Ilé dàwó ní Eko, gbẹ̀mí ìyá àgbàlagbà kan

Oríṣun àwòrán, @lasema/X
Ìyá àgbàlagbà kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tí ilé kan dàwó ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ní òpópónà Oloto, agbègbè Oyingbo ní ìpínlẹ̀ Eko.
Àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Eko, Lagos State Emergency Management, LASEMA nínú àtẹ̀jáde kan ní ilé tó dàwó ló ṣokùnfà ìkú ìyá náà.
LASEMA ní kò sí ẹlòmíràn tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
Wọ́n ṣàlàyé pé irin tí wọ́n fi di ilé náà mú ló ṣàdédé wó lulẹ̀ ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ kú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún lọ́jọ́bọ̀ tó sì fa kí ilé náà dàwó.
LASEMA ní ilé náà ti gbó tí wọn kò sì ṣe àmójútó rẹ̀ mọ́.
Wọ́n ní àwọn ti kàn sí àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ilé ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn Lagos State Building Control Agency (LABSCA).
Bákan náà ni wọ́n fi kun pé àwọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láti fi mọ̀ bóyá àwọn ènìyàn kò há sínú ilé náà.



















