You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ohun tó ń fà àìsàn rọpárọsẹ̀, ìtọ́jú àti ìdènà rẹ̀, báwọn èèyàn ṣe ń ní àìsàn náà láàrin ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan ní Naijiria
Bi oni ọjọ kejilelogun oṣu Keje ṣe jẹ ayajọ ilera ọpọlọ lagbaaye, awọn dokita onimọ itọju ọpọlọ ni Naijiria ti sọ pe ni iṣẹju kọọkan lawọn eeyan n lugbadi arun rọparọsẹ lorilẹede Naijiria.
''Ilera ọpọlọ fun gbogbo eeyan'' ni akori ayajọ ilera ọpọlọ ti ọdun 2026 yii gẹgẹ bi ẹgbẹ World Federation of Neurology ṣe kede rẹ.
Lara nnkan tawọn dokita naa n kọminu le lori ni pe awọn onimọ iṣegun nipa ilera ọpọlọ ko to nnkan lorilẹede Naijiria.
Awọn dokita onimọ nipa ilera ọpọlọ ṣalaye fun iwe iroyin Punch wi pe arun rọparọsẹ ni arun to n ṣakoba fun ọpọlọ julọ lorilẹede Naijiria.
Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa itọju ọpọlọ tun fidi rẹ mulẹ pe ida 80% arun rọparọsẹ ni o ṣe e dena.
Nigba to n sọrọ nipa ilera ọpọlọ ati bi arun rọparọsẹ ṣe n ṣọṣẹ ni Naijiria, Ọjọgbọn Mayowa Owolabi, to jẹ onimọ nipa itọju ọpọlọ ni ile ẹkọ giga Fasiti UI niluu Ibadan sọ pe lẹyin-lẹyin ni orilẹede Naijiria si wa nipa wiwa ojutuu si arun rọparọsẹ.
Ọjọgbọn Owolabi, to jẹ alaga ajọ Lancet Commission on Stroke to n ri sọrọ arun rọparọsẹ sọ pe arun naa n tan kalẹ si i lojoojumọ ni Naijiria.
Ki lo n fa arun rọparọsẹ gan an?
Dokita Salihu Ibrahim Kwaifa, onimọ nipa aisan rọparọsẹ niluu Abuja sọ pe ẹjẹ riru jẹ idi kan pataki tawọn eeyan maa fi n ni aisan ọkan, awọn to ba si ti ni i le lugbadi rọparọsẹ.
Itọ ṣuga: Nnkan keji to tun n fa rọparọsẹ ju lẹyin ẹjẹ riru ni aisan itọ ṣuga(Diabetes).
Awọn eeyan to ba ni itọ ṣuga wa ninu ewu ati ni rọparọsẹ.
Aisan ọkan: Dokita Kwaifa ṣalaye pe aisan ọkan naa le fa rọparọsẹ.
Arun ko-gboogun (HIV).
Ọjọgbọn Owolabi naa ṣalaye wi pe fifi ori ṣeṣe le jẹ ki eeyan ni arun rọparọsẹ ti ipalara naa ba ṣakoba fun ọpọlọ.
Ninu ọrọ rẹ, dokita onimọ nipa itọju ilera ọpọlọ tun sọ pe aito awọn dokita onimọ nipa itọju ọpolọ naa n ṣokunfa bi arun rọparọsẹ ṣe di tọrọ fan kale ni Naijiria.
''Pẹlu bi eeyan to wa ni Naijiria ṣe le ni miliọnu 250, a o ni dokita itọju ọpọlọ to to, bakan naa ni a o awọn oṣiṣẹ eleto ilera to mọ nipa itọju ọpọlọ.''
Ọjọgbọ Owolabi tun sọ pe aitete ri itọju gba lori aisan to le fa arun rọparọsẹ naa maa n ṣokunfa nini arun naa.
Airowo lati lọ gba itọju nile iwosan le fa arun rọparọsẹ.
Lilo ilana ibilẹ ati ẹsin fun itọju arun to le ṣokunfa rọparọsẹ naa le fa arun naa.
Awọn ounjẹ to ba ni ọra pupọ ati awọn ounjẹ ti wọn ba se silẹ sinu agolo naa maa ṣakoba fun ẹjọ eyi to maa ni ipalara fun ọpọlọ.''
Ailọ sile iwosan lati ṣalaye nigba tawọn eeyan ba kọkọ ri awọn apẹẹrẹ yii lo n fa a to fi n di rọparọsẹ mọ wọn lọwọ. "
Apẹẹrẹ arun rọparọsẹ
Ọna meji ni rọparọsẹ pin si, bi Dokita Kwalifa ṣe ṣalaye.
Akọkọ ni rọparọsẹ to waye latari aito ẹjẹ to n lọ sinu ọkan.
Ikeji ni eyi to ṣẹlẹ latari ẹjẹ to di to si tuka sinu ọpọlọ tabi si itosi rẹ.
Awọn apẹẹrẹ ti ẹni ti rọparọsẹ kọlu yoo maa ri ni
Yoo jọ pe ara rẹ n wuwo
Ẹni naa yoo ri i pe oju oun kan ko riran mọ.
Oju rẹ yoo yi si ẹgbẹ kan.
Ara rẹ yoo maa da bii ẹni ti pajapaja mu.
Ko ni i le sọrọ.
Lẹyin wakati kan ṣa, Dokita sọ pe awọn apẹẹrẹ yii yoo poora.
"Ẹni to ba koju apẹerẹ wọnyi ni ida aaọrin si ọgọrin (70 to 80 percent), bi ko ba tọju ara rẹ daadaa, rọparọsẹ yoo kọlu u laaarin oṣu kan si oṣu meji."
Dokita Kwalifa lo ṣalaye bẹẹ.
O ni rọparọsẹ naa yoo ṣẹlẹ nigba ti ẹni naa ko ba mọ nnkan to n ṣẹlẹ layika rẹ mọ, ori ko si ni i fọ ọ ti yoo fi ri i pe ọwọ ati ẹsẹ ti rọ.
Fun ti rọparọsẹ ti ẹjẹ di sinu ọpọlọ tabi itosi rẹ, Dokita Kwalifa sọ pe:
"Bi iru rọparọsẹ yii ba waye, ẹni naa yoo ṣubu lulẹ, ko ni i mọ nnkan kan mọ.
Ṣugbọn ṣiwaju akoko naa, ori yoo maa fọ ọ, yoo si rẹ ẹ.
Bi o ṣe le dena arun rọparọsẹ niyi
Dokita ka awọn ọna yii:
Jijẹ ounjẹ to dara to si n ṣe ara loore.
Ṣiṣe ere idaraya deede.
Yago fun mimu siga ati ọti.
Ṣe itọju itọ ṣuga ti o ba ni.
Maa yẹ ifunpa rẹ wo deede.
Din wahala ṣiṣe ku
Kan si dokita rẹ deede.
Ijọba ni lati gba awọn dokita onimọ nipa itọju arun rọparọsẹ si i lawọn ile iwosan ni Naijiria.
Iranwọ ti o le ṣe fun ẹni ti arun rọparọsẹ ba mu lojiji
Rọparọsẹ le ṣẹlẹ si ẹnikẹni nibikibi, nigbakugba. Nile, nibi iṣẹ, lojuu popo, koda nigba ti eeyan ba n sọrọ lọwọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ.
Gẹgẹ bi Dokita Kwalifa ṣe ṣalaye, rọparọsẹ maa n waye nigba ti ẹjẹ ba dì, ti opo to n gbe ẹjẹ lọ sinu ọpọlọ ko ba le gbe ẹjẹ lọ sibẹ mọ, tabi ti opo ẹjẹ ba bẹ, ti ẹjẹ ko raye denu ọpọlọ mọ.
Nigba to si jẹ pe ọkọ̀ pajawiri (ambulance) to n gbe oku ati alaye ki i tete de ni Naijiria, tabi ko ma tete de ọdọ ẹni ti rọparọsẹ kọlu, awọn to ba wa nitosi ẹni bẹẹ gbọdọ mọ itọju akọkọ yii lati ṣe:
Fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún tàbí ti òsì ẹni náè lélẹ̀:Bi rọparọsẹ ba ṣẹṣẹ kọlu ẹnikan, ma ṣe fi ẹyin ẹni naa lelẹ lori ibusun pẹlu ahọn rẹ to yọ sita. Ahọn to yọ sita naa le di ọna ti yoo gba mí, eyi si le fa iku fun un.Ẹgbẹ ọtun tabi ti osi ẹni naa ni ko o fi lelẹ lori ibusun.
*Rí i dájú pé ẹni náà ń mí dáadáa :Dokita Kwaifa ṣalaye, pe, "Ti o ba fẹẹ ri i daju pe ẹni naa n mi, fi ọwọ kan apa rẹ tabi ibi ọrun rẹ nibi ti mimi ti maa n han, wa a ri i pe o n mi.
Mu aṣọ tabi ohunkohun to le di mimi rẹ lọwọ kuro lọrun ati aya rẹ, ki ẹni naa le mi daadaa.
Mu ohunkohun to ba le pa a lara kuro pẹlu.
Ma ṣe fun ẹni naa ni ounjẹ, omi tabi oogun kankan lo.