Kí ni ipa tí ìdásílẹ̀ ibùdó ológun tuntun ní Omu-Aran, Kwara, yóò ní lórí àwọn ajínigbé, àgbésùnmọ̀mí àti aráàlú? Àwọn onímọ̀ sọ̀rọ̀

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Lẹyin ti ijọba ipinlẹ Kwara kede pe Aarẹ Tinubu ti buwọlu dida baraaki mii silẹ ni ilu Omu-Aran, ipinlẹ Kwara ni oniruuru ibeere ti n jẹyọ pe ṣe igbesẹ naa maa tan ipenija aabo to n ba ipinlẹ naa finra paapaa ni ẹkun Guusu ti ikọlu awọn agbebọn ti di tọrọ fọka sile.

Ọkan lara awọn ipinlẹ ti iwa ijinigbe ati ikọlu awọn agbebọn ti n waye lemọlemọ lati bii ọdun mẹta sẹyin bayii ni Kwara wa bayii.

Ọpọ eeyan lo si ti n kọminu lori ohun ti ijọba le ṣe lati koju ipenija yii ki gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq to kede pe Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu dida baraaki mii si ipinlẹ naa lati koju ikọlu awọn agbebọn naa.

Eyi lo mu BBC News Yoruba kan si awọn onimọ nipa eto aabo lati beere boya igbesẹ yii le tan iṣoro ipenija aabo to n mu ki ọpọ eeyan maa sa kuro ni ile igbe wọn lati sa asala fun ẹmi wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa lo ni ojuṣe lati da aabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu ṣugbọn ti ikurẹtẹ ti ba ileeṣẹ ọlọpaa, wọn ko le ṣe ojuṣe wọn mọ - Lukman Gidado

Onimọ nipa eto aabo, Lukman Gidado, ẹni to jẹ ọgagunfẹyinti lenu iṣẹ Ologun ni bi o tilẹ jẹ pe igbesẹ to dara ni ijọba gbe pẹlu erongba lati kọ baraaki ọlọpaa si ilu Omu-Aran, amọ o ni ijọba ti n ya kuro lori ojuṣe awọn ẹṣọ aabo kọọkan.

Gidado ni labẹ ofin Naijiria, ileeṣẹ ọlọpaa lo ni ojuṣe lati da aabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu ṣugbọn ti ikurẹtẹ ti ba ileeṣẹ ọlọpaa lonii ti wọn ko le ṣe ojuṣe wọn mọ.

O ni niṣe lo yẹ ki ijọba ṣe igbelarugẹ fawọn ọlọpaa, ki wọn ro wọn lagbara, ki wọn si fun wọn ni awọn ohun eelo to yẹ lati fi ṣiṣẹ, ki wọn ba le maa ṣe ojuṣe wọn bo ṣe to ati bo ṣe yẹ.

O fi kun pe ti awọn ọlọpaa ba n ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ, o maa fi aaye gba awọn ologun naa lati mojuto ohun to jẹ ojuṣe wọn ni pato paapaa ni awọn ẹnubode to ti di taja tẹran bayii.

Gidado tẹsiwaju pe ọpọ awọn ẹka lo wa ninu iṣẹ ọlọpaa bii IRT, awọn to wa fun gbigbogunti igbeṣumọmi atawọn ẹka mii ti wọn le koju awọn agbeṣumọmi atawọn agbebọn yii laisi idasi awọn Ologun ti ijọba ba ro wọn lagbara bo ṣe yẹ.

O ni awọn ọlọpaa nilo idanilẹkọọ loorekoore ati ipese awọn amayedẹrun fun wọn ki iṣẹ wọn le maa lọ deedee.

O digba ti ijọba ba binu, maa koju awọn ajinigbe ati agbeṣumọmi ṣaaju ki wọn to ṣe ikọlu ki eto aabo to duro ire ni Naijiria - Akin Adeyi

Ninu ọrọ tirẹ, Akin Adeyi ti oun naa jẹ onimọ nipa eto aabo nigba to n sọrọ lori igbesẹ naa woye pe ṣe gbogbo awọn ipinlẹ ti igbeṣumọmi n waye nibẹ ni ijọba maa ṣi baraaki awọn ologun si.

O ni owo ati akoko to maa n gba lati ṣagbekalẹ baraaki kii ṣe ohun to kere rara ati pe o ṣeeṣe ki ipenija aabo tun ti peleke sii lagbegbe naa ki baraaki ṣiṣe naa to kẹsẹ jari.

Adeyi tẹsiwaju pe ohun to yẹ ko jẹ afojusun ijọba ni awọn igbesẹ ti wọn maa kọkọ gbe lati ri pe wọn fopin si iwa igbeṣumọmi atawọn ijinigbe to n waye ni agbegbe naa.

O sọ pe o yẹ ki ijọba ṣe ibudo fun awọn ọmọ ogun fun igba diẹ na ni agbegbe lati maa mojuto eto aabo dipo kikọ baraaki mii sibẹ.

O ni bi o tilẹ jẹ kikọ baraaki si agbegbe ni awọn igbega to maa n mu bae to ọrọ aje ibẹ, o ni awọn aleebu ti gbigbe baraaki awọn ologun si agbegbe naa maa n ni ko kere, to si le ṣakoba fun igbeaye irọrun fun awọn araalu naa.

O fi kun pe ijọba nilo lati binu, ki ibinu wọn ju ti awọn agbeṣumọmi lọ to jẹ pe wọn ko ni maa nilo lati maa duro de ikọlu awọn agbeṣumọmi atawọn agbebọn naa ki wọn to gbe igbesẹ.

Onimọ nipa eto aabo naa o digba ti ijọba ba bẹrẹ si ni gbena woju awọn oniṣẹ ibi naa lai duro de igba ti wọn maa kọkọ ṣe ikọlu sawọn eeyan ki ijọba to gbe igbesẹ lo le fopin si ikọlu awọn oniṣẹ ibi naa patapata.

Tinubu dá ibùdó ológun míì sílẹ̀ ní Omu-Aran, Kwara láti kojú ìjínigbé àti ìkọlù àwọn agbébọn

Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ti buwọlu idasilẹ ibudo awọn Ologun mii si ipinlẹ Kwara lojuna ati mu eto aabo gbopọn sii, koju igbeṣumọmi, ijinigbe atawọn iwa ipa mii to n waye ni ipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq fi soju opo X rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kọkanlelogun, oṣu Keje sọ pe ilu Omu-Aran ni ijọba ibilẹ Irepodun ni ibudo ọmọ ogun naa maa wa.

Gomina Abdulrasaq sọ pe oun gbagbọ pe ibudo ọmọ ogun naa maa mu alekun ba iye awọn Ologun to wa ni ipinlẹ Kwara to si maa ni ipa rere lati fopin si ijinigbe ati ikọlu awọn agbebọn to maa n waye ni agbegbe naa.

Ibudo Ologun yii lo jẹ didasilẹ bi ipenija aabo ṣe n peleke ni awọn ẹkun guusu Kwara nibi ti ọpọ eeyan ti n sa kuro ni ile lati sa asala fun ẹmi wọn

Gomina naa tun juwe ibuwọlu idasilẹ ibudo awọn Ologun naa bii ifarajin ijọba apapọ lati koju awọn ipenija aabo to n ba ipinlẹ naa finra.

Nigba to n dupẹ lọwọ awọn Aarẹ Tinubu fun bibuwọlu ibudo awọn ọmọ ogun naa, Abdulrasaq ni o maa mu igbooro ba eto aabo, to si maa gbogunti igbeṣumọmi ati ijinigbe ni agbegbe naa.

O tun gboriyin fun ọga agba ileeṣẹ Ologun, Ọgagun Waidi Shaibu ati olubadamọran aabo fun aarẹ Tinubu fun bi o ṣe tete ṣe amuṣẹ ibeere awọn lati pese ibudo Ologun naa lojuna ati koju iwa ọdaran.

O fi kun pe awọn ẹṣọ aabo ṣi n tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ti wọn n ṣe lati gba itusilẹ awọn eeyan to wa ni ahamọ awọn ajinigbe ati lati le gbogbo awọn ọdaran to wa ninu igbo Kwara jina.

Ibuwọlu ibudo awọn Ologun yii lo n jẹ idasilẹ bi ipenija aabo ṣe n peleke ni awọn ẹkun guusu Kwara nibi ti ọpọ eeyan ti n sa kuro ni ile lati sa asala fun ẹmi wọn.

Lara awọn ilu to ti dahoro ni a ti ri Babanla, Owa-Onire ni ijọba ibilẹ Ifelodun nibi ti ikọlu awọn agbebọn ti n waye lemọlemọ.