You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkùnrin tó gbé aláìsàn wá sílé ìwòsàn Adeoyo n'Ibadan yarí pé kò sí dókítà lẹ́nu iṣẹ́, ó yájú sí Nọ́ọ̀sì, ẹgbẹ́ àwọn Nọ́ọ̀sì fọnmú
Niṣe ni ọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna nigba ti ọkunrin kan de ile iwosan agbẹbi ti awọn olukọni ti Adeoyo to wa lagbegbe Yemetu niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo, to si da wahala silẹ nibẹ.
Ọkunrin naa ti a ko mọ orukọ rẹ, lo gbe eeyan rẹ kan to n ṣaisan lọ sile iwosan naa fun itọju, ṣugbọn ti wọn sọ pe ko si dokita kankan lẹnu iṣẹ lasiko naa.
Loju ẹsẹ ti wọn sọ fun ọkunrin naa pe ko si dokita lẹnu iṣẹ ni alẹ ọjọ naa, lo ti sọ ọrọ ọhun di ariwo, to si bẹrẹ sii ṣe ikọlu si Nọọsi to ba lẹnu iṣẹ.
Fọnran aworan ọkunrin naa to gba ori ayelujara kan, lo se afihan bo se gbe foonu rẹ, to si bẹrẹ si se fidio pẹlu erongba lati gbe e sori ayelujara, bakan naa lo tun ṣe ikọlu si obinrin Nọọsi to wa lẹnu isẹ lọjọ naa.
Ninu ọrọ ti a gbọ ninu fọnran ọhun eyi to tẹ BBC News Yoruba lọwọ, a gbọ ti ọkunrin naa sọ pe:
"O n sọ fun mi pe ko si dokita ni ile iwosan Adeoyo, to ba ku n kọ? Ko si dokita ni Adeoyo. Ori rẹ buru ni. Nibo lo n salọ."
Ọkunrin naa wa jẹ ko di mimọ pe, bi oun ṣe n ya fidio lati ya aworan obinrin ọhun, loun funra oun tun n ya fọnran ara oun.
Nibẹ ni Nọọsi naa ti bẹrẹ si sọrọ wi pe "Ṣe ẹ fẹ na mi ni, mo sọ pe ko si dokita nitosi. Ẹ maa na mi, ṣe emi ni dokita ni?"
Àwọn aráàlú sọ̀rọ̀ lórí fidio to gba ori ayelujara naa
Kete ti fọnran naa ti bọ sori ayelujara ni awọn eeyan ti bẹrẹ sii sọ oniruuru ọrọ, koda ti iṣẹlẹ ọhun tun di ariyanjiyan laaarin awọn ọmọ Naijiria.
Bi awọn kan ṣe n tako ọkunrin to ṣe fọnran yii, bẹẹ ni awọn miran n bu ẹnu atẹ lu bi awọn dokita ko ṣe si nile iwosan lasiko naa, ti awọn miran si tun n da ijọba Naijiria lẹbi.
Ẹgbẹ́ àwọn Nọ́ọ̀sì àti Agbẹ̀bí fẹ̀hónúhàn pe ki ijọba fi kele ofin gbe ọkunrin to yaju si Nọọsi to wa lẹnu isẹ nile iwosan Adeoyo
Ju gbogbo rẹ lọ, ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ Nọọsi ati Agbẹbi nilẹ wa, NANNM, ẹka tipinlẹ Oyo, ti wa bu ẹnu atẹ lu iwa ti ọkunrin naa hu, lori bi wọn ṣe lo ṣe ikọlu si ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
NANNM rọ awọn ileeṣẹ eleto aabo ati agbofinro lati fi kele ofin gbe ọkunrin naa lori bo ṣe ṣe ikọlu si ọmọ ẹgbẹ wọn nile iwosan agbẹbi ti awọn olukọni to wa ni Yemetu niluu Ibadan.
Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Kọmureedi Aina Emmanuel Oluwasegun ati alaga wọn nipinlẹ naa, Kọmureedi Adeleke Olugbade Victor buwọ lu, wọn sọ pe niṣe ni ọkunrin naa ti wọn ko mọ fa ibinu yọ lori bi dokita ko ṣe si lẹnu iṣẹ lasiko iṣẹ ọhun.
Wọn fi kun ọrọ wọn wi pe ẹdun ọkan lo n jẹ fun wọn pẹlu bi awọn eeyan ṣe n ṣe ikọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ wọn loorekoore lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ oojọ wọn lọwọ, ti wọn si lawọn nilo eto aabo to pe ye, nitori pe ko yẹ ki awọn di ẹni to n koju iṣoro ipenija eto aabo lẹnu iṣẹ.
"A le dena awọn ikọlu naa, bi awọn oṣiṣẹ eleto aabo to to ba wa nile iwosan, awọn to n ṣe ikọlu maa n na papa bora nigba ti wọn ba ṣiṣẹ ibi tan"
Siwaju sii ni wọn sọ ọ di mimọ pe aisi oṣiṣẹ to to lẹnu iṣẹ lo n jẹ ki iṣẹ pọ, bi awọn alaisan ṣe n pẹ nile iwosan, ati ẹru iṣẹ rẹpẹtẹ lọrun awọn lọrun oṣiṣẹ eleto ilera perete to wa.
NANNM sọ pe ọpọ igba ni awọn ti kọwe si ijọba ipinlẹ Oyo, ileeṣẹ eleto ilera ati igbimọ iṣakoso ile iwosan nipinlẹ Oyo, lati tete gba awọn oṣiṣẹ eleto ilera bii nọọsi ati agbẹbi sẹnu iṣẹ, lati le di alafo to wa nilẹ.
Bakan naa ni wọn rọ ijọba lati ṣe afikun lori awọn oṣiṣẹ eleto aabo lawọn ile iwosan ijọba, lati le maa daabo bo awọn eleto ilera ati alaisan.
Wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ikọlu naa ṣe e dena, bi awọn oṣiṣẹ eleto aabo to to ba wa nile iwosan, ati pe awọn to n ṣe ikọlu maa n na papa bora nigba ti wọn ba ṣiṣẹ ibi tan.
Bakan naa ni wọn rọ ijọba ipinlẹ Oyo lati dide si iwadii lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si fọwọ ṣikun ofin gbe ọkunrin naa, ati pe ki wọn foju rẹ winna ofin lori iwa to hu si ọmọ ẹgbẹ wọn.