣàwárí ayédèrú òṣìṣẹ́ 908 láwọn iléeṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà àádọ́ta, ọlọ́pàá pọ̀ nínú wọn
Ko din ni ẹẹjọlelẹẹdẹgbẹrun (908) ayederu oṣiṣẹ ti ajọ ICPC to n ri si iwa ajẹbanu atawọn iwa to farapẹ ẹ ti kede bayii pe wọn n gbowo lọwọ ijọba lai ṣiṣẹ lawọn ẹka iṣẹ ọba lorilẹede Naijiria.
Ninu awọn ẹka naa ni ICPC ti darukọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria.
Alaga ICPC, Musa Adamu Aliyu (SAN) fidi eyi mulẹ fun BBC.
Ayederu oṣiṣẹ ni awọn ti orukọ wọn wa lori iwe igbowo oṣu, ti wọn n gba owo amọ ti wọn ko si lẹnu iṣẹ ọba, ti wọn ko si ki n ṣiṣẹ kankan.
Gẹgẹ bi Alaga ICPC ṣe ṣalaye, o ni aṣiri naa tu lasiko tawọn n ṣayẹwo awọn orukọ to wa lori iwe igbowo awọn ẹka ileeṣẹ ijọba naa ninu eto kan lọdun 2024.
Aliyu sọ pe awọn bẹrẹ iwadii lẹyin tawọn ri i pe magomago wa ninu owo ifẹyinti tawọn kan gba.
O tẹsiwaju pe ijọba ti gbẹsẹle owo to to N942m, eyi ti i ṣe ($683 thousand) owo dọla to ni i ṣe pẹlu jibiti owo oṣu ti wọn n lu ijọba.
Awọn ẹka wo ni ayederu oṣiṣẹ pọ si ju?
Nigba to n ṣalaye ẹka ti awọn agbowomaṣiṣẹ naa pọ si ju, Alaga ICPC sọ pe iwadii fi han pe o kere tan, aadọta (50) ileeṣẹ ijọba atawọn ajọ ni ọrọ naa kan.
Amọ Aliyu darukọ marun-un ninu wọn to ni ibẹ ni awọn ayederu oṣiṣẹ naa ti gbilẹ ju.
Awọn ileeṣẹ ijọba naa bo ṣe darukọ wọn ni:
- 1 – Ileeṣẹ eto aabo
Ileeṣẹ eto aabo Naijiria lo wa nipo karun-un ninu awọn ibi ti ayederu oṣiṣẹ pọ si.
"Ni minisiri eto aabo, a ri eeyan mọkandinlogun (19) ti wọn jẹ ayederu oṣiṣẹ." Alaga ICPC lo ṣalaye bẹẹ.
- Ẹka ileeṣẹ ọba yii lo n ri si ọrọ awọn ologun ni Naijiria.
- Awọn ẹka ileeṣẹ ọba mi-in to tun darukọ ni
- Ileeṣẹ mọnamọna – Eeyan mẹtadinlogun
- Ileeṣẹ Okoowo– Eeyan mẹtadinlogun
- Ilera– Eeyan mẹẹẹdogun
- Ọfiisi Olori oṣiṣẹ – Eeyan mejila
- Ọfiisi Oluṣiro owo agba nilẹ Naijiria
- Ileeṣẹ ọrọ Abẹnu
2. Ajọ ọlọpaa
Alaga ICPC ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria wa lara awọn ti aṣiri rẹ tu pe ayederu oṣiṣẹ pọ nibẹ.
"Ninu eto yii, a ri eeyan aadọrinlelẹẹdẹgbẹta (570) ti a frura si pe ayederu oṣiṣẹ ni wọn, ti wọn n gba owo osu lai ṣiṣẹ."
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria jẹ ẹka kan gboogi ti igbanisiṣẹ ti maa n waye gidi.
3. Ileeṣẹ ijọba apapọ to n pese omi
Ọpọ ayederu oṣiṣẹ ni ICPC sọ pe iwadii fi han nileeṣẹ to n ri si ipese omi lẹka ijọba apapọ.
"Ni ajọ yii, a ri ọgọrin orukọ (80) awọn eeyan ti wọn n gba owo oṣu bi wọn ko tilẹ ki n ṣe oṣiṣẹ ajọ naa."
Amofin Adamu lo sọ bẹẹ fun BBC.
4. Ileeṣe òde
Ileeṣẹ to n ri si iṣẹ ode lẹka ijọba apapọ ti a mọ si Federal Ministry of Works, wa lara awọn ajọ ti ICPC ti ṣawari ayederu oṣiṣẹ.
"A ri ayederu oṣiṣẹ mẹrindinlọgọta."( 56)
Bẹẹ ni Alaga ICPC wi.
Ileeṣẹ yii lo n ri si eto ati bi wọn ṣe n ṣe awọn ọna marosẹ kaakiri Naijiria.
5. Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere
Ileeṣẹ yii lo wa ni ipo kẹrin ninu awọn ẹka ijọba ti ayederu oṣiṣẹ pọ si julọ, gẹgẹ bi ICPC ṣe fidi ẹ mulẹ.
Alaga ICPC sọ nipa ileeṣẹ yii pe:
"Ni ileeṣẹ yii, a ri eeyan mẹrinlelogun (24) ti wọn je ayederu oṣiṣẹ."
Ileeṣẹ yii lo n ri si ọrọ to ba kan Naijiria nilẹ okeere ati ajọṣepọ wọn.