You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun tí BBC rí rèé níbùdó tí wọn ti ń po kẹ́míkà pọ̀ lọ́nà àìtọ̀ tó tó $400m táwọn ọmọ ilẹ̀ Mexico ń ṣe
Laipẹ la mu iroyin wa fun yin nipa ibudo ipoogun ati kẹmika kan ti asiri rẹ tu sawọn alasẹ ilẹ Naijiria lọwọ.
Nibẹ si ni wọn ti gbẹsẹ le awọn oogun ati kẹmika ti owo rẹ fẹ to miliọnu lọna irinwo Dọla.
Osu karun ọdun 2026 ni isẹlẹ naa waye, ti ọwọ si tẹ awọn ajeji ọmọ ilẹ Mexico to n se akoso ibudo oogun ati kẹmika ti ko ba ofin mu naa.
Iwadi awọn agbofinro si fihan pe awọn afurasi yii lo wa ninu ẹgbẹ awo awọn eeyan to n gbe oogun oloro.
Ijọba Naijiria ti ko awọn eeyan naa lọ sile ẹjọ, to si seese ki wọn gba idajọ laipẹ.
Akọroyin BBC wa se abẹwo si ibudo ti wọn ti n se kẹmika naa, lasiko ti awọn olugbẹjọ to fẹ joko se iwadi isẹlẹ naa se abẹwo si ibudo ọhun.
Inu igbo jinjin kan ni ẹkun Guusu iwọ oorun Naijiria ni ibudo naa wa.
Lọjọ ti BBC lọ sibẹ, awọn ti wọn si fẹsun kan pe wọn n ṣakoso ibudo yii naa wa lẹgbẹ kan nibẹ.
Eyi ri bẹẹ nitori awọn alaṣẹ sọ pe awọn ṣẹṣẹ ṣawari ibi to tobi julọ ti wọn ti n po oogun pọ lọna aitọ atawọn kẹmika ti wọn n lo lati fi ṣe wọn eyi ti iye rẹ to irinwo miliọnu dọla ($400m), ti wọn si n fẹ ki ile ẹjọ wa wo bi ibẹ naa ṣe to.
A ri awọn agbada ti wọn n lo atawọn kẹmika, to fi mọ awọn ohun elo mii ti wọn n lo lati fi po oogun naa pọ nibi.
Lẹyin ti wọn ṣawari ibudo yii, wọn tun ṣawari ibudo kẹmika miran laaarin oṣu kan sira wọn
Agbada nla to tobi, ti oogun Meth olomi kun inu rẹ wa nilẹ, awọn meth ti wọn ko i tii po papọ mọ kẹmika mii lo wa nilẹ bakan naa.
Koda, oorun to n ti inu agbada naa jade lagbara gidi, o n run bii kẹmika to lagbara, a si tun ri awọn ohun elo mii ti wọn n lo nibi.
Lasiko igbẹjọ naa, adajọ to n gbọ ẹjọ naa atawọn igbimọ olugbẹjọ jokoo si apakan, ti wọn si to awọn afurasi sẹgbẹ kan lọwọọwọ pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ.
Awọn oluwadii sọ pe bi awọn ibudo ti wọn ti n po oogun Meth lọna aitọ ṣe n pọ ni si ẹkun Africa n kọ awọn lominu paapaa awọn to n ni ajọṣepọ pẹlu awọn ara Mexico.
Koda lẹyin ti wọn ṣawari ibudo yii, wọn tun ṣawari ibomiran ti ko jin ju iwọn kilomita aadọjọ (150km) lọ si ibudo naa laaarin oṣu kan sira wọn.
Nibẹ ni wọn ti wọn ti mu awọn afurasi marun-un to fi mọ ọmọ orilẹ ede Mexico kan ninu wọn.
Wọn ni iṣẹlẹ yii ti n waye leralera ni Africa, to si n jọ pe wọn fẹ maa lo Africa lati fi po awọn oogun yii.