Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria ṣekúpa agbésùmọ̀mí 48, nígbà tí 974 jọ̀wọ́ ara wọn
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko din ni agbesumọmi mejidinlaadọta ti awọn ọmọ ogun
Naijiria ti ṣekupa kaakiri Naijiria lẹnu lọlọ yii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, ọgagun Musa Danmadami to fi ọrọ naa
to awọn akọroyin leti niluu Abuja sọ pe ko din ni agbesumọmi ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárun
ati mẹ́rìnléláàdọ́rin (974) atawọn ẹbi wọn ti wọn ti jọwọ ara wọn fun ileeṣẹ ọmọ
ọmọ ogun.
O fi kun pe awọn ọmọ oghun tun ṣawari owo ti iye rẹ to ₦2.3m lagbegba
ariwa ila oorun Naijiria.
Danmadami ṣalaye pe awọn ọmọ ogun to n ṣe akanṣe iṣẹ ‘Operation
Hadin Kai’ ti kọju ija lọpọ igba si awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ati ISWAP to n ṣoṣẹ
lagbegbe ọhun.
O ni ọpọ igba lawọn maa n lo ọkọ ofurufu lati ju ado
oloro si awọn agbesumọmi naa.
Ramadan àti ìsìn ìrékọjà àwọn Krìstẹ́nì dá wàhálà sílẹ̀ ní Jerusalem
Àkọlé fídíò, Al-Aqsa mosque: Watch clashes erupt as police raid contested Jerusalem holy site
Awọn fidio kan ti gba ori ayelujara kan to n ṣafihan bi awọn ọlọpaa ilẹ
Israel ṣe n lo ibọn ati igi lati fi ṣe iya fun awọn ara Palestine to n jọsin ti
wọn si pa ala si ibi ti wọn ti n kirun ninu mọsalasi Aqsa.
Awọn ọlọpaa Israel naa ti fi fọnran tiwọn sita eyi to n ṣafihan bi awọn ara
ilẹ Palestine ṣe n ju ohun abugbamu si gbọngan adura naa.
Awọn aworan to jade lẹyin iṣẹlẹ ṣafihan bi awọn tabili, aga ati ẹni adura ṣe
fọnka sori ilẹ.
Agbala Mosalasi Aqsa/Haram al-Sharif ni ibi kẹta to mọ julọ ninu ẹsin
Islam. Wọn tun maa n pe ibẹ ni Temple Mount, ibi to jẹ mimọ julọ ninu ẹsin awọn
Judaism.
Latẹyin wa, ọgba mọsalasi naa ti maa n foju ri ikọ̀lu laarin awọn ara
Palestine atawọn ikọ ologun Israel eyi to si n fa ọpọlọpọ aisi ifọkanbalẹ.
Ninu oṣu Karun ọdun 2021, ikọlu awọn Israel kan da ikọlukọgba alagbara kan
silẹ fun odidi ọjọ mọkanla laarin Irael ati Hamas eyi tii ṣe ẹgbẹ awọn alakatakiti
ẹsin Islam to n jọba ni Gaza.
Bakan naa lọdun to kọja, igba akọkọ ti Osu alapọnle ti Ramadan ati awọn eto
ti awọn ẹya Jew ti to silẹ fun odidi ọsẹ kan lati ṣaami isin irekọja ja papọ lu
ara wọn, ọpọlọpọ ija lo bẹ silẹ fun ọjọ pupọ lera lera ti o si gba ki awọn ọlọpaa
Israel mojuto agbegbe naa ki wọn to sin awn arinrinajo wọ inu ọgba naa.
Wọn ni ṣe ni wọn ju okuta si ara ogiri ibi mimọ yii ti awọn Jew ti maa n
gbadura.
Ẹwẹ, lọdun yii naa bayii, lati Ọjọru ọsẹ, ati pe fun opin ọsẹ meji to mbọ,
ajọdun ọdun Ajinde ni fun awọn kan.
Oríṣun àwòrán, EPA-EFE
Gbogbo asiko ayẹyẹ ọdun yii lo maa n fa oju awọn arinrinajo igbafẹ mọra si ilu nla naa.
Ọgọta ẹgbẹrun eeyan lo yẹ ko de si ilẹ Israel lọsẹ yii gẹgẹ bi akọsilẹ to wa.
Bi ọgọọrọ musulumi ṣe n farahan fun adura ọjọ Jimoh keji ninu aawẹ Ramadan bẹẹ naa ni ero n tu wọ Jerusalem to si jẹ pe wọn n da ọna pọ mọra lati wọle si ilu mimọ naa.
“Eyi dara amọ o jẹ nnkan to le da wahala silẹ paapaa eyi ti awọn oloṣelu le fa”.
Ara ilẹ Pallestine to n taja sọ bẹẹ bo ṣe n ta abẹla fun awọn Kristẹni to n lọ si ibi iboji mimọ eyi ti wọn kọ sibi ti awọn ẹlẹsin Kristẹni nigbagbọ pe wọn ti kan Jesu m igi, si in si ati to ti jinde.
Ṣaaju wahala to bẹ silẹ ni Ọjọru ọsẹ, ilu Hamas ti pe fun ki awọn olujọsin ti ara wọn mọ inu mọsalasi Aqsa ti wọn wa lati le dena ipinu awọn alakatakiti ẹsin Kristẹni kan to fẹ lọ rubọ ẹran ewurẹ fun isin irekọja lori oke, eyi ti wọn gbagbọ pe aṣa inu bibeli kan ni.
Wn bẹrẹ si ni kọlu ara wọn lẹyin ti awn Palestine ti ara wọn m inu mọsalasi lẹyin adura Ramadan.
Awọn ọlọpaa lo wa le gbogbo ero danu ṣugbọn ọpọ wọn lo ṣi duro sinu ile.
Ọlọpaa ṣalaye pe wahala naa waye latọwọ awọn arufin atawọn oni jagidijagan ti wọn ni wọn tabuku mọsalasi.
Awọn alaṣẹ ilẹ Israel ti fi ọrọ sita pe ki awọn eeyan gbiyanju lati pa ẹtọ fun ijọsin mọ lọna to ba wu ẹnikẹni.
Ilu mimọ yii ni awọn musulumi ri gẹgẹ bi ibi ti Anọbi Mohammed ti goke re ọrun, ibi yii kan naa ni awọn Kristẹni naa bọwọ fun gidi gan gẹgẹ bi ibi tẹmpili meji pataki to wa ninu Bibeli.
'Baba Sala tó bí mi lọ́mọ jẹ ìyà lójú mi dáadáa lágbo Tíátà, bí èmi náà ṣe di olórin..., hmmn!'
Ènìyàn méje jóná nínú ìjàmbá ọkọ̀ márosẹ̀ Ibadan sí Eko
Pínpín agbára sáwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ ló le mú àyípadà rere bá Nàìjíríà - Wole Soyinka
Oríṣun àwòrán, Facebook
Àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé nnì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka ti ránṣẹ́ sí
Bola Ahmed Tinubu, tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ tuntun.
Soyinka nígbà tó ń kópa níbi ètò Iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán Arise
TV ní ó pọn dandan kí Tinubu mú kí agbára dínkù lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ nìkan.
Ó ní agbára gbọdọ̀ bọ́ sí ọwọ́ àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ti
ìbílẹ̀ tí ìjọba Tinubu yóò bá ṣe ìjọba rere.
Ó fi kun pé nǹkan tó jẹ òun lógún tí òun sì ń fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba
tuntun tí yóò gorí àléfà ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ni bí ìjọba yóò ṣe
pín agbára sáwọn ẹsẹ̀ kùkú.
Àgbà òǹkọ̀wé náà ní bí ètò ìdìbò gbogbogboò náà ṣe lọ jẹ́
èyí tó kọnilóminú nítorí gbogbo àwọn ìwà jàgídíjàgán tó wáyé lásìkò náà.
Ó ní ètò ìdìbò náà kò bá ìrètí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń retí
ètò ìdìbò tí yóò lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀.
Bákan náà ló pàrọwà sáwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láti jìnà sí
gbígbé ìròyìn lọ́nà tí yóò da omi àláfíà Nàìjíríà bíkòṣe láti gbé ìròyìn bó bá ṣe
jẹ́ gan an.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Soyinka tún bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu
igbákejì olùdíje Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Datti Ahmed fún àwọn ìpèdè tó ń
jáde lẹ́nu rẹ̀.
Ó ní àwọn ọ̀rọ̀ náà le fa ìwà jàǹdùkú láàárín ìlú tó sì pàrọwà
si láti ṣọ́ra ṣe nítorí ìṣọ̀kan Nàìjíríà.
Irọ́ ni fọ́nrán tó gba ayélujára, mi ò pe ètò ìdìbò 2023 ní ìjà ẹ̀sìn - Peter Obi
Oríṣun àwòrán, Twitter
Àkọlé àwòrán, Peter Obi
Olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi ti
jáde sọ̀rọ̀ lórí fọ́nrán tó gba ayélujára lópin ọ̀sẹ̀ èyí tó ṣàfihàn bí òun àti
olórí ìjọ Living Faith Church Worldwide, Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo ti ń sọ̀rọ̀.
Obi ní fọ́nrán náà kìí ṣe òótọ́ wí pé àwọn kan ló mọ̀ọ́mọ̀
gbé fọ́nrán náà síta láti tàbùkù òun.
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ilé iṣẹ́ ìròyìn kan gbé fọ́nrán kan síta
tó sì gba orí ayélujára níbi tí Obi àti Bíṣọ̀ọ̀bù Oyedepo tí ń sọ̀rọ̀ tí Obi sì
ń sọ fún Oyedepo pé ìjà ẹ̀sìn ni ètò ìdìbò ọdún 2023.
Bákan náà ni fọ́nrán náà tún fẹ̀sùn kan Obi pé ó ń bẹ Bíṣọ̀ọ̀bù
Oyedepo pé kí ó bá òun bá àwọn ọmọlẹ́yìn Krìsìtẹ́nì sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Kwara
láti dìbò fún òun.
Ní ọjọ́ kejì ọjọ́ tí fọ́nrán náà gba orí ayélujára ni Bíṣọ̀ọ̀bù
Oyedepo ti sọ̀rọ̀ nílé ìjọsìn rẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú pé òun kò fìgbà kankan rí ṣe
ìpolongo fún olóṣèlú kankan àti pé nǹkan tí ẹ̀mí bá dárí òun nìkan ni òun máa ń
ṣe.
Ẹ̀wẹ̀, lálẹ́ ọjọ́rú ni Peter Obi tó fèsì sí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n
fi kàn án nínú fọ́nrán náà tó sì ní òun kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀.
Ó ní gbogbo nǹkan tí òun ṣe ìpolongo lé lórí lásìkò ìpolongo
ìbò jẹ́ àwọn nǹkan tó ń jẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà lógún láì fi ti ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn ṣe.
"Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sọ fún àwọn alátìlẹyìn mi pé kí wọ́n
má dìbò fún mi nítorí ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn bíkòṣe ìwà àti àwọn nǹkan tí mo ní láti
fi mú àyípadà rere bá Nàìjíríà."
"Kò sí ìgbà kankan tí mo pe ìbò ọdún 2023 ní ogun ẹ̀sìn,
irọ́ ni fọ́nrán tí wọ́n ń gbé kiri náà."
Obi fi kun pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti ìjọba tó wà lóde lábẹ́ ẹgbẹ́
APC ló ń wá ọ̀nà láti ṣí ojú àwọn ènìyàn kúrò ọ̀nà èrú tí wọ́n fi já ẹ̀tọ́ àwọn
gbà.
Bákan náà ló ní wọ́n ń gbèrò láti lé òun kúrò ní orílẹ̀ èdè
Nàìjíríà àmọ́ òun ní ìfarajìn sí gbígba ẹ̀tọ́ òun padà lọ́nà ẹ̀tọ́.
Ó fi kun pé òun ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti gbé Iléeṣẹ́ ìròyìn tó
gbé ìròyìn náà síta láìpẹ́.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.
End of X post
Ọlọ́pàá kan kú, DPO farapa nígbà tí ọlọ́kadà àtàwọn ọlọ́pàá fìjà pẹ́ẹ́ta ní Eko
Oríṣun àwòrán, Twitter
Níṣe ni ọ̀rọ̀ di bó ò lọ yà fún mi ní òpópónà márosẹ̀ Apapa
sí Oshodi ní ìpínlẹ̀ Eko nígbà tí àwọn ọlọ́kadà àtàwọn ọlọ́pàá fìjà pẹ́ẹ́ta.
Ní pápákọ̀ ti agbègbè Cele ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé tí àwọn ọlọ́kadà
náà sì pa ọlọ́pàá kan, tí wọ́n sì tún ṣe DPO àgọ́ ọlọ́pàá mìíràn léṣe.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
múlẹ̀ lórí ìkànnì Twitter rẹ̀ ní "Inspector" ni ọlọ́pàá tí àwọn
ènìyàn náà dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.
Hundeyin ní àwọn ọlọ́kadà náà tún ṣe ọ̀gá àgbà àgọ́ ọlọ́pàá
kan ìyẹn DPO léṣe.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ti nawọ́ gán àwọn afurasí méjì lórí ìṣẹ̀lẹ̀
yìí àti pé ọ̀kadà mọ́kànlélógójì ni àwọn ti gbẹ́sẹ̀ lé.
Ó fi kun pé àwọn ọlọ́pàá náà ń ṣe iṣẹ́ oòjọ́ wọn láti ṣe àmúṣẹ
òfin tó de àwọn ọlọ́kadà ní àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Eko.
"Lásìkò tí àwọn ọlọ́pàá yìí ń ṣe iṣẹ́ wọn lọ́wọ́ ni àwọn
ọlọ́kadà yìí ṣe ìkọlù sí wọn tí ọlọ́pàá kan sì kú lójú ẹsẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ìkọlù náà tún ṣokùnfà bí DPO kan ṣe fara gba
ọgbẹ́ tó lágbára.
Hundeyin sọ àrídájú rẹ̀ pé ọlọ́pàá Eko kò ní kò àárẹ̀ ọkàn
láti ṣe àmúṣẹ iṣẹ́ wọn èyí tó wà lábẹ́ òfin.
Bákan náà ló bú ẹnu àtẹ́ lu ṣíṣe ìkọlù sí àwọn ọlọ́pàá látọwọ́
àwọn ará ìlú.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.
End of X post
Ọkùnrin ẹni ọdún 27 fọwọ́ kan ọmọ oṣù mẹ́sàn án lọ́nà àìtọ́, ó dèrò Kirikiri
Oríṣun àwòrán, Oyinda Dada
Ile ẹjọ giga kan niluu Eko ti ni ki wọn fi ọkunrin ẹni ọdun
mẹtadinlọgbọn kan, Adebayo Agboola, sọgba ẹwọn Kirikiri lori ẹsun pe o ni
ibalopọ pẹlu ọmọ oṣu mẹsan an to jẹ ti alabagbe rẹ.
Ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria jabọ pe adajọ E.
Kubeinje ti ni ki awọn olupẹjọ gbe ejọ naa lọ si ọọfisi ileeṣẹ to n gba ẹjọ ro,
to jẹ ti jọba Eko.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ naa si ọjọ karun un, oṣu to n bọ.
Ẹsun fifọwọ kan ọmọde lọna aitọ ni wọn fi kan Agboola to
n fi agbegbe Ijora-Badia ṣebugbe.
Ọlọpaa to ṣewadii ẹjọ naa, DSP Kehinde Ajayi sọ niwaju
ile ẹjọ ọhun pe asiko ti iya ọmọ naa lọ ra indomie lo gbe ti Agboola ki afurasi
naa to fọwọ kan ọmọ jojolo ọhun.
Eyii ti wọn ni o lodi si ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko ti
wọn gbe kalẹ lọdun 2015.
Ofin naa kede ẹwọn gbere fun ẹnikẹni to ba ni ibalopọ pẹlu
ọmọde.
Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ Ẹtì ọ̀sẹ̀ yìí àti ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ fún ìsinmi ọdún Àjínde
Minisita fun ọrọ
abẹle, ọgbẹni Rauf Aregbesola, lo fi ikede naa sita niluu Abuja.
Oríṣun àwòrán, Ministry of Information
Aregbesola rọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati lo akoko ọdun Ajinde naa lati kẹkọọ nipa irẹpọ, idarijin, ifẹ ati alaafia lara Kristi.
O tun rọ awọn ọmọlẹyin Kristi lati fi akoko ọdun ọhun gbadura fun eto abo Naijiria to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
Lẹyin naa lo ni ki wọn maṣe sọreti nu nipa Naijiria nitori gbogbo nnkan to nira ṣi maa pada bọ sipo.
A ò lọ́wọ́ nínú títojúbọ̀ àti bí ọ̀rọ̀ orí fóònù Obi àti Bishop Oyedepo ṣe lu síta o! – NCC
Èmi kò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tẹ́ẹ fi kán mí, ọwọ́ mi mọ́ - Trump
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Amẹrika
nigba kan ri Donald Trump lo ti ni oun ko jẹbi ẹsun mẹrinlelọgbon ti wọn fi kan
oun.
Igbẹjọ Donald Trump bẹrẹ
lanati Donald Trump si lo wakati kan din die ko to jade.
Awọn ẹsun ti
wọn fi kan Trump lo ni ṣe pẹlu
fifi irọ san owo, wọn tun ni aarẹ tẹlẹri naa n dukoko lori erọ ayelujara
rẹ.
Gbogbo ẹsun ti wọn fi kan
Trump ni o jẹ ẹsun ti o kere julọ ni isọri “category E” labẹ ofin Amẹrika ti o
si ni ijiya ọdun mẹrin ti wọn ba rii wi pe o jẹbi awọn ẹsun
naa.
Adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun, Juan
Merchan kilọ fun awọn agbẹjọro igun mejeji lati ṣọ ọrọ
ẹnu ati ihuwasi wọn bi igbẹjọ rẹ ti n tẹsiwaju.
Donald Trump lo ti ṣaaju sọ
wi pe gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun jẹ isẹ awọn alatako oun,o ni
adajọ Juan Merchan ṣegbe lẹyin ijọba ti ko si fẹran oun nitori
ọmọ rẹ siṣẹ labẹ igbakeji aarẹ to wa lori alefa lọwọlọwọ,
Kamala Harris.
Donald Trump lo fẹ dije
dupo aarẹ Amẹrika fun igba ẹkeji, igbẹjo rẹ yii ni yoo jẹ
igba akoko ti ẹniti o ti jẹ aarẹ Amẹrika yoo maa koju
igbẹjọ.
Aarẹ tẹlẹ, Donald Trump ni wọn ti fẹsun kan
lori bi o ṣe fi owo bo asẹwo kan, Stormy Daniels
lẹnu.
Arabinrin Daniels fẹsun kan
Trump pe awọn mejeeji jọ ni ibalopọ, to si gba owo toto
ẹgbẹrun lọna aadoje owo dọla lati ọwọ agbẹjọro Trump tẹlẹ, saaju eto idibo ọdun
2016 lati fi ẹnu mẹnu lori ajọsepọ wọn.
Aarẹ Trump ti
morile Florida lẹyin igbẹjọ rẹ nibiti o ti ba awọn ololufẹ rẹ
sọrọ, o
ni: “Ẹsun kan ti mo ṣẹ ni wi pe
mo daabo bo orilẹede yii lọwọ awọn to fẹ baajẹ”.
Ireti wa wi pe igbẹjọ naa yoo tẹsiwaju lọjọ kẹrin osu
kejila,osu meji si igba ti
idibo abẹle ẹgbẹ oselu Republican fun ipo aarẹ ẹgbẹ naa.
Kọ̀wé fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alága Afenifere - Àwọn ọ̀dọ́ sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Adebanjo
Oríṣun àwòrán, Facebook
Àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ lábẹ́ ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀
Yorùbá, YOYAN ti ní àwọn kò ní ìfọkàntán nínú adelé alága ẹgbẹ́, Pa Ayo
Adebanjo.
Àwọn ọ̀dọ́ náà ń béèrè pé kí Pa Adebanjo kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀
gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ Afenifere nítorí kò ní ìfẹ́ ìran Yorùbá dọ́kàn.
Àtẹ̀jáde kan tí adarí àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún, Eric
Oluwole fi léde fẹ̀sùn kan Adebanjo pé ó ń hùwà tako ìlọsíwájú ìran Yorùbá.
Wọ́n ní láti ìgbà tí Adebanjo ti gbapò alága ẹgbẹ́ náà ló ti
ń ṣiṣẹ́ lòdì sí gbogbo ohun tí ẹgbẹ́ náà wà fún pàápàá ní dídá ààbò bo ìran
Yorùbá.
Wọ́n ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn pé Adebanjo ṣe àtakò ọmọ
Yorùbá láti dé ipò Ààrẹ Nàìjíríà bí ó ṣe tako Tinubu lásìkò ìpolongo ìbò sípò
Ààrẹ.
Àtẹ̀jáde ọ̀hún ṣàfikún rẹ̀ pé kìí ṣe Pa Adebanjo tí bàbá
Reuben Fasoranti fà àkóso ẹgbẹ́ Afenifere lé lọ́wọ́ ni èyí tí àwọn ń rí báyìí.
Wọ́n tẹ̀síwájú pé ìdí nìyí tí àwọn kò fi ní ìgboyà àti ìfọkàntán
nínú Adebanjo mọ́ tí àwọn sì ń gbà á níyànjú láti yé pe ara rẹ̀ ní adarí
Afenifere mọ́.
Bákan náà ni wọ́n ní fífi ọwọ́ òsì júwe ilé fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́
méjì tó tún jẹ́ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ láti ọwọ́ Pa Adebanjo láìsí ìmọ̀sí àwọn ọmọ
ẹgbẹ́ yòókù jẹ́ ohun tí kò bá ojú mu tó.
Wọ́n ní àwọn bù ẹnu àtẹ́ lu bí Pa Adebanjo ṣe yọ Agbẹnusọ
àti akọ̀wé ètò Afenifere, Jare Ajayi àti Abagun Kole Omololu láì gba àṣẹ lọ́wọ́
Pa Ruben Fasoranti.
Wọ́n ní fún àwọn ìdí wọ̀nyí kí Pa Adebanjo kọ̀wé fipò rẹ̀
sílẹ̀ kó sì yé pe ara rẹ̀ ní alága Afenifere mọ́.
Ìjọba Ondo yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gbà 1000 lọ́wọ́ àwọn ènìyàn láti ṣàtúnṣe ètò ẹ̀kọ́
Oríṣun àwòrán, Facebook
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo ti kéde pé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà yóò
máa san ẹgbẹ̀rún kan náírà ní ọdọọdún láti fi ṣàtìlẹyìn fún ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀
náà.
Alága ìgbìmọ̀ tó wà fún ìkówójọ ìdàgbàsókè ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀
Ondo ìyẹn "Ondo State Education Endowment Funds" (OSEEF), Akinola
Akinfenwa ló kéde ọ̀rọ̀ náà fún àwọn akọ̀ròyìn.
Akinfenwa ní gbogbo ènìyàn tí ọjọ́ orí wọn bá ti pé
méjìdínlógún ni wọ́n ní ètò láti máa san owó yìí lójúnà àti lè ràn ìjọba lọ́wọ́
láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ wọn.
Ó ní ìgbésẹ̀ yìí wáyé láti ri pé owó wọlé fún ètò náà yàtọ̀
sí èyí tí ìjọba ń gbé kalẹ̀.
"A máa lo owó yìí láti fi ṣàtúnṣe àti mú àyípadà bá ètò
ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ wá"
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́, sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀
ẹ̀rọ ìpínlẹ̀ Ondo, Femi Agagu ní ìjọba ni yóò máa gba owó yìí lọ́wọ́ àwọn
ènìyàn.
"A máa lo owó náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ tó jẹ́ wí pé
àwọn ènìyàn káàkiri ìpínlẹ̀ Ondo àti lẹ́yìn odi ni yóò máa wá san owó
yìí."
Irọ́ ni pé mo fi ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà ṣe ìpolongo ìbò - Obi
Oríṣun àwòrán, Collage
Olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party níbi ètò ìdìbò
sípò Ààrẹ tó wáyé ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kejì, ọdún 2023, Peter
Obi ti fèsì sí ẹ̀sùn tí ìjọba àpapọ̀ fi kàn án pé ó ń gbèrò láti dojú ìjọba bolẹ̀.
Peter Obi ní gbogbo ìpolongo ìbò tí òun ṣe ṣáájú, lásìkò àti
lẹ́yìn ìdìbò náà, kò sí ibì kankan tí òun ti fi ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà ṣe ìpolongo òun
rárá.
Obi sọ̀rọ̀ yìí nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde láti fi fèsì fún
Mínísítà fétò ìròyìn àti àṣà ilẹ̀ Nàìjíríà, Lai Muhammed.
Ṣáájú ni Lai Mohammed ti fẹ̀sùn kan Obi níbi ètò kan ní orílẹ̀
èdè Amẹ́ríkà wí pé níṣe ló ń ṣe àtìlẹyìn fún dída ojú ìjọba tó wà lóde délẹ̀.
Obi ní ẹ̀sùn tí Mohammed fi kan òun yìí yàtọ̀ gédégédé sí
ìwà tí òun le wù àti pé wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ ba òun lórúkọ jẹ́ ni.
"Gbogbo ìgbìyànjú àti ipá ni wọ́n ń sà láti fi pe àwọn
nǹkan tí kìí ṣe tèmi ní tèmi, àwọn ẹ̀sùn tí Mínísítà Lai fi kàn mí yìí kìí ṣe
tèmi rárá."
"Mi ò fi ìgbà kankan bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ tàbí gbé oríyìn
fún àwọn tó ń fojú tẹ́ńbẹ́lú Nàìjíríà, mi ò lè ṣe tàbí ṣàtìlẹyìn fún ohun tí
yóò kóbá ìṣọ̀kan Nàìjíríà."
"Gbogbo ìpolongo tí mo ṣe ló wà ní àkọsílẹ̀, àláfíà àti
àwọn nǹkan tó ń bá Nàìjíríà ni mo fi ṣe ìpolongo."
"Mi ò fi ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà ṣe ìpolongo rárá, mo jẹ́ ẹni
tó nífẹ̀ẹ́ ṣíṣe nǹkan ní ọ̀nà tó tọ́ tí mo sì ń bèèrè fún ẹ̀tọ́ mi báyìí ní ilé
ẹjọ́."
Bákan náà ló rọ gbogbo àwọn tó ń sọ̀rọ̀ òdì tàbí tàbùkù
Nàìjíríà láti jáwọ́ níbẹ̀ nítorí wọ́n ń ba Nàìjíríà lórúkọ jẹ́ ni.
Donald Trump ń jẹ́jọ́ lọ́wọ́ nílùú New York lórí ẹ̀sùn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n
Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun
ti wọn fi kan oun ni bayii ti igbẹjọ rẹ ti bẹrẹ.
Ẹsun mẹrinlelọgbọn ni wọn fi kan Trump, lara rẹ ni iwa ọdaran
ati yiyi iwe okowo wa.
Adajọ Judge Juan Merchan lo n gbọ ẹjọ ọhun nile ẹjọ kan
to wa lagbegbe Manhattan, niluu New York.
Donald Trump ni Aarẹ tẹlẹri akọkọ ti yoo koju ẹsun iwa ọdaran
nilẹ Amẹrika.
Ẹwẹ, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo peju siwaju ile ẹjọ ti igbẹjọ
naa ti n waye, ti wọn si wọ aṣọ kan to ni aworan Trump lara, eyii ti wọn kọ akọle
si lara pe “Ko jẹbi.”
Awọn alatilẹyin rẹ lo ṣe ikowojọ lati ran aṣọ naa, ki wọn
le pin fun awọn eeyan ni New York fun atilẹyin.
Àwọn agbébọn ti jí ọmọ ilẹ ẹ̀kọ́ girama mẹ́wàá gbé lọ ní Kaduna
Oríṣun àwòrán, Ripples Nigeria
Awọn agbebọn ti ji awọn ọmọ ile ẹkọ girama mẹwaa gbe lọ
nipinlẹ Kaduna.
Kọmiṣọna eto abo ipinlẹ naa, Samuel Aruwan, lo fidi
iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.
Iroyin ni ile ẹkọ government secondary school, to wa ni
ijọba ibilẹ Kachia ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Bo tilẹ jẹ pe Aruwan sọ pe awọn ko tii le sọ ni pato ibi
ti iṣẹlẹ naa ti waye, awọn n reti abajade iwadii lati mọ boya inu ile ẹkọ naa
ni wọn ti ji awọn ọmọ ọhun gbe tabi ibomiran.
O fi kun pe ijọba yoo fi atẹjade ṣọwọ si awọn akọroyin ti
wọn ba ti mọ sii nipa ijinigbe ọhun.
Ipinlẹ Kaduna jẹ ọkan gbogi ni Naijiria nibi ti iṣẹlẹ
ijinigbe ti di tọrọfọnkalẹ.
Wo mínísítà tó ń já fún ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo ní Afrika
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita to n ri si ibaṣepọ laarin awọn orilẹ-ede lorilẹ-ede
France, Chrysoula Zacharopoulou, ti ke si awọn orilẹ-ede ni Afrika lati bọwọ
fun ẹtọ awọn to n ni ibalopọ akọsakọ.
Lasiko to n sọrọ niluu Accra, lorilẹ-ede Ghana, Zacharopoulou
sọ pe oun ko ni dẹkun ati maa ja fun ẹtọ awọn eeyan naa nilẹ Afrika.
O ni “ Ni orilẹ-de ede mi ati nilẹ Europe, a maa bọwọ fun
ẹtọ awọn ẹlomiran, asi ni aṣoju to n ṣe igbeleke ẹtọ awọn to n ni ibalopọ akọsakọ.”
“Mi o ni dẹkun ati maa sọ siwaju si pe a gbọdọ maa bọwọ
fun gbogbo eeyan, to fi mọ awọn to n ni ibalopọ akọsakọ, ẹtọ wọn labnẹ ofin ni.”
Zacharopoulou, to n rinrinajo ọlọjọ mẹta si Ghana wa lara
awọn olori lati ilẹ okeere to n ja fun ẹtọ awọn to n ni ibalopọ akọsakọ nile adulawọ.
Ohun to sọ yii fara pẹ ohun kan naa ti igbakeji Aarẹ Amẹrika,
Kamala Haris sọ lasiko abẹwo rẹ si Ghana lọsẹ to kọja.
Ile Ife kìí ṣe fún ẹlẹ́sìn Musulumi tábi Krìstẹ́nì rárá - Arole Obatala àgbáyé
Tí Tinubu bá kọ̀ láti yanjú àtúntò ìjọba, ó ṣeéṣe kí.... - Soyinka
Súnmọ́ ìyàwó rẹ̀ nínú Ramadan àmọ́ tóo bá kú pi ... ẹ wá gbọ́ òótọ́ - Akewugbagold lahùn