Ọwọ́ DSS tẹ àwọn télọ̀ tó ń rán àṣíá Russia fún àwọn olùwọ́de ní Kano
Ọwọ awọn oṣiṣẹ agbofinro DSS lorilẹede Naijiria ti tẹ awọn aranṣọ to n ran aṣia orilẹede Russia fun awọn oluwọde niilu Kano.
Ileeṣẹ agbofinro DSS ni ọwọ tẹ awọn telọ naa ti wọn n ran awọn aṣia ti wọn n pin kaakiri ipinlẹ naa.
Bakan naa ni ileeṣẹ agbofinro DSS tun fi kun un pe ọwọ awọn ti tẹ awọn to gbe iṣẹ naa fun wọn., bẹẹ ni iwadi awọn ṣi n tẹsiwaju lori rẹ.
Ọmilẹgbẹ awọn oluwọde lapa ariwa orilẹede Naijiria ni wọn n mu aṣia orilẹede Russia kiri lasiko iwọde to n waye nibẹ.