Níbo Layé Kọjú Sí? Ṣé kí lọ́kọláya máa gbé ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ le mú ewu dání bí?
Níbo Layé Kọjú Sí? Ṣé kí lọ́kọláya máa gbé ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ le mú ewu dání bí?
Published
Ki lọkọlaya maa gbe ni ilu ọtọọtọ jẹ ohun to maa n fa ariwisi ni ọpọ igba.
Yatọ si ki eeyan ma fi inu tan ara ẹni to maa n fa awuyewuye, aisi anfaani lati maa faraọ ololufẹ ẹni tabi maa ni itakurọsọ ni gbogbo igba jẹ ohun tawọn eeyan kan ṣe maa n sọ pe awọn ko le gba ki ọkọ tabi aya awọn maa gbe lọtọ.
Lori eto nibo laye kọju si lọtẹ yii, BBC News Yoruba ṣagbeyẹwo ero awọn araalu lori ki ọkọ tabi aya wọn wa ni ilu ọtọ si ibi ti wọn wa.
Bakan naa la tun ba gbajumọ Sade Okoya sọrọ lori ipa ti ki obinrin maa ṣiṣẹ maa ni lara wọn.






